Monday 31 August 2020

Ayajo ojo Isese: Awon elesin ibile n beere fun olide lowo ijoba


Ayajo ojo Isese: Awon elesin ibile n beere fun olide lowo ijoba

Yanju Adegboyega

O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii.

Gbogbo ogunjo osu kejo lodoodun ni won ti ya soto gege bi ojo esin ibile lagbaye. Ojo Tosde ose to koja yii si ni ayeye ojo Isese mi-in tun waye lodun yii. Lasiko iwode odun tawon elesin ibile nipinle Oyo se s’aafin Olubadan lati sajoyo odun Isese naa, Aare Isese nipinle Oyo, Oloye Omikunmi Egbelade salaye pe ijoba to kuro nipo nipinle Oyo ko se daadaa to fawon elesin ibile nipa bo se ko lati kede olide fawon elesin ibile fun ojo Isese pelu bi ile igbimo asofin se fowo si ipe ohun.

Omikunmi wa salaye poun nigbagbo pe, ijoba to wa lode bayii ko nii ja won kule. Nitori ti gomina to wa nipo bayii, Onimo-ero Seyi Makinde seleri lasiko to n se ipolongo idibo poun yoo maa kede olide fun ayajo odun Isese.

“O ba wa lokan je pe, Oloogbe Gomina Abiola Ajimobi kuna lati kede ogunjo osu kejo gege bi ojo isinmi fun ayajo odun Isese. A o beere olide Egungun tabi ti Sango. Ayajo ojo odun Isese ti ko gbogbo elesin ibile papo. Gbogbo wa la n se e. Ki lo wa le nibi ki won ya ojo naa soto fun wa?

 

No comments:

Post a Comment