Monday 14 September 2020

O sele! Ipo asiwaju PDP nile Yoruba dija laarin MAKINDE ati FAYOSE



 

 

O sele! Ipo asiwaju PDP nile Yoruba dija laarin MAKINDE ati FAYOSE

Yanju Adegboyega

( O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii)

Oro ta a ni yoo di asiwaju egbe oselu PDP lekun Iwo Oorun orile-ede yii, iyen ile Yoruba ti dija nla laarin gomina ipinle Ekiti tele, Ogbeni Ayodele Fayose ati gomina ipinle Oyo bayii, Onimo-ero Seyi Makinde. Gege ba a se gbo, oro ta a ni yoo dari egbe oselu naa saaju asiko ti idibo egbe lekun naa yoo waye ohun lo ti fe fo egbe naa si wewe.

Akoroyin wa gbo pawon agbaagba egbe kan lo ti n sise tako Makinde lati je asiwaju egbe, bo tie je p’oun ni omo egbe ti ipo re ga julo lekun idibo ohun, nitori ipo re gege bi gomina. Sugbon, tawon eeyan yii n san gbogbo ona lati din agbara re ku ninu eka egbe naa. Awon eeyan kan to bakoroyin wa soro ninu egbe naa ni ote to dide si Makinde ohun ko se lori aba to da pe ki Fayose ati Seneto Biodun Olujinmi lo lo ilana oselu lati petu si wahala to sele laarin awon mejeeji lori idibo abele woodu egbe to waye nipinle Ekiti, eyi ti won pada fagile.

Gege ba a se gbo, awon igun ti Olujinmi ti faramo ki won lo ilana oselu, eyi ti yoo je ki won pin ipo ni ida ogoji si ogota. Sugbon, igun ti Fayose ko faramo ilana naa rara. Nise ni won fe gba gbogbo akoso egbe patapata.

Ta o ba gbagbe, oro wahala ohun koko bere sii foju han nigba tawon alaga egbe nipinle Eko, Ondo, Ogun ati Osun fesun kan Makinde po ti pawon olori egbe lekun Iwo Oorun orile-ede yii ti. Awon alaga naa, ninu leta kan ti won ko ranse si alaga apapo egbe lorile-ede yii, Omooba Uche Secondus lojo kokandinlogun osu kefa odun yii ni won ti fesun kan Makinde po n da ipade egbe lekun naa pe lai je kawon oloye egbe mo si i.

Leta ohun ni alaga egbe nipinle Eko, Ogbeni Deji Doherty; alaga egbe nipinle Ondo, Onimo-ero Clement Faboyede; alaga egbe nipinle Ogun, Omowe Skirulai Ogundele ati alaga egbe nipinle Osun, Alagba Sunday Akanfe jo fowo si. Won tun fesun kan Gomina Makinde po n dogbon lati je ki Oloye Olabode George ati Seneto Hosea Agboola di alaga apapo egbe ati alaga egbe lekun Iwo Oorun.

Sugbon, oro ba ibomi-in yo lojo monde oseto koja, nigba ti gomina tetele, Ayodele Fayose ko awon agba egbe kan leyin lati lo ri alaga apapo egbe, Omooba Uche Secondus l’Abuja. Lara awon to kowoo rin pelu Fayose ni merin ninu awon alaga egbe lekun Iwo Oorun naa, Deherty; Ogundele; Akanfe ati alaga tigun kan ninu egbe oselu PDP Ekiti sese dibo yan, Ogbeni Bisi Kolawole.

Awon to tun wa nibe ni Igbakeji alaga apapo egbe PDP fun ekun Iwo Oorun orile-ede yii tele, Eddy Olafeso ati akowe egbe, Bunmi Jenyo, to soju oludije egbe naa ninu idibo gomina to waye nipinle Osun lodun 2018, Seneto Ademola Adeleke pelu Oladipo Adebutu.

Enikan to lasiri ohun to waye ninu ipade ohun lowo ni, ohun ti won so nibe ni oro ipade egbe lekun Iwo Oorun to fe waye ati bi won yoo se gba egbe kuro lowo Makinde ni ekun naa.

Sugbon, ninu igbese oselu mi-in to tun waye, awon omo egbe oselu PDP  to n soju ekun Iwo Oorun nile igbimo asofin niluu Abuja gbe ikede kan jade ninu awon iwe iroyin ojoojumo kan, nibi ti won ti lawon wa leyin Makinde gege asiwaju egbe oselu naa, gege bi omo egbe to dipo oselu to ga julo mu lekun idibo ohun.

Ikede ohun, ti won gbe jade ninu awon iwe iroyin ojoojumo bii meloo lawon seneto egbe oselu PDP maraarun atawon omo ile igbimo asoju-sofin mejila ninu merinla to wa lati ekun Iwo Oorun orile-ede yii fowo si. Awon seneto ohun si ni Ayo Akinyelure, Kola Balogun, Biodun Olujinmi, Francis Fadahunsi ati Nicholas Tofowomo.

Bee si lawon omo ile igbimo asoju-sofin bii Oluwole Oke, Kolade Akinjo, Oghene Egoh, Soyinka Olatunji, Tajudeen Obasa, Adedeji Stanley Olajide Bamidele Salam, Ajilesoro Taofeek, Omolafe Adedayo, Ajibola Muraina, Yemi Taiwo ati Abass Agboworin wa nibe pelu.

Awon asofin yii lawon gbe igbese naa “lati le dena awon isele aburu to le fe sele lasiko idibo egbe ohun to n bo lona, ki won si satunse sawon iwa igberaga ati igbese modaru tawon omo egbe kan lawon ipinle kan n gbe lati da ipaya sile lawon idibo egbe nipinle won lasiko yii.”

Igbese won yii lo se deede pelu asiko tawon omo egbe oselu PDP nipinle Ekiti kede atileyin won fun Gomina Makinde, ti won si ni ko ma ate siwaju pelu erongba re lati mu atunto ba egbe naa, ko si doola re lati ma wo. Lojo tusde ose to koja yii lawon omo egbe naa soro ohun leyin ipade awon oloye egbe atawon mi-in to ni nnkan se ninu egbe naa.

Ipade ohun la gbo pawon eeyan peju-pese sii. Ninu won si ni alaga igun kan ninu egbe, Ogbeni Kehinde Odebunmi; Seneto Biodun Olujimi; Duro Faseyi; igbakeji gomina tele, Sikiru lawal; Otunba Yinka Akerele; Diran Odeyemi atawon agbaagba egbe mi-in kaakiri ipinle naa.

Odebunmi to soro loruko awon to ku ni egbe ti pinnu lati fun Makinde ni gbogbo atileyin to ye lati le doola egbe ohun, ko ma baa ku. O l’eka egbe nipinle naa wa leyin Makinde lati maa dipo asiwaju re mu lo ati pawon ti fowo gbogbo igbese re lati ni egbe to duro daadaa, to si nisokan lekun naa.

O toka si fayose gege bi asiwaju awon alatako Makinde. O ni, nitori ti Makinde ko lati satileyin fun un lati maa huwa ko to ninu egbe ni Fayose se dide ogun si i.

Nigba to n kin oro Odebunmi leyin, Olujinmi sapejuwe awon to n tako Makinde gege bi awon olooraye oloselu pelu afikun pe gbogbo igbese Fayose atawon alatileyin re ni yoo ja sofo. O lawon agba egbe lekun naa ni yoo dide ija si enikeni to ba fe kan Makinde l’abuku ninu ilakaka re lati rii pe otito lo leke, yato sawon kan to n gbiyanju lati ba egbe je.

O safikun oro re pe, nise ni Fayose dabi aja to n ku lo, to si n di eyin mo gbogbo ohun to bat i ri nitosi pelu afikun pe nise lo n wona lati ba egbe naa je, ko to lo sinu egbe oselu APC

Olujinmi wa jeje atileyin re fun Seyi Makinde, o ni “asiko yii ni Iwo Orun orile-ede yii nilo gomina yii, nigba tawon kan n gbero lati ja tabuku ilana egbe nipase igbimopo ote.

O ni “abewo Fayose atawon olote egbe re si Uche Secondus ko yato si irin-ajo afe. Emi naa le mu enikeni lo solu ile egbe, ka si ya foto. Ohun to ja julo ni, ki la so nibe. Won le ma so nnkan kan nibe rara lojo naa. Eyin Makinde la wa, a o si nii gba ki enikeni fi abuku kan an.”

Nigba to n fesi nipase oludamoran re lori iroyin, Lere Olayinka, Fayose se kanle p’oun n ba Makinde ja soro asiwaju egbe pelu afikun pe ajosepo to wa laarin awon dan moran gan ni.

O salaye pe, Makinde ni asiwaju egbe n’Iwo Oorun orile-ede yii nitori ipo re gege bi gomina. O ni sugbon ko ye ko si ipo naa lo, nipa ko maa da soro abele egbe lawon ipinle.

“Ko seni to n ba Makinde ja sipo asiwaju egbe. Ayo Fayose ko ba enikeni ja sipo egbe, koda Makinde. Sugbon, p’eeyan je asiwaju egbe ko ni ko je alase fun PDP ni gbogbo ipinle.

“Ooto oro to wa nibe ni pe ko sele ri, ki won maa dari egbe PDP gege bi dukia enikan, ko si le sele bayii. Lasiko ti Fayose je gomina kan soso, ko da soro taa ni yoo je alaga PDP ni Osun, Oyo, Eko, Ondo ati Ogun. Gbogbo awon eeyan wonyi lo yan taa ni yoo dari won funra won. Sugbon, ko ri bee lasiko yii.”

“Ere idaraya ni oselu. Se tie ki n se temi ni. Ti mo ba n se temi, ma da sii. Lo se tie naa ni. Ere idaraya ni. Nigba to o ba n se tie, mi o nii soro. Awon oloselu to gbon, kii jokoo sinu yara won, ki won maa saroye lori ohun ti alatako won n se. Awon naa maa n lo se tiwon ni. Nitori naa, nise ni Ayo Fayose n se ere oselu tie naa.

Kawon to ku naa lo se tiwon. Ti Fayose ba kawon eeyan lo ba Secondus, kawon naa ko eeyan lo ba a.”

No comments:

Post a Comment