Wednesday 30 September 2020

O tan! Owo tun te elomi-in, to n foro AMOTEKUN lu jibiti niluu Oyoo

 

O tan! Owo tun te elomi-in, to n foro AMOTEKUN lu jibiti niluu Oyoo

Yanju Adegboyega

(O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii)

Lai tii ju ose meji lo ti won mu okunrin kan, Isiaka Kareem niluu Ibadan po n gbiyanju lati lu awon eeyan to fe gba ise ninu iko alaabo ile Yoruba nni, Amotekun, owo ijoba ipinle Oyo tun ti te elomi-in lose to koja yii niluu Oyo.

Okunrin ohun, Adeyemi Agboola, eni to nile-ise ikanni ayelujara, Cybercafe loju ona to lo si papa isere Durbar niluu naa ni won lo n ta foomu igbani sise Amotekun to je ayederu fawon eeyan to mo pe won o kawe ni eedegbeta naira, N500 eyo kan pelu ileri poun yoo ran won lowo lati ri ise ohun gba.

Gege ba a se gbo, lojo Wesde ose to koja lowo te Agboola, eni to salaye pe nise loun n lo anfaani lati lu awon eeyan ni jibiti. Ko to di pe okan ninu awon to ti ko sii lowo so lasiko ayewo p’oun o mo iyato ninu ayederu ati ojulowo foomu. Eni naa, to ni ka ma daruko oun lo mu foomu ayederu ti Agboola ta fun un lo sibudo ayewo igbani sise n’Ibadan, nibi ti asiri ti pada tu.

Nigba to n soro lori isele ohun, oga agba fun iko Amotekun, Ajagunfeyinti Olayanju Olayinka ni odaran naa yoo foju wina ofin fun iwa to hu ohun, nitori ti won ti fa a le awon ti yoo sise lori re lowo. O wa ro awon ara-ilu lati maa fi oju s’ori bi alakan fawon eeyan to le fe lo anfaani awon isele to n se layika won lati lu won ni jibiti bi iru eyi ti Agboola n se nitori to rii pawon eeyan kan ko ni eko iwe to to tabi rara.

O ni “o je ohun to bani lokan je pawon eeyan kan tun le lo anfaani lati lu elomi-in jibiti nipase igbani sise, nitori to mo pe won o mo on ko, mo on ka. A o sise iwadii gidi lati mo iye awon eeyan to ti ko si pampe okunrin naa.

“A ti fa a lawon ile-ise alaabo to ye lati foju re wina ofin. Yoo si je eko fawon mi-in to le fe gb’ese le ona ti ko to, to n to naa. Ijoba ipinle yii ti n fi gbogbo igba sise lati yo awon eeyan wa kuro ninu ise ati osi to n ba won finra. Sugbon, a o nii gba kawon kan to lero pawon gbon yan awon eeyan wa je.”

Olayinka wa gbawon eeyan to n gbero lati sise ninu iko Amotekun lati ma wa ona alumokoroyi kankan pelu afikun pe ki won sora fawon onile-ise ikanni ayelujara ti won n lo ba fun iforuko sile.

Ilu Ogbomoso lawon iko to n sayewo fawon eeyan to fe sise ninu iko Amotekun wa lojo Tosde, ojo kerinlelogun ni papa isere ilu Ogbomoso nibi ti won ti sayewo fawon eeyan to wa lati ariwa ati guusu Ogbomoso lojo Jimoh ojo karundinlogbon osu yii. Awon eeyan to wa lati Suuru lere lo si sayewo ti won lojo Satide, ojo merindinlogbon osu yii ni papa isere ilu Ogbomoso kan naa.

 

N’Ibadan, EFCC foju oludasile ile-eko ba ile-ejo lori jibiti iwe ase irinna ile okeere

 

 

N’Ibadan, EFCC foju oludasile ile-eko ba ile-ejo lori jibiti iwe ase irinna ile okeere

Yanju Adegboyega

(O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii)

Ajo to n gbogun ti iwa ibaje nidii owo ati oro-aje lorile-ede yii, EFCC, eka tiluu Ibadan ti gbe obinrin kan, Motunrayo Olasebikan ati okunrin kan, Abideen Adefisayo Tijani lo siwaju ile-ejo giga ilu Ibadan kan lori esun pe won lowo ninu sise ayederu iwe ase irinna ile okeere.

Olasebikan, eni to ni oludasile ile-eko loun ni won woo un ati Tijani lo siwaju Onidajo Ladiran Akintola lori esun meje otooto. Lara esun ohun si nigbimopo huwa odaran ati iwe yiyi.

 

Okan ninu awon esun ohun lo bayii “Iwo Olasebikan Motunrayo ati Tijani Abideen Adefisayo ni bi osu kesan-an odun 2018 niluu Ibadan labe idari ile-ejo yii se iwe kan takole re je “Ase irinna” ti nomba re je J511464256 loruko enikan to n je Pamilerin Adedayo pelu alaye pe ile-ise asoju orile-ede Canada lo ko o lojo kefa osu keje odun 2016 titi di ojo kefa osu kefa odun 2021. Eyi te e se pelu ero pe won yoo sise lori re pe ojulowo ni, te e si mo pe iro le pa. Nipa bee, e ti se si ofin.

Gege ba a se gbo, iwe ehonu kan ti enikan to n je Inumudunsola Popoola ko si ajo EFCC loruko awon egbe re ti won jo lu ni jibiti lo je ki ajo naa wo awon odaran mejeeji lo siwaju ile-ejo. Ninu iwe ehonu ohun, Popoola fesun kana won mejeeji yii pe ninu osu keji odun 2018, awon odaran mejeeji naa tan ohun atawon meta mi-in lati gba owo to to milionu die lowo won pelu ileri lati bawon seto iwe irinna.

O salaye pawon mejeeji naa fi ara won han gege bi awon to maa n bawon eeyan se iwe irinna tijoba fun niwee ase. O ni looto ni won fawon lawon iwe irinna, sugbon tawon pada mo pe ayederu ni won ko fun won, lasiko tawon n gbero lati fir in irin-ajo si ile okeere.

Awon odaran mejeeji so fun ile-ejo pawon o jebi awon esun ti won fi kan won. Eyi lo si mu ki agbejoro olupejo, Omowe Ben Ubi ro ile-ejo lati fun lojo tigbejo naa yoo bere. O war o ile-ejo lati je ki won lo fawon mejeeji pamo sahamo titi dojo tigbejo yoo waye.

Awon agbejoro olujejo, A B C Ademiluyi ati S O Alli ro ile-ejo lati ma jee ki ojo igbejo naa pe pupo, ki won le gba iduro awon onibaara won. Onidajo Akintola wa sun igbejo mi-in siwaju di ojo keje osu kewaa lati gba iduro won. Sugbon, o pase kin won lo ko won pamo sahamo ajo EFCC na.

N’Ibadan, Ile-ejo fawon eeyan merin sewon lori iwa jibiti

 

N’Ibadan, Ile-ejo fawon eeyan merin sewon lori iwa jibiti

Yanju Adegboyega

(O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii)

Ile-ejo giga ijoba ipinle Oyo kan to n jokoo niluu Ibadan ti fawon eeyan merin kan sewon lori esun pe won n fogbon jibiti gbowo lowo awon eeyan. Awon eeyan ohun ni Kushimoh Azeez Adeleke, Afolabi Olubukola, Kolawole Idowu ati Olakunle Ishola. Ajo to n gbogun ti sise jibiti owo ilu lorile-ede yii, EFCC eka tiluu Ibadan lo gbe awon eeyan ohun lo siwaju ile-ejo lori esun kan soso.

Esun ohun ka bayii “iwo Kushimoh Azeez Adeleke, Afolabi Olubukola, Kolawole Idowu, Olakunle Ishola ati Isaiah Oluwabunmi, eni to ti salo lasiko yii, ni nnkan bi osu kin-in-ni odun 2019 niluu Ibadan lagbegbe ile-ejo yii huwa jibiti nigba te e gba owo to to egberun lona eedegbeta naira ati mejilelaadota owo naira, N552, 000 lowo enikan to n je Folake Modupe Temowo nigba te e paro fun un pe e fe fowo ohun toju aburo oko re kan, Seyi Tomowo to nijamba moto to po gan ni. Bee le si mo pe iro le pa fun un. Iwa yin ohun lo si tako ofin orile-ede yii.

Awon mereerin gba pawon jebi esun ohun. Leyin naa ni agbejoro olupejo, Festus Ojo ro ile-ejo lati fi won sewon bo se ye lori ese ti won se ohun. Onidajo Ladiran Akintola ninu idajo re pase ki enikookan won lo sewon odun meji meji.

O ma se o! AYUBA, olokada pokunso n’Ibadan

 

O ma se o! AYUBA, olokada pokunso n’Ibadan

-          Gbogbo eeyan niku re n se ni kayeefi

Yanju Adegboyega

(O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii)

Nise loro isele iku omo odun mejilelogun kan, Ayuba Sarafa si n se gbogbo eeyan to wa laduugbo Amuloko niluu Ibadan ni kayeefi titi dasiko yii. Gege ba a se gbo, nise ni won sadeede ba oku Ayuba, eni to je omo kan soso ti baba re bi nibi to pokunso si ninu ile akoku kan nitosi ile aburo baba re kan lojo Jimoh ose to koja.

Akoroyin wa gbo pe, Ayuba, eni to n sise okada gungun lo dagbere ibiise lojo Tosde, sugbon ti enikeni ko gburoo re titi dojo Jimoh ti won pada ri oku re ohun. Nigba to n soro, aburo baba re to n gbe pelu ni leyin to ti dagbere eni ise f’oun lojo Tosde, oun o gburoo re titi t’oun fi lo sun lale ojo naa rara.

Gege bo se so, nigba to daaro ojo Jimoh ti ko seni to le so ni pato ibi to wa, ni won ba gbiyanju lati pe foonu re. O ni nigba ti won rii pe foonu re n dun ati pe nitosi lo ti n dun. Obinrin kan lo feti sile, to si n lo sona ibi ti foonu ti n dun ohun. Ko to di po kan oku re nibi to ti n mi dirodiro, inu apo aso re si ni foonu re ti n dun.

A gbo pe, won ba ora dudu meji nile nibi to pokunso si pelu bata re ti fon kale. Ninu awon nailoonu ohun si ni won ti ba aso jalamia funfun kan, ohun-ikunra oloorun meji, aso awotele, singileeti funfun kan to je tuntun, sin-sin, bisikiiti atawon nnkan re mi-in. Bee lo si fi ankasiifu funfun kan se aso iboju-bomu.

Nise ni iya re, eni ti won poruko re ni Nike n wa ekun mu. Gege ba a se gbo, iya re yii lo wa lati ilu Owu nipinle Ogun, nibi ti won lo ti lo leyin ti baba ti Ayuba ti ku. Bee lo n pariwo pawon aye lo lowo soro omokunrin re kan soso naa.

Nigba takoroyin beere, ohun to ro po le fa ki Ayuba pokunso, aburo baba re to n gbe pelu, Kazeem Tijani, eni to lomo bibi ilu Apomu nijoba ibile Isokan, ipinle Osun lawon ni ise awon to n ta ike aloku loun n se ni “nise ni Ayuba gba okada to n gun ni san diedie, bee lo si n se deedee ninu sisan owo pada f’eni to gba a lowo re. Omo egbon mi ni. Ko j’enikeni ni gbese, bee si ni ebi ko pa a rara. Ko tii niyawo. O ti t’odun meji tabi meta to ti n gbe lodo mi. Emi gan lo n ba sise tele ko to gba okada to n gun. Ise aranso, telo gan lo ko, o si n se daadaa. A ti wo gbogbo yara re, a o si ri boya o ko iwe kan sile, bo tie je pa o ri ara re yewo. Mo ti foonu sawon molebi wa l’Apomu, koda won ti wa loju ona bayii.

Ninu oro tie, alaga egbe olokada l’Amuloko, Ogbeni Oluwatosin James sapejuwe Ayuba gege bi eeyan jeje, ti kii ba enikeni ja. Gege bo se so “iku Ayuba ba gbogbo wa lojiji. Aaro yii naa la gbo iroyin iku re ni gareeji. Eeyan jeje, ti kii ba enikeni ja ni. To ba ti sise okada re tan laaro, nise ni yoo lo paaki, ti yoo si gba soobu aburo baba re lo lati lo ran an lowo. Ninu egberun lona irinwo din mewaa, N390, 000 to gba okada to n gun, o ti sanwo re ku egberun metadinlogorin, N77, 000. Kii se p’eni to gbe okada fun un n hale mo on. Koda, bi omo iya re ni eni naa je. Nitori naa, iku n se wa ni kayeefi gan ni.

Lasiko takoroyin wa debi isele ohun, oku Ayuba si wa nibi to ti n mi dirodiro. Sugbon, awon elesin ibile ti wa nibe, ti won seto awon etutu. Ki oro iku ohun ma ba a di akufa laduugbo naa. Bee si ni olopaa kan lati tesan Akanran naa wa nibe lati se awon akosile kan, ko to di pe won yoo sin in. gbogbo awon lanloodu adugbo naa ni won lawon o tie mo nnkan ti won le so lori iku Ayuba

 

Ope o! Owo OPC te awon afemi sofo ati ajinigbe to wa l’Oke Ogun

 

Ope o! Owo OPC te awon afemi sofo ati ajinigbe to wa l’Oke Ogun

-          Opo ibon atawon ohun-ija oloro ni won ba lowo won

Yanju Adegboyega

(O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii)

Lose to koja lo yii lowo egbe ajijagbara ile Yoruba nni, Oodua Peoples Congress, OPC te awon afemi sofo atawon ajinigbe to fara pamo sinu igbo oba lagbegbe Oke Ogun, ipinle Oyo. Gege bi alaga egbe ohun nipinle Oyo, Komureedi Rotimi Olumo se so fawon akoroyin, olori egbe OPC to tun je Aare Onakakanfo ile Yoruba, Oloye Gani Adams lo pase ki oun atawon omo egbe naa lo maa gbe l’Oke Ogun titi won yoo fi le awon eeyan naa kuro nibe.

Olumo salaye p’owo awon omo egbe OPC te mewaa ninu awon afemi sofo ati ajinigbe naa, ti won si ti fa won le ile-ise olopaa lowo. O wa dupe lowo awon oba alaye agbegbe naa fun awon iroyin ati iranlowo ti won se fun OPC ati olopaa. O ni egbe OPC ti se ise takun-takun lati rii pe alaafia joba nipinle Oyo.

Gege bo se so “emi gege bi olori OPC nipinle Oyo, o ye ki n koko dupe lowo olori wa, Aare Onakakanfo Gani Adams fun bo se fun wa niroyin nipa iwa awon afemi sofo ati ajinigbe to wa lagbegbe Oke Ogun. O ti se pupo fun ile Yoruba.

O tun dupe lowo awon omo egbe OPC niluu Igbeti ati Igboho fun iranwo atawon ifowo sowopo won lati je ki ise won yori sir ere. Olumo salaye pe, awon omo egbe OPC lo mu awon afemisofo ati ajinigbe naa ninu igbo ti won fara pamo si pelu afikun pe gege bi olori egbe OPC nipinle Oyo, oun ko nii faaye gba afemi sofo ati ajinigbe kan kan.

Olumo wa ke sijoba ipinle Oyo lati satileyin to ye fun egbe OPC, ki alaafia ati eto aabo to peye le wa fun emi ati dukia awon eeyan. Bee lo ni ki won rii daju pawon afemi sofo ati ajinigbe towo te naa foju ba ile-ejo.