O ma se o! SEGUN AINA,
onitiata ku n’Ilorin
Yanju Adegboyega
Ajalu nla mi-in tun ja
lawujo awon osere ori-itage lose to koja, nigba ti okan ninu awon agba osere
ilu Ilorin, Alagba Dare Segun Aina naa tun ku. Gege ba a se gbo, ojo Tusde, ojo
kerinla osu yii lokunrin naa ku leyin to ti saisan fun bi ose meta gbako. Gege bi okan ninu awon to sun mo okunrin naa
nigba aye re, Ogbeni Idowu Alarape se salaye fun akoroyin wa. Oko-ere okan ninu
awon omo-ise re lo ti de lati ilu Olomi Oja, nigba to sakiyesi po fe re oun. Loju
ese la si gbo po gba ile-iwosan lo, sugbon to pada ku sile-iwosan naa.
Omo bibi ilu Oke Opin
nijoba ibile Ekiti, ipinle Kwara ni Alagba Dare Segun Aina. O lo sile-iwe alakoobere niluu Oke Opin,
leyin naa lo te siwaju nile-iwe girama Anglican, Oke Opin. Leyin to pari iwe
mewaa, o lo ko’se ere ori-itage lodo Oloogbe Alagba Afolabi Ogundele, eni tawon
eeyan tun mo si “baba Caleb” lodun 1980, odun 1985 lo si da duro gege bi oga
nidii ise tiata.
Leyin to di ominira ara
re, o kori siluu Eko, nibi to ti da ise po pelu okunrin gbajumo onitiata mi-in,
Oloogbe Gbodorogun. Won si jo n gbe ere ori-itage kaakiri awon ilu ati adugbo
niluu Eko, koda won maa n lo sere fun won lawon orile-ede to mule ti orile-ede
yii, bii Cotonou. Odun 1995 lo pada
siluu abinibi re, Kwara to sit un n te siwaju ninu ise ere onise, sugbon ise
awon to maa n to itage gan lo mu lokunkundun.
Yato si ise tiata,
Oloogbe Aina tun n sise awon to maa n bawon gb’oku jo, ti won si maa n sinku. Koda,
o ni moto ti won fi maa n gbe oku lo si ite, bee lo si n kan posi ta fawon
eeyan. Alarape sapejuwe okunrin naa gege
bi eni to niwa pupo. O salaye pe, kii fa ijangbon rara. O ni ti oselu egbe ba
de, to ba nifee sipo kan. Sugbon, to ba rii p’elomi-in naa nifee sipo ohun,
nise ni yoo fi sile fun eni naa.
Nigba aye re, Alagba
Aina ti figba kan je alaga egbe awon osere, ANTP nijoba ibile Irepodun, ipinle
Kwara ri. Bee lo ti je oludari ariya (Social Director) fun egbe osere TAMPAN
lodun 2005. Meji ninu awon omo re, okunrin kan, obinrin kan lo n sise ere
ori-itage lasiko yii, Seun ati Adeola.
Opo awon gbaju gbaja
osere ori-itage lo ti ba sise papo bii Oloogbe
Ogun Majek; Fokoko; Iya Tuudi; Abeni
Agbon; Oloogbe Ajileye; Oloogbe Dagunro;
Olofa Ina; Iya Iroko; Lalude atawon
mi-in bee bee lo. Eni odun mejidinlogota ni lasiko iku re.
Akiyesi : O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii.
No comments:
Post a Comment