Monday 7 September 2020

Awon egbe oloja n binu si bi won se fi Y K ABASS je Babaloja ipinle Oyo - Sugbon, SEYI MAKINDE ni t’oba lase


Awon egbe oloja n binu si bi won se fi Y K ABASS je Babaloja ipinle Oyo

-          Sugbon, SEYI MAKINDE ni t’oba lase

Yanju Adegboyega

(O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii)

Nise lo dabi igba ti awuyewuye ti oye Babaloja ipinle Oyo, eyi ti Olubadan ile Ibadan, Oba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunniso akoko atawon omo igbimo re fi okunrin gbajumo onisowo aso nni, Alaaji Yekeen Abass je laipe yii ko tii tan nile. Nitori lose to koja yii lawon egbe oloja kan ti won poruko won ni Coalition of Traders in Oyo State fi atejade kan sita fawon akoroyin pelu ileri pawon setan lati daabo bo iwe ofin egbe.

Ninu atejade tawon asiwaju oloja kan, Komureedi Ajala; Komureedi Abu Abioye ati Komureedi Abileko Oyewo fowo si lojo Tusde ose to koja n’Ibadan, won benu-ate lu ipinnu awon eeyan kan lati da wahala sile ninu egbe oloja.

“won ni o je ohun itiju ati abuku fun awon eeyan kan lati gbero lati gbe olori kan lawon oloja ti won le ni milionu meji nipinle yii lori, lasiko ti gbogbo eeyan n gbadura si Olorun lati ba wa ka’se arun COVID-19 kuro nile nipinle Oyo, ki gbogbo nnkan le pada bo sipo, ki idaamu awon eeyan wa si  sopin.

Awon egbe naa kawon edun okan won sile bayii “Awon oloja lokunrin-lobinrin to le ni milionu meji kaakiri ijoba ibile metalelogun to wa nipinle Oyo fa alaga awon babaloja ati iyaloja l’oja Bodija to tun je alaga alaga awon babaloja ati iyaloja nijoba ibile mokookanla to wa nile Ibadan, Alaaji Sumaila Aderemi Jimoh kale gege bi Babaloja ipinle Oyo.

”Pe nibi ipade ti won ti yan Alaaji Sumaila Aderemi Jimoh nile igbimo awon lobaloba, Sekiteria ijoba ipinle Oyo, Agodi, Ibadan, gbogbo awon babaloja ati iyaloja lati ekun to wa nipinle Oyo peju pese sibe bii Oke Ogun, Ibarapa, Ogbomoso ati ekun mereerin to wa niluu Oyo.

“Pe ilana ti won gba yan Alaaji Sumaila Aderemi Jimoh gege bi Babaloja ipinle Oyo lo gba ona to to, to si ba ohun ti ofin egbe la kale lo. Eyi si ni ko je ko si atako ati wahala titi eto ohun fi pari.

”O ye ka je ko ye gbegbe wa pe, egbe wa, gege bi awon egbe to ku lo foruko sile pelu ajo ijoba Corporate Affairs Commission gege bi ilana ofin orile-ede yii.

“Gege bi enikeni ko se le gbe olori le awon egbe wonyii, NMA, NBA, NFF, NSE, NLC, TUC lori, bee ni yoo soro fun enikeni lati gbe olori kan le egbe wa naa lori. A niwee ofin, ohun la si gbodo tele, ki wahala ma ba a sele.

“A mo, a si nigbagbo pe ololufe alaafia ati eni to nibowo fun ofin ni gomina ipinle Oyo, Onimo-ero Seyi Makinde. Ko si nii fe tako ohun ti ofin wi, eyi toun pelu ti j’anfaani re lasiko ti won p’ejo tako idibo gomina to gbe e wole. Bee sin i gomina ko nii fen i nnkan se pelu ohun yoowu to le da omi alaafia tawon eeyan ipinle Oyo n gbadun lasiko yii ru.

“Bee la si mo, Kabiyesi Alayeluwa, Oba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunnso akoko gege bi eni to maa n gbeja awon eeyan re, olugbelaruge awon eeyan re, eni to maa n dide tako irenije, paapaa irufe eyi to waye yii. Eyi to fara jo eyi ti Oloogbe Seneto Abiola Ajimobi gbiyanju lati se nigba to fee gbona tin ko bofin mu satunse soro oye oba ile Ibadan. O wa lakosile pe, Kabiyesi dide sigbese aburu ohun lai beru.

“Lati kin oro wa leyin pe, Kabiyesi ko nifee irenije. Alayeluwa ti kowe kan ranse si wa ri lori irufe oro yii, eyi ti Adeola Oloko fowo si lojo kerindinlogun osu keje odun yii. Leta ohun ka bayii “Kabiyesi Olubadan ni ki n so fun un pe, gege bi eni to ni ikora-eni nijanu. Kii da soro to ba nii se pelu ohun yoowu to n sele laarin oloja.” Nipa eyi, igbagbo wa ni pawon eeyan kan to mo tara won nikan lo n si Kabiyesi lona lori oro to wa nile yii.

“Egbe wa tun n so pe, Alaaji Sumaila Aderemi JImoh ni ojulowo Babaloja ipinle Oyo, nitori oun nikan nilana ti won fi yan an ba ohun ti ofin so mu. O si l’etoo labe ofin lati maa sise lo gege bi Babaloja titi saa re nipo yoo fi pari pelu afikun po lore-ofe lati yun dije fun saa keji.

Leyin eyi lawon egbe ohun kilo fun eni yoowu to ba n pera re ni Babaloja ipinle Oyo lati ma se bee mo, nitori ti won lawon ko nii yi ese awon kuro lori yiyan Alaaji Sumaila Aderemi Jimoh gege bii Babaloja ipinle Oyo. Won lawon setan lati daabo bo eto awon oloja to le ni milionu meji lai beru ohun ti enikeni le gbiyanju lati se fun won.

Won ni “gege ni eni to nibowo fun ofin, a fe ro gomina ipinle Oyo, Onimo-ero Seyi Makinde, komisanna olopaa, awon olori eso alaabo to ku, awon lobaloba, awon olori elesin, awon olori egbe osise atawon eeyan awujo gbogbo lati tete da soro ohun, ko to di pe yoo di ohun to n da omi alaafia ilu ru.

Sugbon, gomina ipinle Oyo, Onimo-ero Seyi Makinde ti ni t’oba lase. O si ni Alaaji Yekeen Abass ti Olubadan atawon omo igbimo re yan loun faramo gege bi Babaloja ipinle Oyo.

Se lojo Jimoh ose to lo lohun-un ni OLubadan fi Alaaji Abass joye Babaloja ipinle Oyo, sugbon tijoba ipinle Oyo bu enu-ate lu igbese naa. Ninu oro to so lasiko ohun, komisanna fun eto iroyin, Omowe Wasiu Olatunbosun lori eto kan to se lori redio lojo Satide, ojo kokandinlogbon osu kejo lo ti so pe ijoba ko mo pe Olubadan fi Alaaji Abass joye Babaloja ipinle Oyo.

Sugbon, lose to koja yii, lasiko abewo ikini kiu oriire ojo-ibi odun mejilelaadorun-un Olubadan ni Gomina Makinde nijoba oun yoo maa fun awon oba ni gbogbo eto won. Makinde, eni to lo sise egbe oselu PDP nipinle Ondo lasiko ayeye ojo-ibi oba alaye naa ni gbogbo ipinnu re loun faramo.

Gege bo se so “isejoba oun yoo maa se eto to ba ye fun gbogbo awon oba to wa nipinle Oyo ati pe gege bi eni ti won bi daadaa, oun ko nii yaju si agbalagba.

Ninu atejade kan ti akowe iroyin si gomina, Ogbeni Taiwo Adisa fowo si, gomina ro gbogbo awon olugbe ipinle Oyo lati mu ifowosowopo ati isokan lokunkundun.

“Mo fe lo asiko yii lati ro awon eeyan wa lati wa nisokan. Mo ranti pe mo so lasiko ipolongo ibo pe ijoba mi yoo mu igbogun ti ebi ati ise lokunkundun. Ebi ati ise ko mo boya kristeni l’eeyan kan tabi musulumi. Nitori naa, e je ka so fun gbogbo awon to fe fi esin ya wa ki won rin siwaju, ki won si lo se ohun to to.

Gomina te siwaju ninu oro re, o ni “idi ti mo fi wa nibi losan-an yii ni pe, mi o si nile lasiko ayeye ojo-ibi odun mejilelaadorun-un yin to waye lose to koja. Mo wa nipinle Ondo. Nitori naa, mo wa sibi lonii pelu awon omo igbimo alase ijoba lati wa kii yin lona-oto, mo si gbadura pe o pe laye loruko Olorun.”

Gomina Makinde salaye pe, yato sohun tawon eeyan kan n so kiri pe ija wa lara oun ati Kabiyesi. O ni ko le siru re laarin awon rara. To ba si wa, nise lawon maa yanju re bii baba ati omo.

“Gbogbo awon to feran ki won maa gbe iroyin aburu nipa ijoba ipinle Oyo atawon ohun ta a n se nipinle yii lo nija wa laarin emi ati Kabiyesi. E je ki n so fun un yin leekan sii pe, won to mi daadaa, nitori naa mi o nii yaju sagba. Gbogbo eni to ba je gomina ye ko mo pe, ipo yen maa tan leyin odun merin. To ba si tun wu u lati te siwaju, yoo pada wa so fawon eeyan ni.

Tawon eeyan ba si fe e, won yoo tun dibo fun tabi ki won lawon o fe e mo. Sugbon, bawo ni ti Kabiyesi?  To ba ti gori ipo, nibe ni yoo wa, titi digba to ba lo darapo mawon asiwaju re. Nitori naa, ko si nnkan ohun to le dija sile laarin wa.

“Mo tun fe mu un daa yin loju leekan sii, gbogbo ohun to ba ye, la o se gege bi ijoba. Kii se fun Olubadan nikan, fun gbogbo awon oba alaye wa nipinle Oyo ni. A o maa fun won lohun to to si won nigba gbogbo. Toro ba wa, baba le pe mi, a o si yanju re nirowo-irose.

“Awon kan tie so pe, mi o tii wa ki baba lat’igba ti mo ti di gomina. Mo lero pe, ti won ba tun so bee nigba mi-in, awon eeyan ti mo ohun tiwon yoo fi fesi fun, pe ki won fi emi ati baba sile. Ki won koju mo ise won.

Nigba to n fowo siyansipo Babaloja ipinle Oyo, Gomina Makinde ni “mo fe so nibi pe, nigba ti Kabiyesi ti se ipinnu naa, ijoba naa ti lowo sii niyen. Nitori naa, ki won gbe awon igbese to ku, to ye ki won gbe ni. Kabiyesi ko le se ipinnu, ka wa yii danu.”

 


 

No comments:

Post a Comment