Monday 31 August 2020

O ma se o! adigunjale yinbo pa TAOREED leyin to gb’owo tan ni banki n’Ibadan


O ma se o! adigunjale yinbo pa TAOREED leyin to gb’owo tan ni banki n’Ibadan

Yanju Adegboyega

o ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii.

Ko seni to ri oku okunrin eni odun marundinlaadota kan, Taorred Alao tawon adigunjale yinbon pa lojo Monde ose to koja niluu Ibadan, ti ko mu omi loju. Taoreed lawon adigunjale kan ti enikeni ko tii mo yinbon pa loju ona to ti sekiteriati ijoba ipinle Oyo lo sile ijoba l’Agodi, Ibadan. Gege ba a se gbo, awon adigunjale ohun lo ti n tele Taoreed ni kete to gb’owo ni banki kan ni Bodija.

Akoroyin wa gbo pawon adigunjale eleni meji ohun lo wa lori okada kan, ti won si ya okada ti Taoreed gun sile niwaju ile-ise ijoba ipinle oyo to n ri si oro ayika. Leyin naa si ni won yinbon fun un. A gbo pe, bi won se yinbon fun un tan ni won gbe baagi kekere kan to kowo to gba ni banki ohun si. Bee si ni won tun gbe okada re lo. Enikan tisele ohun soju re ni owo to wa ninu baagi naa yoo to egberun lona eedegbeta naira, N500, 000.

Nigba to n fidii isele aburu naa mule, alukoro ile-ise olopaa ipinle Oyo, Ogbeni Olugbenga Fadeyi ni eemeji ni won yinbon fun Taoreed pelu afikun pe won gbe owo kan ti enikeni ko mo iye to to, eyi to lo gba ni banki lo, bee si ni won gbe okada Bajaj re lo pelu.

Fadeyi safikun oro re pe loju ese ni won sare gbe Alao lo sile-iwosan Adeoyo to wa laduugbo Ring Road. Nibe si ni won ti so po ti ku, ti won si ti gbe oku re pamo sile igbokusi to wa nibe.

Ninu oro re “Iroyin to to mi lowo lati odo oga olopaa tesan to wa nitosi ibi isele ohun ni pe, ni deedee aago mejila ku iseju meedogun aaro, ladojuko ile-ise ijoba ipinle oyo to n ri si oro ayika, awon kan yinbon fun enikan ti won poruko re ni  Taoreed Alao, eni odun marundinlaadota ti won si gbe okada Bajaj re salo.

”Loju ese ni won sare gbe e lo sile-iwosan Adeoyo, nibi to pada ku si. Iroyin fi ye wa pe nise lawon eeyan ohun telee lati banki olokoowo kan laduugbo Bodija debi ti won ti yinbon fun un naa.

“Foonu meji ati owo to to egberun lona aadorun naira ni won ba lara re. Won si ti gbe oku re pamo sile igbokusi to wa ni ile-iwosan Adeoyo nibe.

Alukoro ile-ise olopaa ipinle Oyo wa salaye pawon olopaa ti n topase awon to sise aburu ohun pelu afikun pe laipe lowo yoo te won.

 

No comments:

Post a Comment