Monday 17 August 2020

ELEBUIBON pe ipade oso at’aje l’Osogbo

ELEBUIBON pe ipade oso at’aje l’Osogbo

-          Lawon eeyan ba se kayeefi

O O ti jade ninu iwe Iroyin ALARIYA OODUA ose yii.

Nise ni gbogbo awon eeyan to wa nipinle Osun, paapaa niluu Osogbo si soro tiyanu tiyanu lori isele nla kan to waye lojo Tosde ose to koja lo niluu naa, nigba ti okunrin olori elesin ibile nni to tun je Araba ilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon pe ipade akoko awon aje ati oso onilosiwaju, Progressive Witches and Wizards Association.

Ipade ohun to waye ninu ile re to pe ni “Araba Castle niluu Osogbo la gbo pawon aje ati oso kaakiri orile-ede yii peju pese si. Gege ba a se gbo, lasiko ipade pataki ohun, Elebuibon gb’awon omo egbe naa nimoran lati maa imo kun imo nipa ara won. Ki won si agbara ti Olorun fun won lati mu ilosiwaju ba ara won, ki won sit un lo o lati fi ran orile-ede yii lowo pelu.

Leyin naa lo ro awon olori orile-ede yii ati gbogbo awon eso alaabo lati sise lori ona ti opin yoo fi de ba itajesile to n fi gbogbo igba waye. O wa kilo fun gbogbo omo orile-ede yii, paapaa awon elesin isese lati ma ba won lowo si ipaniyan nitori ki won ma ba a pin ninu ijiya to n bo lori gbogbo awon to wa nidii awon isele itaje sile to n waye lorile-ede yii.

Ju gbogbo re lo, awon oso ati aje ti n kora won jo lati maa sepade lati le mu ilosiwaju bara won ati orile-ede yii. Eyi to si waye lojo Tosde ose to koja lakoko re, pelu ireti pe bee ni yoo maa waye lodoodun.

 

No comments:

Post a Comment