Monday 14 September 2020

EFFC mu awon omo iya meji fun Yahoo-Yahoo n’Ibadan


EFFC mu awon omo iya meji fun Yahoo-Yahoo n’Ibadan

-won tun ba ose dudu ati oogun lowo won

Yanju Adegboyega

( O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii)

Awon osise ajo to n gbogun ti sise owo ilu nisekuse, EFCC, eka tiluu Ibadan ti mu awon omo iya kan naa meji atawon eeyan meta mi-in fun esun pe won n lu jibiti lori ero ayelujara. Awon omo iya kan naa meji ohun ni Ayoola Timilehin, Olusola Timilehin, ati Oladayo Fayemi, Tolulope Fayemi pelu awon meta mi-in.

Gege ba a se gbo, lojo wesde ojo kesan-an osu yii ni won mu awon eeyan ohun nibi ti won fara pamo si laduugbo Alaka, Elebu niluu Ibadan. Awon meta to ku ni Temitope Kumuyi, Babatunde Oyelakin ati Olanrewaju Ibrahim. Gbogbo won si l’ojo ori won wa laarin ogun si ogbon odun.

Akoroyin wa gbo pe, ajo EFCC mu awon eeyan ohun nipase ise iwadii to fi han pe, won n gbe igbe aye omo jaye jaye lai ni ise kan pato, ti won fi n r’owo.

Lara awon nnkan ti won gba lowo won ni igba kan ti ose dudu wa ninu re atawon oogun abenu gongo mi-in. Moto ayokele merin; ero komputa alagbeka; awon foonu olowo iyebiye ati sitampu eka to n pawo wole nile-eko imo isegun oyinbo ni yunifasiti Queensland lorile-ede Australia. Ni kete tise iwadii bat i pari lori won ni won yoo foju ba ile-ejo.

 

 

No comments:

Post a Comment