Monday 17 August 2020

O tan! SUNDAY to n paayan l'Akinyele ti sa m'olopaa lowo

O tan! SUNDAY to n paayan l'Akinyele ti sa m'olopaa lowo
Yanju Adegboyega
O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii
Ile-ise olopaa ipinle Oyo ti kede pe omokunrin kan, Sunday Sodipe, eni odun mokandinlogun ti won fura si gege bi odaran to wa nidii ipaniyan nipakupa to n sele nijoba ibile Akinyele niluu Ibadan ti sa mo awon olopaa lowo. 
Ninu atejade kan ti alukoro ile-ise olopaa ipinle Oyo, Ogbeni Fadeyi Olugbenga fi sita lojo Sannde ana, ojo kerindinlogun osu yii ti nomba re je AZ: 5250/OY/PPRO/VOL. 5/159 lo ti salaye pe "Komisanna olopaa, Ogbeni Joe Nwachukwu Enwonwu n lo asiko yii lati so fun gbogbo eeyan ipinle Oyo pe omokunrin afurasi odaran to wa nidii ipaniyan to n fi gbogbo igba waye nijoba ibile Akinyele, Moniya, Ibadan, Sunday Shodipe, eni odun mokandinlogun towo ile-ise olopaa te, ti won si safihan re lolu ile-ise olopaa lojo ketadinlogun osu keje odun yii pelu awon meji mi-in, ti won tun to gbe lo siwaju ile-ejo ti sa kuro ninu ahamo olopaa lojo kokanla osu yii. 
Nitori idi eyi, komisanna olopaa n ro gbogbo eeyan lati foju sode, mu un tabi tete so fun won ni tesan olopaa to ba wa nitosi, ti won ba ri i. O tun lo asiko ohun lati ro enikeni to ba niroyin to le satona lati ri odaran ohun mu, ki won ma fi fale lati fun ile-ise olopaa.
O ni "Komisanna tun n fasiko yii so fun gbogbo eeyan pe, ile-ise olopaa setan lati daabo bo emi ati dukia awon eeyan rere ipinle Oyo. Aabo to peye si wa nile fun gbogbo eni to n pa ofin mo lati maa ba ise oojo won lo lai beru rara pelu ikilo gidi fun enikeni to ba n gbero lati da omi alaafia ilu ru pe ki won ma sun mo ipinle Oyo rara.
Leyin naa lo gba gbogbo awon odo to maa n fiya je odaran lowo ara won nimoran lati dawo iwa bee duro. O ro won lati fa eni yoowu ti won ba fura si le olopaa lowo. O ni "foto Sunday Sodipe lo ti wa lara atejade yii lati ran awon ara-ilu lowo lati le ri i mu. E dakun, e ba wa tan iroyin yii kaakiri, ko le rorun lati tete ri i mu.

 

No comments:

Post a Comment