Monday 31 August 2020

A o daabo bo ara wa, te o ba le daabo bo wa - awon agbe Ikoyi so fun ijoba Oyo




 

 

A o daabo bo ara wa, te o ba le daabo bo wa - awon agbe Ikoyi so fun ijoba Oyo

Yanju Adegboyega

O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii.

Awon agbe ati gbogbo olugbe ilu IKoyi-Ile nipinle Oyo ti salaye po see se kawon bere sii daabo bo ara awon lowo awon fulani daran-daran to n fi gbogbo igba ko lu won, se won lese ati pa won nipakupa tijoba ipinle Oyo ba kuna lati daabo bo won.

Awon agbe yii lo ni laipe yii lawon Fulani ohun pa okan ninu won, ti won fipa bawon omo awon lopo. Ti won si tun ba gbogbo oko won je. Awon eeyan naa ni, isele aburu ohun si ni ko je kawon loju oorun rara mo. Nigba to n soro fawon akoroyin, Babalaje Agbe nijoba ibile Oriire, Oloye Oyekola Joseph salaye pe, lati bi odun mejo seyin lawon agbe ilu naa ko ti nifokanbale rara. O si wa ke sijoba ipinle Oyo lati tete wa nnkan se soro ohun, ko to di pe yoo koja ohun tapa re yoo ka.

Oyekola, eni to tun je akowe fun egbe Idera Agbe, eka tijoba ibile Oriire ni “a o tie mo nnkan ta a le se, nitori ta a ba ni ka gbe igbese tabi ka gbesan. O le fa itaje sile. A fe kijoba ran wa lowo, ki won si gbe igbese to ye. Nitori, oba wa to ye ko ko daabo bo wa lo kuna, to si je pee yin awon Bororo yii lo n gbe si.

“Awon daran-daran yii ge owo okan ninu awon osise wa to n sise ninu oko. Won ba gbogbo ire oko wa je. Won sa agbe kan naa ladaa lori, ti won si se awon mi-in lese. Omobinrin wa meji si ni won tun fipa ba lopo.

Okan lara awon agbe naa to n je Usman Daudu ni ogun sare oko agbado, isu, tomato atawon ire oko mi-in lawon daran-daran yii baje. Bee si ni won sa oun ladaa lori lasiko toun n gbiyanju lati le won kuro ninu oko naa.

“Won o dawo ikolu duro lawon oko wa. Aimoye igba la ti be won, sugbon to je eyin eti won ni gbogbo ebe wa n bo si. Bororo ni won, nitori ta o nisoro pelu awon Fulani to ti wa nibi tele.

Agbe mi-in toro ohun tun kan, Dominic Gbegi ni eemerinla ni won sa oun ladaa lasiko toun n gbiyanju lati le awon daran-daran ohun to ko maalu wonu oko oun, ti won si ba gbogbo ire oko je.

Nigba to n soro lori isele ohun, Onikoyi ti Ikoyi-Ile, Oba Abdul-Yekeen Atilola Oladipupo ni gbogbo ipa loun ti sa lati le mu ki alaafin joba laarin awon agbe atawon daranm-daran yii pelu afikun p’oro wahala agbe atawon daran-daran kii soro ilu oun nikan, bi ko se oro gbogbo agbegbe kaakiri.

Gege bo se so “Gbogbo ona lati gba lati mu ki alaafia joba laarin won, nitori pa o le ya agbe ati daran-daran. A ti jo n gbe papo ojo se die. Opo igbese ni mo ti gbe lori oro ohun lati wa opin si i, sugbon o dabi eni pe igbiyanju mi ko to. A fe kijoba ba wad a si i.

“Mo ti se okan-o-jokan ipade pelu awon baale to wa lagbegbe yii lati wa opin sisele ohun. Koda, mo sepade pelu igbakeji oga agba olopaa orile-ede yii l’Osogbo pelu komisanna olopaa. Awon olopaa si seleri fun mi lati ba wa nnkan se si i.

Oba alaye yii wa ke si gomina ipinle Oyo, Onimo-ero Seyi Makinde, ile igbimo asofin ipinle Oyo atawon ile-ise alaabo gbogbo lati dakun wa nnkan se soro ohun, ko to di po koja ohun towo le ka, nitori toun o fe itaje sile mo niluu naa.

Okan lara awon ilu to ti pe nile ni Ikoyi-Ile nijoba ibile Oriire, ipinle Oyo. Awon abule to to orinlelegbeta din mefa, 674 lo si yii ka. Awon bii Olode-Elu, Animashaun, Obamo, Igboayin,Laomi atawon mi-in bee bee lo.

O ma se o! adigunjale yinbo pa TAOREED leyin to gb’owo tan ni banki n’Ibadan


O ma se o! adigunjale yinbo pa TAOREED leyin to gb’owo tan ni banki n’Ibadan

Yanju Adegboyega

o ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii.

Ko seni to ri oku okunrin eni odun marundinlaadota kan, Taorred Alao tawon adigunjale yinbon pa lojo Monde ose to koja niluu Ibadan, ti ko mu omi loju. Taoreed lawon adigunjale kan ti enikeni ko tii mo yinbon pa loju ona to ti sekiteriati ijoba ipinle Oyo lo sile ijoba l’Agodi, Ibadan. Gege ba a se gbo, awon adigunjale ohun lo ti n tele Taoreed ni kete to gb’owo ni banki kan ni Bodija.

Akoroyin wa gbo pawon adigunjale eleni meji ohun lo wa lori okada kan, ti won si ya okada ti Taoreed gun sile niwaju ile-ise ijoba ipinle oyo to n ri si oro ayika. Leyin naa si ni won yinbon fun un. A gbo pe, bi won se yinbon fun un tan ni won gbe baagi kekere kan to kowo to gba ni banki ohun si. Bee si ni won tun gbe okada re lo. Enikan tisele ohun soju re ni owo to wa ninu baagi naa yoo to egberun lona eedegbeta naira, N500, 000.

Nigba to n fidii isele aburu naa mule, alukoro ile-ise olopaa ipinle Oyo, Ogbeni Olugbenga Fadeyi ni eemeji ni won yinbon fun Taoreed pelu afikun pe won gbe owo kan ti enikeni ko mo iye to to, eyi to lo gba ni banki lo, bee si ni won gbe okada Bajaj re lo pelu.

Fadeyi safikun oro re pe loju ese ni won sare gbe Alao lo sile-iwosan Adeoyo to wa laduugbo Ring Road. Nibe si ni won ti so po ti ku, ti won si ti gbe oku re pamo sile igbokusi to wa nibe.

Ninu oro re “Iroyin to to mi lowo lati odo oga olopaa tesan to wa nitosi ibi isele ohun ni pe, ni deedee aago mejila ku iseju meedogun aaro, ladojuko ile-ise ijoba ipinle oyo to n ri si oro ayika, awon kan yinbon fun enikan ti won poruko re ni  Taoreed Alao, eni odun marundinlaadota ti won si gbe okada Bajaj re salo.

”Loju ese ni won sare gbe e lo sile-iwosan Adeoyo, nibi to pada ku si. Iroyin fi ye wa pe nise lawon eeyan ohun telee lati banki olokoowo kan laduugbo Bodija debi ti won ti yinbon fun un naa.

“Foonu meji ati owo to to egberun lona aadorun naira ni won ba lara re. Won si ti gbe oku re pamo sile igbokusi to wa ni ile-iwosan Adeoyo nibe.

Alukoro ile-ise olopaa ipinle Oyo wa salaye pawon olopaa ti n topase awon to sise aburu ohun pelu afikun pe laipe lowo yoo te won.

 

Wahala PDP, won lu ADELEKE, eeyan GOMINA SEYI MAKINDE nilukulu l’Abuja


 

Wahala PDP, won lu ADELEKE, eeyan GOMINA SEYI MAKINDE nilukulu l’Abuja

Yanju Adegboyega

O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii.

Nise lawon eeyan kan tinu n bi ninu egbe oselu alaburada, PDP sadeede ki alaga ile-ise ijoba ipinle Oyo to pese moto akero fawon ara-ilu, Pacesetter Transport Services, Ogbeni Dare Adeleke mole lojo Monde ose to koja, ti won si lu u nilukulu lolu ile-ise egbe oselu naa niluu Abuja.

Gege ba a se gbo, Adeleke to je okan ninu awon to sun mo gomina ipinle Oyo, Onimo-ero Seyi Makinde ni won sese yan gege bi akowe igbimo ti yoo seto ayewo fawon to fe dije ninu idibo abenu egbe oselu PDP ninu atundi ibo kan ti yoo waye sipo omo ile igbimo asofin agba ni ariwa ipinle Cross River.

Sugbon, nnkan yidande lasiko ti Adeleke fe lo gba leta iyansipo re ohun nile egbe oselu PDP l’Abuja, nigba tawon kan tinu n bi ki i mole. Ti won si lu u nilukulu. Ninu iwe ehonu kan to ko si alaga apapo egbe oselu PDP lorile-ede yii, Omooba Uche Secondus, Adeleke beere pe kawon to lu u naa foju wina ijiya lowo igbimo to n ri si iwa ibaje ninu egbe.

Nigba to n salaye bi won se kolu u naa, Adeleke ninu iwe ehonu re ni “lojo Monde ojo kerinlelogun osu kejo odun yii, mo de olu ile egbe oselu PDP to wa nile Wadata, Zone 5 ni deedee aago mewaa aaro lati se awon ise ilu kan gege bi mo se je akowe fun igbimo ti yoo sayewo fun atundi ibo sile igbimo asofin ariwa ipinle Cross River.

”Mo wo ofiisi akowe eto gbogbo egbe wa, lati gba leta iyansipo mi, nibe si ni mo ti ri alaga igbimo ti yoo sayewo ohun pelu awon eeyan kan. Bi mo se n gba leta mi tan ni Amofin Alphonsus Eba, Onorebu Chris Njar Mbu atawon meta mi-in sadeede kolu mi. Bi won se n fun nikuuku, ni won n gba mi loju-nimu, ti wo  si ya mi l’aso. Mo gbiyanju lati ja ajabo lowo awon eeyan yii, bi won se ja leta iyansipo mi atawon iwe mi-in ti mo mu dani lowo mi. Opelope awon olopaa atawon eso alaabo mi-in to wa nibe, ni mo fi ja ajabo lowo awon eeyan naa.

Adeleke tun salaye pawon eeyan ohun dunkooko mo oun lati ma wa sipinle Cross River, nitori ti won le pa oun nibe. Akoroyin wa gbo lenu enikan to sun mo olu ile egbe oselu PDP daadaa, sugbon ti ko fe ki won daruko oun pawon eeyan kan to sun mo gomina ipinle Ekiti tele, Ogbeni Ayo Fayose lo ti awon

 

O tan! Won mu EMMANUEL ti won lo f’igbe je buredi n’Ibadan


 

O tan! Won mu EMMANUEL ti won lo f’igbe je buredi n’Ibadan

Yanju Adegboyega

O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii.

Ile-ise olopaa ipinle Oyo ti salaye pe, okunrin kan, Ammanuel Egbu tawon eeyan kan desun kan po n fi igbe eeyan je buredi ti wa lowo awon bayii. Lojo Satide ojo kejilelogun osu yii ni won mu okunrin naa, nibi ti won ti lo n fi igbe je buredi.

Gege ba a se gbo, Egbu, eni to ni soobu to ti n ta awon irun tawon obinrin fi n soge, Brazilian hair lawon eeyan kan mu ninu soobu re to wa laduugbo Sango, Ibadan. Awon to mu un ohun ti koko fi oju re han gbogbo eeyan. Koda, won tun ji gbogbo oja to wa ninu soobu re ko salo.

Nigba to n fidii isele ohun mule, alukoro ile-ise olopaa ipinle Oyo, Ogbeni OLugbenga Fadeyi ni “oga olopaa tesan to wa laduugbo naa so fun mi pawon eeyan kan lo gba okunrin naa sile lowo awon to fesun kan an po n fi igbe je buredi. Won ni won baa won igbe to ko sinu ora lowo re. Won si mu un wa si tesan olopaa.

“Oga olopaa naa ti bere igbese lori esun ohun, okunrin ti won fesun kan yii si ti wa lahamo. O ti bere iwadii to ye, bee si ni won ti mu ninu ohun ti won ni won ba lowo re lati mu lo sibi ti won yoo ti sayewo lona igbalode si i lati mo boya igbe ni tabi kii se igbe.

“O ti gba oro lenu eni ti won fesun kan naa, leyin ti gbogbo iwadii ba si pari, o see se ki won gbe oro ohun lo si eka ile-ise olopaa to wa fun iwadii ofin n’Iyaganku fun iwadii siwaju sii. Iwadii si ni yoo so, boya aajo owo lo n se tabi bee ko.


Y K ABASS di Babaloja ipinle Oyo

Yanju Adegboyega

O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii.

Lojo JImoh ose to koja yii ni won fi ewe oye le okunrin gbajumo onisowo aso ilu Ibadan nni, Alaaji Yekeen Abass, eni ti gbogbo eeyan mo si Y K Abass lori gege bi Babaloja ipinle Oyo. Nibi ayeye ohun to waye ni aafin Olubadan ile Ibadan, Oba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunniso Akoko to wa ni Popoyemoja, Ibadan lawon egbe oloja kaakiri ipinle Oyo peju-pese si.

Lasiko ti won n se oro oye ohun fun un, Oba Adetunji salaye pe ta a ba wo awon ipa ti Abass ti ko ninu idagbasoke ipinle Oyo, ko seni to to lati dipo Babaloja mu ju oun naa lo. O ni Babaloja tuntun ohun soriire pupo lati joye lasiko toun n sayeye ojo-ibi odun mejilelaadorun-un pelu afikun pe ifinijoye re ohun lo je aseyori fun gbogbo omo bibi ipinle Oyo.

Olubadan wa sadura fun ibagbepo alaafia laarin awon onisowo nile Ibadan, ipinle Oyo ati orile-ede Naijiria lapapo bi Abass se n di asiwaju awon oloja nipinle Oyo.

Nigba to n soro lori ifinijoye re, Babaloja tuntun, Alaaji Yekeen Abass lu gomina ipinle Oyo, Onimo-ero Seyi Makinde logo-enu fun bo se gb’awon onisowo laaye lati maa ta oja won lasiko ajakale arun COVID-19 to ba gbogbo agbaye finra. Pelu bi ko se je ki won mo inira rara lasiko ohun. Bee lo moriri gbogbo awon oba lalaye nipinle Oyo, paapaa Olubadan fun ipa baba to ko lati rii pe ilu Ibadan n nilosiwaju lasiko re.

Abass wa jeje fun ijoba, awon eeyan ipinle Oyo ati gbogbo awon onisowo poun o nii yan enikeni niposin laarin won. Bee lo si gb’awon oloja nimoran lati maa tele ase ijoba lori ona ati dena itankale arun COVID-19, nitori to si wa pelu wa.

Lara awon to wa nibi ayeye ifinijoye ohun ni awon omo igbimo Olubadan bii Otun Olubadan, Agba Oye Lekan Balogun; Balogun ile Ibadan, Agba Oye Owolabi Olakunlehin; Otun Balogun, Agba Oye Tajudeen Ajibola; Asipa Olubadan, Agba Oye Eddy Oyewele; Asipa Balogun, Agba Oye Gbadamosi Adebimpe, Ekerin Balogun, Agba Oye Kola Adegbola;  Eekarun-un Olubadan, Agba Oye Amidu Ajibade ati Eekarun Balogun Agba Oye Azeez Agagagugu.