Wednesday 12 August 2020

O tan! ASEYIN f’ofin de BASORUN Iseyin

O tan!

ASEYIN f’ofin de BASORUN Iseyin

-          O lo n gba’le onile, o si n safojudi sori ade

O ti jade ninu iwe iroyin Alariya Oodua ojo kewaa osu kejo, odun 2020

Aseyin ilu Iseyin, Oba Abd-Ganiy Adekunle Salau, Ajinase kin-in-ni ti pase ki Basorun ilu Iseyin, Oloye Raheem Adelodun lo ro kun nile na lori awon esun iwa ibaje kan ti won fi kan an. Lara awon esun ti won fi kan Basorun ohun ni fifi tipatipa gba ile onile ati afojudi si ori-ite, eyi to le tabuku ba ipo Aseyin.

Yato si Basorun yii, oba alaye naa tun yo Akiisi ilu Iseyin, Ogbeni Sulaimon Adewale Olanrewaju nipo lori esun po safojudi ati pe ko gba ibawi lori iwa afojudi to n hu sipo Aseyin. To si tun gbimopo pelu Basorun ilu Iseyin lati maa ta ile onile ninu ilu naa.

Ninu iwe kan ti Aseyin funra re ko lojo kokandinlogbon osu kefa odun yii sawon mejeeji toro kan. O fesun kan Oloye Adelodun poun ati Akiisi tele ohun n huwa to le ta abuku ba ipo ati ase ori ade ati ti molebi re. Leta ohun ka bayii “nitori iwa fifi gbogbo igba maa safojudi lai gba ibawi si ase ati ipo Aseyin, Oba Abd-Ganiy Adekunle Salau, a rii po o j’ebi esun ti won fi kan o. Eyi si farahan ninu awon ipade ikoko to n se pelu awon oloye pelu erongba lati ti won kolu ase ati ipo Aseyin ilu Iseyin.

“Iwa re ohun ni ko si yato si k’eeyan gbero lati dite gba ijoba ati ti tase agere. Yato si gbogbo iwonyi, ko jo po o fe gbo ibawi lori awon igbese to n gbe lateyin wa nipa bo o se maa n soro abuku si Aseyin pelu bi won se ki o nilo to. Bee lo tun se lojo kerindinlogbon osu kefa odun yii niwaju awon oloye Kabiyesi. Iwa re yii lo si tako asa ati ise ile Iseyin, eyi to le mu abuku baa aye ati ipo Aseyin. Nitori idi eyi, lo ro kun nile na gege bi Basorun ilu Iseyin, titi ta o fi da oro re ro.

“Titi digba naa, o o gbodo fi ara re han nibikibi gege bi Basorun ilu Iseyin, bee si lo gbodo gbe gbogbo ojuse re sile. Gbogbo awon eto ati anfaani to si ro mo ipo naa ni ko nii je tie mo.

Gege bi enikan to bakoroyin wa soro l’aafin Aseyin, sugbon to ni ka ma daruko oun se so, leta ohun ti lo sile-ise ijoba ipinle Oyo to n ri soro ijoba ibile ati oye jije nipinle Oyo lati da owo osu awon mejeeji toro kan naa duro.

Eni naa ni igbese Aseyin ohun kii se akoko. O ni lodun 2018, awon kan naa huwa afojudi bee, ti Kabiyesi si f’ofin de won. Sugbon, nigba tawon agbaagba ilu kan bii agba oselu nni, Oloogbe Oloye Salaudeen Adelere da si i, o f’ori ji won.

 

 

No comments:

Post a Comment