Monday 7 September 2020

Wahala n’Ilara-Mokin, won l’oba lo fi Bibeli gbadura nidii oosa ilu.


Wahala n’Ilara-Mokin, won l’oba lo fi Bibeli gbadura nidii oosa ilu.

-lawon ilu ban i ki won yo o loye

(O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii)

Yanju Adegboyega

Tijoba ipinle Ondo atawon toro kan ba ko tete gbe igbese to ye lori oro ohun, o see se ki wahala nla kan sele niluu Ilara-Mokin nijoba ibile Ifedore, ipinle Ondo, nitori tawon omo ilu naa kan n binu si oba alaye ilu ohun, Oba Abiodun Aderemi Adefehinti lori iwa kan ti won lo hu, eyi ti won lo tako isese. Gege ba a se gbo, won l’oba alaye ohun lo sidii awon osa ilu naa lasiko odun ijesu pelu Bibeli lati lo gbadura loruko Jesu, eyi ti won lo tako isedale ilu naa.

Akoroyin wa gbo pe, ojo Sannde ogbonjo osu to koja yii ni odun ijesu, eyi to maa n waye lodoodun lasiko ti isu tuntun ba ti jade. Awon oba ilu naa si maa n lo se adura pataki nidii awon oosa ilu ohun lati dupe lowo Olodumare fun oju to tun ri odun tuntun, bee si ni won yoo sadura ki odun mi-in tun soju won. Sugbon, won ni Oba Abiodun maa n lo sidii oosa pelu Bibeli, ti Olori re naa yoo si tun mu aago ti won n lo ni soosi lowo lati lo sadura loruko Jesu nidii oosa ilu.

Opo awon omo ilu naa tinu n bi siwa ti won l’oba won n hu yii lo ni ko sidagbasoke kankan niluu Ilara-Mokin lati bi odun meedogun ti Oba Abiodun ti gori ite. Won salaye pe, gbogbo awon idagbasoke to wa nilouu naa lat’igba ti oba alaye ti joba ko ju eyi ti alase ati oludari ile-ise onimoto Elizade, Agba Oye Adeojo se.

Gege ba a se gbo, awon eeyan ti ko le koju oba alaye yii lo ti n kun sinu, nigba ti won tun rii lasiko odun ijesu odun yii, to tun gbe Bibeli lowo, tiyawo re naa si tun mu aago soosi lo sidii awon oosa ilu lati sadura.

Nigba to n bawon akoroyin soro, omo bibi ilu ohun kan to tun je osere ori-itage, Alaaja Anike Alajogun salaye pe okan ninu odun tawon omo bibi ilu Ilara-Mokin feran pupo ni odun Ijesu. O ni asiko odun naa lawon omo ilu yii maa n wa sile lati eyin odi, sugbon bi Oba Abiodun se gori ite ni gbogbo nnkan bere sii baje, to si n tun itan ko.

O ni “emi gan koro oju si bi Oba Alara ti Ilara-Mokin se da asa ati ise po mo esin. Lati lo maa fi Bibeli ati oruko Jesu gbadura lasiko odun ilu. Lati ibere akoso re lo ti ya oba olori kunkun, ti kii gbo ohun tawon eeyan re ba so. Nise lo fe ki asa parun, sugbon tawon alale ko gba fun un. Ni gbogbo odun Ijesu, nise ni yoo lo sibi kan taa n pe ni “Oko Idasu” nibi tawon oba to ti je saaju re maa n lo lati lo gbadura, ki won si setutu, sugbon eyi toun yoo fi se bi awon asaaju re, nise ni yoo gbe Bibeli lo ni tie, tiyawo re naa yoo si mu aago ati ohun-elo orin Tambourine lowo lo maa gbadura loruko Jesu nibe. Eyi ti ko tona rara. O to akoko ki gbogbo iranu yii dopin.

“Lat’igba ti oba yii ti bere sii da nnkan po ni ko ti sirepo n’Ilara-Mokin, ti gbogbo nnkan si n dojuru. Ko silosiwaju tabi idagbasoke kankan niluu, leyin iwonba eyi ti oludari Elizade n funra re se niluu. Awon agbaagba atawon ijoye ilu naa o ri nnkan se sii, nitori monafiki ni won. Ti Oba Abiodun ko ba le tele isese. Ko fipo sile fawon to setan lati tele asa ati ise. Kii se dandan ni ko ku sori ite. Ko seni to fipa mu un lati joba. Ojo Sannde ose to koja yii lodun Ijesu. Odoodun la maa n se e nigba ti isu tuntun ba jade.

Nibi ti oro de duro bayii, awon omo ilu Ilara-Mokin n binu pupo si Alara ilu Ilara-Mokin gan ni, nitori ti won lo n te asa ati ise ilu loju mole pelu bo se n gbe Bibeli lo sidii awon oosa ilu. To si tun n lo gbadura nibe loruko Jesu.

 

No comments:

Post a Comment