Monday 31 August 2020

O ga o! Won tun fipa b’obinrin mi-in lopo n’Ibadan, won tun pa a


O ga o! Won tun fipa b’obinrin mi-in lopo n’Ibadan, won tun pa a

Yanju Adegboyega

Ni ko tii ju ojo kan lo towo ile-ise olopaa ipinle Oyo pada te, omokunrin afurasi odaran ti won lo n fipa bawon obinrin lopo, to si n pa won nijoba ibile Akinyele, Ibadan, Sunday Sodipe, isele ifipa bani lopo ati isekupani mi-in tun ti waye nibe. Ilu Alabata nitosi Moniya lo si ti sele.

Akoroyin wa gbo p’ojo Monde ose to koja yii, ojo kerinlelogun osu kejo nisele aburu ohun se. Gege ba a se gbo, omokunrin kan ti won poruko re ni Toheeb Ako atawon kan to ti salo lo fipa ba omobinrin kan ti won poruko re ni Mary Daramola lopo, ti won sit un pa a.

Nigba to n soro lori isele aburu ohun, Balogun Alabata, Oloye Rasaq Ajimoti salaye p’enikan to n re koja lo rawon eeyan ohun lasiko ti won fe gbe oku Mary sonu sinu igbo kan nitosi. Eni naa lo si pariwo, eyi to je ki owo te Ako. Ti won si mu un lo si tesan olopaa to wa ni Moniya.

Ninu oro tie, eni ti Daramola n gbe lodo re, Abileko Folakemi Adedeji banuje pupo lori isele buruku naa, o si pe fun idajo ododo lati le je eko fawon yoowu ti won ba n gbero lati fipa ba eeyan lopo lojo iwaju.

 Lasiko to n bakoroyin soro, Baale Alabata, Oloye Olakanmi Olaniyan ro awon odo ilu naa lati se suuru pelu afikun pe ile-ise olopaa atawon osise eleto-aabo to ku ti n sise iwadii lo lori isele naa. Bee si ni won ti fi gbogbo awon olugbe Alabata lokan bale lori aabo emi ati dukia won.

Gege ba a se gbo, won ti gbe odara naa lo si eka ile-ise olopaa to n sewadii iwa odaran to wa n’Iyaganku, Ibadan fun iwadii siwaju sii. Lasiko ta a n ko iroyin yii jo, a o loore-ofe lati ba alukoro ile-ise olopaa ipinle Oyo, Ogbeni Gbenga Fadeyi soro.

 

  

 

No comments:

Post a Comment