Monday 31 August 2020


 

OLUBADAN sojoobi odun mejilelaadorun-un, gbogbo Ibadan n dunnu

-sugbon, COVID-19 ko je ki won se e lalariwo

Ojo Wesde ose to koja yii ni Olubadan ile Ibadan, Oba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunniso Akoko pe eni odun mejilelaadorun-un lori ile alaaye. Ayeye ohun ko ba si je alariwo, sugbon nitori ase ijoba to wa lori apejo elero pupo lo je ki won se ayeye naa ni oniwonba. Yato sawon eeyan to se ikini lori redio ati ninu awon iwe iroyin, awon oloye ile Ibadan, egbe agbarijopo awon omo bibi ile Ibadan, Central Council of Ibadan Indegens, CCII ataeon afenifere mi-in se abewo “e n le nibeun” si oba alalye naa.

Nibi eto ti ko la ariwo lo kan to waye ni aafin Popoyemoja la ti rawon omo igbimo Olubadan bii, Asipa Olubadan ile Ibadan, Agba Oye Eddy Oyewole; Asipa Balogun ile Ibadan, Agba Oye Kola Adegbola ati Eekarun-un Olubadan ile Ibadan, Agba Oye Amidu Ajibade. Awon oloye ile Ibadan to tun wa nibe ni Ekefa Olubadan, Oloye Lekan Alabi; Jagun Olubadan, Oloye Wasiu Aderoju Alaadorin; Mogaji Moshood Gbolagade Akere atawon mi-in gbogbo.

Aare egbe agbarijopo awon omo bibi ile Ibadan, CCII, Oloye Yemi Soladoye lo ko gbogbo awon omo igbimo re leyin wa lati wa ki Olubadan ku oriire ojo-ibi ohun. Pasito fun aafin Olubadan, Oluso aguntan Soji Adediji lo se adura nilana esin kristeni lati bere eto ohun. Leyin naa si ni aweje-wemu tele e. Awon alase ati gbogbo osise ile-ise wa naa n ki Olubadan ku oriire ojo-ibi naa. Emi yoo sopo odun laye.

No comments:

Post a Comment