Tuesday 16 February 2016

Agogo Ogbon

Agogo Ogbon!!!
Oko-eru eleekeji
Mo ro oro ohun, omi le roro loju mi.
Nigba ti maa fi lanu lati soro, poroporo l'omi n da sile loju mi. Gbogbo takada ti mo si n ko apileko yii si lo tutu jigbinni.

Bi ipolongo ominira l'oro ohun bere.

Agbekale iro ohun daa pupo, to bee ta o sakiyesi.

Lati le di ilumo-on ka, won so fun wa pe oro ibi ko ju'bi laarin okunrin ati obinrin ni.

Nigba naa, won waasu fun wa pe, oro eto omoniyan ati eto awon omode lawon n gbe kiri.

Lati fa oju awon obinrin mora, won sapamo sabe irolagbara awon obinrin.

Awa kan n ri gbogbo re, gege bi ara ilaju.

Nitori eyi, a kan saara si won. A si fi iwa omugo korin rere ki won.

Won ti di wa loju to bee, ta o sakiyesi igba ti won gbe oro ibi ko ju'bi sile. Ti won si f'oro ojuse eni gbigba se ati siso "ohun to to" di "eyi ti ko to".

Won so fun wa pe, oro agboye laarin ara wa ni. Abi, ki lo buru ninu tiyawo re ba rise ju oko lo. Ko gba ipo olori ile, ki oko si maa gb'ase lowo re?

Won so fun wa pe, a l'ase lori eya-ara wa. A le see bo se wu wa.

Won so fun wa pe, ti okunrin ba le "lajosepo pelu obinrin to wuu, nigba to ba wuu". Bee lo ye ko ri fun obinrin naa.

Won seto "ife ofe ati ore pelu ere". Won si je ko ye wa pe, nise la n lo eto wa labe ofin lati gbadun eya-ara wa.

A si gba bee. Odo langba wo ni ko nii gba?

Nigba taa soro nipa awon "ARUN IBALOPO", won fi ora idaabo bo, kondoomu lo wa. Koda, won bere sii pin in fun wa lofee lawon ileewe girama wa.

Won so fun wa pe, lati omo odun merindinlogun lati ni eto lati se ohun to wu wa.

Eyi si je ka maa ri awon obi ati oluko wa bi aja inu iwe, ti ko le gbo debi ti yoo bu eeyan je. Nigba ti won o letoo lati ba wa wi mo.

A n soro nipa ominira to dun!

Nigba taa soro nipa oyun airotele laarin awon odomobinrin, won so fawon obi wa lati maa ko wa nipa ilana ifeto somo bibi lati kekere.

Won sagbekale ilana eko ibalopo tuntun lawon ileewe wa, gege bi ona lati tun fogbon pin kondoomu fun wa sii.

Opo ninu wa lo tun pada gbe oyun esin, bee la si n soro.

Nipa bee, won pinnu lati fi ofin gbe oyun sise lese. Gege bi ohun to tona.

Ona ati ran wa lowo naa ni o.

E o rii pe, ojo-ola wa je won logun gan ni. Bee si ni won fe rii daju pe a gbe ile aye wa ni kikun.

Oyun sise si jo nnkan gidi loju wa.

A gba lati maa se bee.

Abi, ki nidii taa fi maa bimo ta o fe tabi ta o nii le toju saye?

Okan wa da wa lebi lori iwa yii, nitori to jo ipaniyan.

Sugbon, won ni ka ma seyonu.

Gege bi alaye won, ohun taa n se ni pe ka gbe "ole-inu" ta o fe jade lasan, kii se pe a n pa omo.
Bee la tun gba si won lenu, a si moju kuro nibe.

Won tun ni ko ye ka maa beru orisa, esin, awon obi wa tabi awujo.

Leyin naa, won so fun wa pe, a ni ominira lati fi aye wa se ohun to wu wa. Niwon igba, ta o ba ti pa enikeni lara tabi te eto elomi-in loju.

Loju ese nibe, a o nibowo fun OLORUN mo.

O ya wa lara lati maa gba boolu, se faaji tabi ka maa wo awon fiimu ologbonrangandan lojo Jimoh ati Sannde.

A tun pinnu lati gbidanwo ibalopo ako s'ako ati abo s'abo. O si jo igbadun, bee ni won tun n se koriya fun wa.

Nigba taa so fun won pe, awujo tiwa koro oju siru iwa bee. Won fi ofin gbee lese, won si ni koda a le fe ara wa sile gan bii l'oko-l'aya.

A tun pinnu lati te siwaju nipa igbidanwo oogun oloro.
Won takoo loju gbogbo aye, sibe a n rii ra bo se wu wa.

Ju gbogbo re lo, omo kekere si ni wa. Ko si ohun ti awon agbofinro le se fun wa, won o le fiya je wa nitori ojo-ori wa.

A n wa eni awokose, bee ni won fun wa lawon gbajumo osere won to ti ko aimoye oko tabi iyawo. Gbajumo olorin ti oogun oloro ati ogogoro ti di baraku fun atawon gbajumo elere idaraya ti won se isekuse kiri pelu iyawo oniyawo tabi oko oloko.

Won so fun wa pe, awon ilumo-onka yii laluyo, bee si ni won l'ominira. Nitori naa, ka maa gbero lati da bii won.

Opolopo wa bere sii fon ara (pumping iron), fin ara wa (getting tattos). Bee si la n gun abere oogun oloro (injecting steroids), ka le jo agbalagba, ka si "laluyo" bi awon eni awokose wa.

A bere sii ri awon ti ko sagbere gege bi awon ope.

Lati le jo awon eni "awokose" wa, awa naa bere sii sare le gbogbo ohun to ba ti wa ninu iro.

Bee la n ya foto awon eni "awokose" wa taa gba po ti laluyo, to si tun joju ni gbese ninu awon iwe iroyin. Taa n lee mo inu ile wa.

A bere sii lo oogun to n din ora ku ninu ara, ka le ri bii won.

A sakiyesi pe, tipatipa ni won fi n wo aso sorun, a si bere sii ko ise won.

Nigba ti oju fe maa kun wa, won mu wa mo awon ile ijo won ati pati ale.

Won ni ka gbe omoluabi ti, ka sa ti jaye ori wa.

Koda, nigba ti won fipa bawon kan lara wa lopo, won ni ka panumo. Ka maa ba faaji wa lo.

Opo ninu wa ni oti amupara ti di baraku fun, sugbon won so fun wa pe ara ona lati so pe omo nla ni wa ni. Nitori naa, la ba mura sii.

Lasiko kan, a sakiyesi pe a ti di eru won lai mo.

A sakiyesi pe, a o nidii kankan lati wa laye month. Bee si ni aye gan ko nitumo kankan mo.

Nitori ati maa joju ni gbese, opo ninu wa lo ti ko arun buruku "anorexia nervosa".

Opo ninu wa to bara won ninu ajosepo oko atiyawo lo soro fun lati je olooto.

Opo lo si n bere sii ronu ati gba emi ara won.

Opo mi-in ni arun ibalopo.

Opo ninu wa lo nisoro to nii se pelu opolo.

Aimoye ni ko le tesiwaju ninu eko won mo nipase oyun airotele, oogun oloro ati oyun sise to yiwo.

Nikorita yii lati rii pe, ojo iwaju wa ti baje nisoju wa.

A bere sii wa taa lo ye ka di ebi oro ohun ru.

Leyin opolopo iwadii ti ko so eso rere kan, a gba pe a o tie kuku mo "taa ni won" gan.

Igba naa ni oju wa wale. A si ranti oro ti awon baba wa maa n so fun wa pe:
“Ominira to na ti po ju, oko-eru ni to farasin ni”.

A tun ranti igba tawon iya wa maa n so fun wa pe:
“Ominira ti ko ba ti si eni to n ye'ni lowo re wo. Ko yato si keeyan o wa ninu igbekun igbalode”.

Lasiko ohun, oro ohun ti bowo sori fun wa.

A ti ra iro ominira "won".

Boya, ko tii pe ju fun eyin.

A je pe, kee ma je ki iro ati itanje won o je yin o..

E ma je ki oro tutu ominira won o tan yin je.

Iro lasan ni gbogbo re!

A le fidii eyi mule nipa ipo ajosepo wa, oogun oloro lilo, oyun airotele, iwa jagidi jagan ati bee bee lo.

E sora. E dakun, kee si kilo fawon odo to ku, ki isele yii ma mu gbogbo iran yii l'eru.

Nitori to ba je looto la NIFEE OLORUN, gege baa se n so. O ye ka yago fun gbogbo ohun to KORIRA.......

No comments:

Post a Comment