Thursday 25 February 2016

Awon toogi ja n'Ibadan, leeyan mefa ba ku

N'Ibadan, awon omo-isota ja, won paayan repete.
Nise l'oro di "boo lo, o yago" fun mi lona lojo tusidee ose to koja yii laduugbo Oja'Ba niluu Ibadan nigba tawon omo isoa kan kolu ara won, ninu eyi taa gbo pe ko din leeyan mefa to ba isele ohun rin. Tawon olugbe adugbo naa ko si le lo tabi bo nidii ise oojo won.
Awon egbe omo isota ohun ti won pe ni Idowu ati Zaccheus la gbo po n ba igun omo isota mi-in ti enikeni ko moruko re ja, sugbon ta o le so pato ohun to fa wahala laarin won naa. Bi awon kan se n so pe, ija "emi ju o, iwo o ju mi" ni, bee lawon kan so pe oro owo kan lo dija laarin won.
Yato si eyi, awon kan ni igun omo-isota Ekugbemi ati Oluomo lo n bara won fa wahala. Eyi to wu ko, ooto ibe ni pawon olugbe adugbo naa ko le sun oorun asundiju fun bi ojo meta ninu ose to koja naa. Nitori taa gbo pe, ojo sannde ose to lo lohun-un ni won ti bere ijangbon naa.
Akoroyin wa gbo pe, wahala sele nirole ojo tusidee, nigba tawon igun Idowu gbiyanju lati gbesan ija kan to ti waye saaju nibi ti okan ninu awon omo eyin re ti ku. Eni to ba wa soro ni, eyi lo mu ki won lo dena de awon omo igun keji ti won o daruko naa pelu iranlowo awon igun omo-isota Zaccheus laduugbo Gege Adero, Ibadan.
Elomi-in to tun ba wa soro salaye pe, ohun to fa wahala ohun gan ni bi Idowu se lo da ariya kan tawon kan n se laduugbo Mapo ru, eyi ti won pe ni "Obo Day". Eni naa ni, nise ni Idowu yii maa n fonnu kiri pe omo egbe ajijagbara ile Yoruba, OPC loun. Bee, won ti lee ninu egbe naa nigba to se asemase kan. Eni yii so fun akoroyin wa pe, nise lawon to n se ariya to lo daru naa luu ni alubami, eyi to si mu ko pada lo ko awon omoleyin re wa lati wa gbeja re.
Enikan tisele naa soju re ni awon ohun-ija oloro bii akufo igo ni won koko n lo fi ja, sugbon nigba ti yoo fi di ojo wesidee, won ti bere sii lo awon ohun-ija oloro bi ibon ati ada. Gbogbo awon oloja to wa laduugbo naa lo n sare pale oja won mo, nigba tawon omo isota yii n le ara won wonu agboole to wa nibe.
Nigba tawon olopaa si de sibe ni wahala ohun tun ro'le die. Tit dasiko taa n ko iroyin yi jo lawon olopaa si wa kaakiri agbegbe ohun pelu oko ijagun lati le rii pe alaafia joba. 
Akoroyin wa gbo pe, awon ohun-ija oloro tawon omo-isota yii n ko kiri lai beru lo mu ki opo awon ontaja adugbo naa ti soobu won pa fun opolopo wakati. Bi awon kan n so pe eeyan meta lo ku, lawon kan n so pe mefa leni to ku. Sugbon, olopaa ni enikan soso lo ku nibe.
Eni to ba wa soro ni "a o mo nnkan to sele gan. A gbo pe, irole tusidee ni won ti bere, ti won n fi akufo igo bara won ja. Sugbon, laaro yii ni won sadeedee bere sii lo awon ohun-ija bii ibon.
"Nise la ha saarin won nibi, koda a o le ta nnkan kan lataaro taa ti de. Nigba ta o le si soobu. O ga gan-an ni o," 
Sugbon, enikan so pe "eeyan mefa lo ti ku lenu igba ti won bere wahala won. Lale ojo tusidee ni won sa omokunrin kan to n bo lati enu ise re ni Gate. Ojo wesidee ni omokunrin yen ku nileewosan UCH. Oun si lo n toju iya re to ti darugbo. Bee si ni won pa omo ileewe kan, to wo aso sukuu sorun."
"Awon mefa lo ti ku, nitori mo gbo tawon kan ninu won n so pe, o di merin si meji bayii. Sugbon, a o mo igun omo-isota ti won n ba ja titi dasiko yi."
Nigba to n soro lori isele naa, alukoro ileese olopaa ipinle Oyo, Ogbeni Adekunle Ajisebutu fidii isele naa mule. Sugbon, o ni enikan soso lo ku nibe.
Ajisebutu ni, "Enikan soso lo ku. Komisanna si ti pase pe ki awon olopaa maa wa laduugbo naa ni tosan-toru lati le daabo bo emi ati dukia awon eeyan nibe. Owo ti te awon eeyan kan pelu. 
Lasiko taa n ko iroyin yi jo, alaafia pada sibe, bee si nileese olopaa ti so poun o nii foju rere wo enikeni to ba n da omi alaafia ilu ru".

No comments:

Post a Comment