Monday 17 August 2020

Awon to n binu ilana igbani s’Amotekun ko mo nnkan ni – TOGUN

 

 

Awon to n binu ilana igbani s’Amotekun ko mo nnkan ni – TOGUN

Ajagun-feyinti Kunle Ajibola Togun ni alaga iko eso alaabo ile Yoruba, Amotekun fun ipinle Oyo. Laipe yii la gbe iroyin kan pawon ode ibile atawon kan n binu lori ilana igbani sise iko naa, eyi ti won ni ki won lo maa se lori ikanni ayelujara.

Ehonu awon ode to n binu naa ni pe, nise ni won fe o kawon kopa ninu iko ohun, eyi lo je ki won ni kawon lo maa foruko sile lori ikanni ayelujara, nitori ti won mo pawon o nimo nipa lilo ero komputa. Akoroyin wa, YANJU ADEGBOYEGA ba alagba naa soro lori foonu laipe yii. Abo ree.

 
Alariya Oodua: E ku deedee asiko yii, e si ku ise ilu.

Togun: Bawo ni nnkan o?  E seun, a dupe o.

Alariya Oodua: Ni bi ose meloo seyin, a gbe iroyin kan lori ilana igbani sise eso alaabo ile Yoruba, Amotekun, eyi teyin je olori fun nipinle Oyo. Awon ode ibile si fesun kan pe, nise le fe ti oro oselu bo ilana igbani sise ohun, nitori tawon ode ibile ko le lo ero komputa, ka to so ikanni ayelujara. Ki le ri si i?

Togun: E seun. Se e mo pe alai nikan-an se ni won sa?

Alariya Oodua: Alai nikan-an se? Ki le ri?

Togun: Mo ni alai nikan-an se ni won. Taa lo wa nile Yoruba nile to mo lonii ti ko l’omo to le ba a se iforuko sile yen?

A o nii gba enikeni sinu iko Amotekun gege bi egbe rara. Awa naa gbo nipa ehonu won. Won lo ye ka ko foomu fawon ni, kawon pin in fawon eeyan awon. Iyen o le see se.

Alariya Oodua: Ninu foomu igbani sise yen, abala kan wa ti won ni ki olori ilu ati eni to n soju won nile igbimo asofin fowo si. Nje gbogbo eni to mu foomu wa ni onorebu to n soju ekun idibo re le da mo gege bi eni to wa latibe, to si mo iru iwa to wa lowo re?

Togun: Awon omo ile igbimo asofin yii naa lo sofin, ti won si fowo si i pe ka se bee. Won si so p’enikeni to ba wa lati ekun idibo awon, awon gbodo fowo si foomu fun un.

Alariya Oodua: Seyin o si ro pe yoo lewu die, ki onorebu kan fowo siwee fun eni ti ko mo dele?

Togun: Won o nilo lati mo won, ki won to fowo si foomu yen. Se gbogbo eni to n gbe lekun idibo won ni won maa mo ni.

Awon ibeere to wa ninu foomu ohun o si nira rara. Oruko, adireesi. Nje o wa ninu egbe alaabo kan? Ewo? Ode, OPC, Agbekoya, o tan. Koda, ko sibi taa ti beere iwe-eri kankan nibe. Sugbon, eni to ba maa darapo gbodo to eni odun mejilelogun si ogota.

A mo pe iru awon agbekoya o mo’we. Bee si la le ri ninu awon to ku naa. sugbon, ohun tawon fe ni pe ka ko foomu fun won, ki won lo maa pin in fawon to wu won.

A o fipa mu enikeni lati darapo. Eni to ba fe ni. Eeyan o si le je agbaboolu, ko tun je adari idije, refiri leekan naa. Ohun tawa fe niyen.

A ti salaye fun won pa o gba eeyan sinu Amotekun gege bi egbe. Ori ko ju ori ni. Ode to ba ti darapo mo Amotekun gbodo mo poun o nii lo sipade egbe ode mo, titi yoo fi fise sile. Nitori, to ba se bee, ibi meji ni okan re yoo wa. To ba wa kuro ninu Amotekun, o le pada sinu egbe re, boya OPC, Vigilate tabi eyikeyii to n se. E si je ki n so fun un yin. Kii se pe, nitori ta o gba eeyan sinu Amotekun, a o le fun un nise se. A o maa ba won sise papo gege bi egbe ode, OPC, Agbekoya tabi Vigilate. A o kan ni maa sanwo osu fun won ni. Nitori naa, awon gan lo n se monafiki, ti won si n ti oselu b’oro to wa nile yii.

Nje e le gbagbo pawon kan ti n lo ta foomu wa l’egberun kan aabo fawon eeyan. Enikan wa ba mi ni Saki poun ra foomu to je ofe ni lori ikanni ayelujara ta a fi si.

Alariya Oodua: Awa tie ro pe, ai lagboye oro to wa lara nnkan to n dawon eeyan wa laamu. Opo ni yoo ti nii lero pe, ki won ma baa gba oun ni won se gbe ilana igbani sise yii kale?

Togun: Sugbon, gbogbo won naa ko la le gba. Nigba ti foomu gbigba yoo fi wa sopin, awon to le ni egberun lona aadota lo ti foruko sile nipinle Oyo nikan. Se gbogbo egberun lona aadota yii la o wa gba? A o le gba gbogbo won, sugbon ohun ta a n so ni pe, won ti n sise yii teletele, o si ye won daadaa. Nitori naa, awon ta a gba yii ni yoo maa gb’owo osu ti won ba bere ise, sugbon, iyen o so pawon ta o gba o wa ni ko si nnkan to kan awon mo. Won o si maa sise won lo.

Alariya Oodua: Awa lero pohun tawon eeyan wa nilo ni ilaniloye?

Togun: A ti se ilaniloye fun won. A ti lo se l’Oyoo, a ti se ni Saki. O ye ka lo s’Ogbomoso lose to koja, sugbon idiwo kekere kan waye, la o se le lo mo. A ti n lo se ilaniloye kaakiri. Mo ti lo salaye lori radio ati telifisan ijoba ipinle Oyo. Lanaa, mo wa lori redio ijoba apapo n’Ibadan.

Se ki n jewo fun un yin? Mo gbo ti won lawon kan n so po se je Oke Ogun ni won ti yan alaga fun Amotekun. Won loro yen tie di awuyewuye nibi ti won l’eni naa ti so o.

Awon ode naa o si tun ran oro lowo. Won ni won lawon lo mo inu igbo, nitori naa, awon lo ye ki won gba sinu Amotekun. E dakun, se OPC o mo inu igbo? Se agbekoya o mo inu igbo? Se agbe to n da oko o mo inu igbo? Ohun ta a fe se ni po ti niye ta a maa mu ninu okookan awon t’oro kan.

Ni nnkan odun mejo seyin, komisanna olopaa ipinle Oyo kan ti ran igbakeji re wa ba mi ri ni Saki, pe ko wa mo ogbon ta a n da ninu iko alaabo vigilante. Lonii, opo awon omo iko alaabo vigilante la tun ko fawon ijoba ibile kaakiri, to je pawon lo n sanwo osu won. Ise ti won ti n se lat’ojo yii wa niyen. Se won o wa mo inu igbo mo? Awon to n mu odaran, ti won n lo doju ija ko awon Fulani daran-daran to ba huwa odaran.

Alariya Oodua: Asiko kan tie wa ti gomina tele nipinle Oyo, Otunba Adebayo Alao-Akala ni ko ye ko je ajagunfeyinti ni won o fi s’olori Amotekun?

Togun: Se e maa gbo mi? Akosemose olopaa ti ori re pe daadaa ni Alao-Akala looto. Sugbon, mo mo pe ko le ja mi niyan ohun ti mo fe so yii rara. Ti apa olopaa ko ba ka eto aabo mo nibi kan, kii sawon omo oloogun nijoba maa n ranse si.

Kii se gbogbo oro naa la le fi se oselu, paapaa eto aabo. E wo iru ogun tijoba apapo n gbe tawon iko onisunmomi, Boko Haram. Se apa olopaa ka a ni won n ko soja lo sibe?

Orisi idanilekoo meji kan wa tawon omo oloogun n gba. Akoko la n pe ni “Tactic A”, eyi lo nii se pelu aabo laarin orile-ede s’orile-ede. Lati dojuko eni yoowu to ba fe ta’se agree lati ita. Ekeji ni “Tactic B”, eyi ni eto aabo abele. Nitorti naa, nise lo ye ka gbaruku ti gbogbo igbese to ba le sawon eeyan wa lanfaani.

Ta a ba r’eni to nimoran to le fun wa lori bi iko yen se maa tun wulo fawon eeyan wa, ko wa fun wa. Inu wa yoo dun lati gba imoran bee. Ohun to bi Amotekun ni pe, kii se gbogbo ibi ni olopaa le wa leekan naa. E lo sawon orile-ede to ti goke agba kaakiri agbaye. Te e ba se nijoba ibile, olopaa ijoba ibile ni yoo mu un yin. To ba je ipinle ni, olopaa ipinle ni yoo mu un yin. Oro to ba je mo aabo ijoba apapo, olopaa ijoba apapo ni yoo mojuto o. Iyen l’eto aabo won se duro daadaa.

Amotekun kii se orogun fun olopaa, bi ko se lati kun olopaa lowo ki aabo to daju le wa fun emi ati dukia awon eeyan wa.

Alariya Oodua: E seun, a dupe gan ni o.

Togun: Eyin naa seun pupo fun anfaani yii.

No comments:

Post a Comment