Wednesday 30 September 2020

O ma se o! SULE ADIGUN, olorin Fuji ku n’Ibadan

O ma se o! SULE ADIGUN, olorin Fuji ku n’Ibadan

Lojo Tosde ose to koja yii niroyin iku okan lara awon agba-oje olorin Fuji niluu Ibadan, Alaaji Sulaimon Adigun Oladimeji tun gba gbogbo ilu kan. Iku Sule Adigun yii, eni tawon eeyan tun maa n pe ni “Katapila” nitori bo se ga, to si sigbonle lo waye lai tii p’osu meta leyin ti okunrin onifuji mi-in to tun je akowe apapo egbe awon onifuji lorile-ede yii, FUMAN, Alaaji Ganiyu Iyanda Composee naa ku.

Gege ba a se gbo, Adigun ko fi bee saisan rara, to fi pada ku naa. Se ni nnkan bi odun meloo seyin la gbe iroyin kan jade pawon dokita nile-iwosan ekose isegun UCH gee se re kan, nitori ti egbo kan to mu un l’ese ko san, eyi ti won ni aisan ito-suga ti won lo n se e lo fa a.

Okan lara awon gbajumo olorin fuji to lo saa niwon odun 1970 si 1980 ni Sule Adigun. Okan pataki si ni lara awon oje wewe olorin asiko re to wa leyin Alaaji Sikiru Ayinde Barrister lati maa korin bu Alaaji Kollington Ayinla ni nigba ti ija awon mejeeji n lo ni pereu.

 

Okan ninu awon to sun mo on daadaa, eni to ti figba kan je gomina egbe awon olorin Fuji nipinle Oyo, Alaaji Taofeek Alagbe Omoowo lasiko to n bakoroyin wa soro salaye pe, iku adanu nla niku Adigun fun eka amuludun ati egbe awon olorin Fuji lorile-ede yii. O sapejuwe re gege bi eeyan lile, ti ko feran iyanje. Sugbon o l’eeyan daadaa ni pelu.

 

Omo bibi adugbo Agbeni niluu Ibadan ni Adigun. Bo tie je pa o mo pupo nipa kekere re, sugbon,odo okunrin kan ti won poruko re ni Sule Ajangidi la gbo po ti bere orin kiko re lasiko Ajiwere/Ajisaari. Gege ba a se gbo, Ajangidi lo maa n ko awon omode to ba lebun orin jo lati maa fi won se idije lasiko aawe awon Musulumi. Akoroyin wa gbo pe, Oloogbe Sikiru Ayinde Majester lasiwaju awon olorin to wa lodo Ajangidi ki Adigun to de. Nigba ti Adigun si de, Ajangidi gba tie ju Majester lo, eyi lo si je ki Majester kuro nibe lati lo bere egbe olorin tie.

Ni gbogbo asiko to wa lodo Ajangidi yii, Adigun tun maa n lo lu ilu kan ti won pe ni “Agbamole” fun okunrin olorin Awurebe kan, Sulaimon Asanke. Leyin naa lo tun pada lo gbe orin leyin Alagba Dele Orijin.

Iwadii akoroyin wa fi ye wa pe, ni nnkan bi ose meloo seyin lo sakiyesi pee se re ti won ge tun ti fe maa ran eyi ti won ko ge. Sugbon, ti ko seni to mo igbese to gbe lori re, titi dasiko ti won kede iku re lojo Tosde ose to koja yii.

Oun ni igbakeji aare egbe onifuji, FUMAN akoko lasiko isejoba Alaaji Saka Orobo. Opo awon ilu bii Lalupon, Iwo, Ilobu atawon mi-in bee bee lo la gbo po ti joye lasiko to si wa loju opon nidii ise orin. Ojo Tosde naa la si gbo pe won ti sin oku re nilana esin Musulumi sile akobi re ti won poruko re ni Akeem to wa laduugbo Arapaja, Odo-Ona kekere, Ibadan.

 

No comments:

Post a Comment