Monday 31 August 2020


Y K ABASS di Babaloja ipinle Oyo

Yanju Adegboyega

O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii.

Lojo JImoh ose to koja yii ni won fi ewe oye le okunrin gbajumo onisowo aso ilu Ibadan nni, Alaaji Yekeen Abass, eni ti gbogbo eeyan mo si Y K Abass lori gege bi Babaloja ipinle Oyo. Nibi ayeye ohun to waye ni aafin Olubadan ile Ibadan, Oba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunniso Akoko to wa ni Popoyemoja, Ibadan lawon egbe oloja kaakiri ipinle Oyo peju-pese si.

Lasiko ti won n se oro oye ohun fun un, Oba Adetunji salaye pe ta a ba wo awon ipa ti Abass ti ko ninu idagbasoke ipinle Oyo, ko seni to to lati dipo Babaloja mu ju oun naa lo. O ni Babaloja tuntun ohun soriire pupo lati joye lasiko toun n sayeye ojo-ibi odun mejilelaadorun-un pelu afikun pe ifinijoye re ohun lo je aseyori fun gbogbo omo bibi ipinle Oyo.

Olubadan wa sadura fun ibagbepo alaafia laarin awon onisowo nile Ibadan, ipinle Oyo ati orile-ede Naijiria lapapo bi Abass se n di asiwaju awon oloja nipinle Oyo.

Nigba to n soro lori ifinijoye re, Babaloja tuntun, Alaaji Yekeen Abass lu gomina ipinle Oyo, Onimo-ero Seyi Makinde logo-enu fun bo se gb’awon onisowo laaye lati maa ta oja won lasiko ajakale arun COVID-19 to ba gbogbo agbaye finra. Pelu bi ko se je ki won mo inira rara lasiko ohun. Bee lo moriri gbogbo awon oba lalaye nipinle Oyo, paapaa Olubadan fun ipa baba to ko lati rii pe ilu Ibadan n nilosiwaju lasiko re.

Abass wa jeje fun ijoba, awon eeyan ipinle Oyo ati gbogbo awon onisowo poun o nii yan enikeni niposin laarin won. Bee lo si gb’awon oloja nimoran lati maa tele ase ijoba lori ona ati dena itankale arun COVID-19, nitori to si wa pelu wa.

Lara awon to wa nibi ayeye ifinijoye ohun ni awon omo igbimo Olubadan bii Otun Olubadan, Agba Oye Lekan Balogun; Balogun ile Ibadan, Agba Oye Owolabi Olakunlehin; Otun Balogun, Agba Oye Tajudeen Ajibola; Asipa Olubadan, Agba Oye Eddy Oyewele; Asipa Balogun, Agba Oye Gbadamosi Adebimpe, Ekerin Balogun, Agba Oye Kola Adegbola;  Eekarun-un Olubadan, Agba Oye Amidu Ajibade ati Eekarun Balogun Agba Oye Azeez Agagagugu.

 

No comments:

Post a Comment