Monday 14 September 2020

Amotekun: Eyi nidi ta o fi kanju lati gb’aayan –Togun

 

Amotekun: Eyi nidi ta o fi kanju lati gb’aayan –Togun

Yanju Adegboyega

(O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii)

Alaga eso alaabo ile Yoruba, ti won n da pe ni Amotekun nipinle Oyo, Ajagun-feyinti Kunle Togun ti salaye idi ti won o fi kanju lati gbawon eeyan ti yoo sise ninu iko ohun. Ojo wesde ose to koja ni Togun salaye idi ohun fakoroyin lasiko ti won n sayewo fawon to ti fife han lati sise ninu iko ohun.

Awon osise ile-ise alaabo DSS, Sifu Difensi atawon osise ogba ti won ti n tun eeyan ro lo n sayewo finni finni fawon eeyan naa. Togun, eni to ti figba kan je oludari ni eka otelemuye nile-ise oloogun orile-ede yii salaye pe igbese ayewo yii lo waye lati le je kawon ile-ise eso alaabo yo awon kanda kuro ninu iresi awon eeyan to fe gba’se Amotekun. O ni “igbese yii, yoo fun wa lanfaani lati mo awon wo lo ni akosile iwa odaran ri ninu won.

Awon eeyan to to egberun meji nireti wa pe, won yoo gba ninu ayewo to n lo lowo yii.

Ninu oro re, Togun ni “Amotekun yoo din iwa odaran ku jojo, to ba bere ise, paapaa lawon igberiko wa gbogbo. Ojo wesde la bere igbani sise ati ayewo finni finni fun gbogbo awon eeyan to ti fife han lati sise ninu iko alaabo Amotekun. Awon to nifee lati sise ninu re si ti n yoju. A si n se ayewo fun won, lati mo taa ni won gan.

 “A o fe gba awon odran sinu iko alaabo naa. Idi si niyii ta a se n sora ninu gbogbo igbese wa. A o fe kanju, ka wa lo se asise.”

No comments:

Post a Comment