Monday 7 September 2020

Kii sawon apani setutu lo pa MARY n’Ibadan – Ile-ise olopaa


 

Kii sawon apani setutu lo pa MARY n’Ibadan – Ile-ise olopaa

Yanju Adegboyega

(O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii)

Ile-ise olopaa ipinle Oyo ti salaye pe iku omobinrin kan, Mary Daraqmola to waye niluu Alabata nijoba ibile Akinyele n’Ibadan ta a gbe iroyin re jade lose to koja kii se lati owo awon to n pani setutu ola gege bawon eeyan kan se n so kaakiri. Ninu atejade kan to fi sita loruko komisanna olopaa, Joe Nwachukwu Enwonwu, alukoro ile-ise olopaa ipinle Oyo, Ogbeni Olugbenga Fadeyii salaye pe, akiyesi komisanna olopaa ti lo sibi iroyin kan lori ikanni ayelujara atawon iwe iroyin kan to ni “won tun fipa ba omobinrin mi-in lopo, ti won si pa a laduugbo kan n’Ibadan.”

O ni komisanna olopaa fe lo asiko yii lati so fun gbogbo eeyan pe, kii sawon to n pani setutu ola lo pa omobinrin ohun gege bawon eeyan se n so kiri. O salaye pe oga olopaa tesan Moniya so pe lojo Monde ojo kerinlelogun osu kejo ni deedee aago mejo ale, enikan ti won poruko re ni Toheeb Ganiyu ni ilu Alabata, ijoba ibile Akinyele mu orebinrin re, Daramola Mary, eni odun mejidinlogun lo sile re. O fun ni opolopo oti bia mu, ko to di po ba a lajosepo.

Leyin eyi ni won ri oku Mary pelu ato-okunrin loju-ara re pelu eje lenu re. Loju-ese nibe si ni won ti mu afurasi yii fun iwadii ni olu ile-ise olopaa to wa ni Moniya nibi ti won ti gba oro sile lenu re ki won to gbe e ranse si eka ile-ise olopaa to n wadii iwa odaran n’Iyaganku nibi to wa lahamo bayii fun iwadii siwaju sii.

Fadeyi ni “komisanna olopaa fe ko ye gbogbo eeyan pe, isele ohun kii se ti awon to n pani setutu rara, gege bawon eeyan kan se n gbe e kiri lori ikanni ayelujara. Isele ipaniyan laarin awon ololufe meji ni. Komisanna si wa lo asiko yii lati ro gbogbo obi ati alagbato lati maa so irinsi awon omo won atawon ibi ti won n rin si lati le dena irufe isele aburu bayii lawujo wa. Yato seyii, komisanna gbawon odo nimoran lati maa wa nnkan gidi, eyi to le mu won nise owo, imo ati ibowo ara-eni. Ki won si jina sawon ohun to le mu ki omi alaafia ilu daru.

Lakootan, o nile-ise olopaa setan lati daabo bo emi ati dukia awon eeyan rere ipinle Oyo pelu afikun pe komisanna olopaa ni eto-abo to peye wa kaakiri tibu-tooro ile Ibadan atipinle Oyo lapapo ba a se n wonu awon osu “ba ba ba” yii.

 

No comments:

Post a Comment