Monday 7 September 2020

Bi mo se pade ADEDIBU, ki n too se omoleyin re fun ogbon odun o le – Baba Super



 

Bi mo se pade ADEDIBU, ki n too se omoleyin re fun ogbon odun o le  – Baba Super

 (O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii)

Alagba Gabriel Okoeda, eni ti gbogbo eeyan tun mo si “Baba Super” ni olowo-otun fun okunrin agba oselu ile Ibadan atipinle Oyo tele nni, Oloye Lamidi Ariyibi Adedibu. Oun lo wa nidii owo ti baba naa yoo ban a nigba aye re, okan pataki si ni ninu awon osise to pe julo lati ba okunrin naa sise ni, o si le l’ogbon odun to fi ba a sise. Koda, o wa pelu re titi dasiko iku baba naa lojo kokanla osu kefa odun 2008. Lojo Sannde ose to koja yii, ojo kokandinlogbon osu kejo odun yii lo pe eni odun marundinlogorin. Akoroyin wa, YANJU ADEGBOYEGA forowero pelu re nibi to ti so bo se rawon okan-o-jokan oruko inagije tawon eeyan n pe e bii African Strongest man, Baba Super No Mercy, Try ati See Double, The Son of God atawon mi-in gbogbo.. Abo ree.

-          Nje a le mo yin?

-          E seun, gege bi mo se so saaju. Oruko mi ni Alagba Gabriel Okoeda, omo bibi ilu Esan nipinle Edo, orile-ede Nigeria ni mi.

Mo darapo mo ile-ise omo oloogun orile-ede yii lodun 1967 ni Benin, won sig be mi lo siluu Abeokuta fun ekose ogun. Leyin naa ni won gbe mi lo sawon ile-ise omo oloogun bii 3rd Marine Commando, 13 Brigade, ati 8 Battalion labe Ogagun Benjamin Adekunle, eni ti gbogbo eeyan mo si Black Scorpion nigba to fi wa ni Ila Oorun orile-ede yii atijo.

Bo tie je pe, elere idaraya ni mi lasiko ti mo fi wa ninu ise oloogun, sibe mo kopa ninu ogun abele to waye laarin odun 1967 si 1970. Ni kete ti mo si kuro ninu ise oloogun, mo mu ise ijakadi Judo nise. Bee si ni mo maa n gbe irin wuwo, weight atawon ere idaraya mi-in bee bee lo. Nibe sin i mo ti gba ami-eye okunrin to lagbara julo nile Africa, (African Strongest man.

-          Bawo le se ri inagije "Super No Mercy"?

-          E seun. Lasiko ogun abele orile-ede yii laarin odun 1967 si 1970 ni mo gba gbogbo inagije mi bii "Super No Mercy, Try and See Double, Son of God". Lasiko ija yen ni.

Emi ni mo wa nidii ibon Machine gun. Gbogbo igba yoowu tija ba si wa, nise ni mo maa n j alai laanu enikeni. Ti ma a maa dana ibon ya awon ota. Awon omo oloogun to si wa nibe, to n gbadun bi mo se n lo ibon yen lo so mi ni “Super N Mercy.”

-          Bawo le se salabaapade asiwaju oloselu ile Ibadan. Oloogbe Alaaji Lamidi Adedibu?

-          Lasiko ti mo wa ni ajo to n mojuto oro ere idaraya laarin odun 1979 si 1980 ni mo pade Alaaji Lamidi Adedibu gege bi olori awon to n gbe irin wuwo akoko. Ni kete ti mo kuro ninu ise oloogun ni. Ipase awon asiwaju mi kan nidii ijakadi “Judo, Henry ati Patrick. Omo iya kan lawon mejeeji yii

Won mu mi mo on lati maa sise pelu re, nitori ti won lawon mo pe maa wulo fun un, paapaa nitori agbara ti mo ni.

Se ka si so tooto. Olorun fun mi ni agbara kan, to je pe mo le koju eeyan marun-un loju ija leekan naa. Leyin to si ti sedanwo fun mi, Adedibu gba mi lati sise fun un.

B’odun se n gori odun, mo di osise re to fokan tan julo. Emi ni mow a nidii ounje ti yoo je, owo mi ni gbogbo owo re n wa atawon nnkan mi-in ti ko le fi sowo elomi-in.

-          Igbagbo awon eeyan kan ni p’eeyan lile ati ika ni Adedibu. Won a tie maa pe e ni Alaafin Molete. Nje ooto?

-          Se e ri i. Adedibu kii se ika eeyan rara. O le j’eeyan lile. Idi eyi si ni p’asiwaju to mo nnkan to n fe ati oloselu ni. Ko nii faaye gba iyanje laelae. Iyen lo si je kawon eeyan maa ro pe ika ni

-          Gbogbo nnkan to ba ni, ni yoo lo lati gbeja eni yoowu to ba nigbagbo pe won yan je lori ohunkohun tabi nipa ile. Leyin to ba si ti sewadii re daadaa, Adedibu yoo rii daju p’eni naa gba idajo ododo, bo ti wu ko nira to.

Ibukun nla nigbesi aye re je fun emi atawon eeyan mi lasiko to wa laye. Eeyan to le ni ogorun meta lo n fun l’ounje lojumo l’aafin Molete. Iyen si ni won fi n pe oselu re ni “Oselu Amala”

Asiwaju oselu to mo nnkan to n fe, to si loju aanu ni. Ko tii seni to le t’ese bo bata to bo sile lat’igba to ti ku. Bi okan lara molebi re lo se maa n se mi. Iwaju ni mo wa l’aafin re ni Molete. Emi ni mo n dari gbogbo eto, owo atawon ise ile fun un.

-          Bawo le se le sapejuwe irufe oselu re?

-          Oselu Adedibu je oselu to n fi gbogbo igba ja fun awon mekunnu. O korira iyanje pupo. Ko sigba t’eeyan ba iranlowo dodo re, ti ko nii se e. Iyen lo si je ki won maa pe oselu re ni “Oselu Amala.” O lawo pupo. Oore-ofe ni mo ni lati ba a sise po.

-          Nje e le so fun wa nipa wakati ti won lo gbeyin laye?

-          Oh! O dun ni pupo. Ojo kokanla osu kefa odun 2008 ni. Lojo yen, o ni ki n tete de sile oun laaro. Nitori to n gbero lati lo fun ayewo ilera l’Ekoo. Nigba to si n pad abo s’Ibadan, o ni ki n rii p’ounje oun ti wa nile. O n pe mi ni gbogbo igba lati ran mi l’eti p’ounje oun ti wa nile. Bee si ni mo n lo so fun Alaaja Bose lati yara si sise ounje Baba ati pe Baba ti wa loju ona.

Oun ati igbakeji gomina ipinle Oyo tele, Alaaji Azeem GBolarumi atawon kan lo jo lo. Bo se de s’Ibadan. Ofiisi ajo to n ri si iwole-wode lorile-ede yii lo lo l’Agodi lati lo fowo sawon iwe kan. Sugbon, siyalenu mi, ipe kan wole sori foonu mi pe, Baba Adedibu ti subu, won si ti gbe e digbadigba lo sile-iwosan UCH, Ibadan. Leyin naa si ni won lo ti ku.

-          Bawo le se gba iroyin iku re?

-          Mo gba iroyin iku Baba Adedibu pelu ibanuje okan. Nise lo re mi, nigba ti mo gbo iroyin ohun.

Isele yen so gbogbo wa sinu idaro. Bi iroyin yen si se n tan kale lawon ero, oloselu, omokunrin, omobinrin alajose ninu oselu atawon ara-ilu mi-in n ya wa sile re ni Molete. Nise niroyin ohun n tan bi ina papa ninu eerun. Asiko ibanuje gbaa ni fun ipinle Oyo.

Ojo ti mi o le gbagbe kiakia ni. Iru re sowon l’eeyan. Opo awon eeyan te e n wo nipo giga lonii lo je Adedibu lo gbe won debe. Ko tii si oloselu naa to niru agbara ti Adedibu ni lat’igba to ti ku.

Eni to gboya pupo, to si nigbagbo ninu adura ni, paapaa ninu Kuraani ati Bibeli. Awon kan nigbagbo po maa n s’oogun. Eyi kii sooto rara. Opo awon pasito ati lemoomu le jerii sii po nigbagbo pupo ninu Bibeli ati Kuraani.

-          E n sayeye ojo-ibi odun marundinlogorin yin bayii. Eko wo le fe kawon eeyan ko lara iriri yin lasiko te e fi ba oga yin tele, Adedibu sise?

-          Ayeye ojo-ibi odun marundinlogorin je idupe si Olorun, oga ogo fun gbogbo ohun ti mo ti se laye mi.

O je asiko ti mo fi n ranti oore-ofe Olorun to mu mi la opo iriri koja nile aye. Mo sin Adedibu pelu okan otito ati ododo fun ogbon odun le.

-          E seun fun anfaani yii.

-          Eyin le se ju. Eyin naa yoo dagba.

No comments:

Post a Comment