Monday 31 August 2020

A o daabo bo ara wa, te o ba le daabo bo wa - awon agbe Ikoyi so fun ijoba Oyo




 

 

A o daabo bo ara wa, te o ba le daabo bo wa - awon agbe Ikoyi so fun ijoba Oyo

Yanju Adegboyega

O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii.

Awon agbe ati gbogbo olugbe ilu IKoyi-Ile nipinle Oyo ti salaye po see se kawon bere sii daabo bo ara awon lowo awon fulani daran-daran to n fi gbogbo igba ko lu won, se won lese ati pa won nipakupa tijoba ipinle Oyo ba kuna lati daabo bo won.

Awon agbe yii lo ni laipe yii lawon Fulani ohun pa okan ninu won, ti won fipa bawon omo awon lopo. Ti won si tun ba gbogbo oko won je. Awon eeyan naa ni, isele aburu ohun si ni ko je kawon loju oorun rara mo. Nigba to n soro fawon akoroyin, Babalaje Agbe nijoba ibile Oriire, Oloye Oyekola Joseph salaye pe, lati bi odun mejo seyin lawon agbe ilu naa ko ti nifokanbale rara. O si wa ke sijoba ipinle Oyo lati tete wa nnkan se soro ohun, ko to di pe yoo koja ohun tapa re yoo ka.

Oyekola, eni to tun je akowe fun egbe Idera Agbe, eka tijoba ibile Oriire ni “a o tie mo nnkan ta a le se, nitori ta a ba ni ka gbe igbese tabi ka gbesan. O le fa itaje sile. A fe kijoba ran wa lowo, ki won si gbe igbese to ye. Nitori, oba wa to ye ko ko daabo bo wa lo kuna, to si je pee yin awon Bororo yii lo n gbe si.

“Awon daran-daran yii ge owo okan ninu awon osise wa to n sise ninu oko. Won ba gbogbo ire oko wa je. Won sa agbe kan naa ladaa lori, ti won si se awon mi-in lese. Omobinrin wa meji si ni won tun fipa ba lopo.

Okan lara awon agbe naa to n je Usman Daudu ni ogun sare oko agbado, isu, tomato atawon ire oko mi-in lawon daran-daran yii baje. Bee si ni won sa oun ladaa lori lasiko toun n gbiyanju lati le won kuro ninu oko naa.

“Won o dawo ikolu duro lawon oko wa. Aimoye igba la ti be won, sugbon to je eyin eti won ni gbogbo ebe wa n bo si. Bororo ni won, nitori ta o nisoro pelu awon Fulani to ti wa nibi tele.

Agbe mi-in toro ohun tun kan, Dominic Gbegi ni eemerinla ni won sa oun ladaa lasiko toun n gbiyanju lati le awon daran-daran ohun to ko maalu wonu oko oun, ti won si ba gbogbo ire oko je.

Nigba to n soro lori isele ohun, Onikoyi ti Ikoyi-Ile, Oba Abdul-Yekeen Atilola Oladipupo ni gbogbo ipa loun ti sa lati le mu ki alaafin joba laarin awon agbe atawon daranm-daran yii pelu afikun p’oro wahala agbe atawon daran-daran kii soro ilu oun nikan, bi ko se oro gbogbo agbegbe kaakiri.

Gege bo se so “Gbogbo ona lati gba lati mu ki alaafia joba laarin won, nitori pa o le ya agbe ati daran-daran. A ti jo n gbe papo ojo se die. Opo igbese ni mo ti gbe lori oro ohun lati wa opin si i, sugbon o dabi eni pe igbiyanju mi ko to. A fe kijoba ba wad a si i.

“Mo ti se okan-o-jokan ipade pelu awon baale to wa lagbegbe yii lati wa opin sisele ohun. Koda, mo sepade pelu igbakeji oga agba olopaa orile-ede yii l’Osogbo pelu komisanna olopaa. Awon olopaa si seleri fun mi lati ba wa nnkan se si i.

Oba alaye yii wa ke si gomina ipinle Oyo, Onimo-ero Seyi Makinde, ile igbimo asofin ipinle Oyo atawon ile-ise alaabo gbogbo lati dakun wa nnkan se soro ohun, ko to di po koja ohun towo le ka, nitori toun o fe itaje sile mo niluu naa.

Okan lara awon ilu to ti pe nile ni Ikoyi-Ile nijoba ibile Oriire, ipinle Oyo. Awon abule to to orinlelegbeta din mefa, 674 lo si yii ka. Awon bii Olode-Elu, Animashaun, Obamo, Igboayin,Laomi atawon mi-in bee bee lo.

No comments:

Post a Comment