Saturday 11 June 2016

Kayeefi n'Ibadan, Won ri aworan obinrin to pon'mo lara ogiri ---Lawon kan ba n lo boo, won ni Yemoja ni.

Kayeefi n'Ibadan, Won ri aworan obinrin to pon'mo lara ogiri
---Lawon kan ba n lo boo, won ni Yemoja ni.
Yanju Adegboyega
NIse lawon eeyan n ro giirigi lo saduugbo Olomi niluu Ibadan lojo Jimoh ose to koja yii, nigba tiroyin kan gba igboro kan pe, won ri aworan obinrin kan to pon'mo seyin ninu ile kan nibe. Gege baa se gbo, ese ko gbero laddugbo ohun titi di ale ojo naa, nigba ti gbogbo eeyan to gbo n lakaka lati fun oju won lounje ati lati ri eemo naa funra won.
Ibi isele ohun, to wa ni ojule kejidinlogoji, Olorunkemi Zone 1, Olomi-Academy lawon eeyan si ti so di mecca lasiko taa n ko iroyin yi jo lowo. Gege baa se gbo, owo irole ojo tosidee ni omobinrin to ni yara kan ninu ile olojule mejo ati boisi kota merin naa, nibi toun gan ti n lo yara to kangun ninu boisi kota ohun ti sakiyesi aworan naa, sugbon to koko n paa mora. A gbo pe, nigba ti oro ohun ko yee mo lo pariwo sita pe kawon eeyan wa wo kayeefi to ri naa. Ti gbogbo eeyan si wa ba wo ohun to ri ohun.
Lasiko ti akoroyin wa debi isele ohun laaro ojo satide, omobinrin to ni yara naa to ko lati daruko re, ti ko si tun gba akoroyin wa laaye lati ya foto aworan naa lo salaye pe, asiko ti oun maa pe ero le aworan ohun lori ko tii ya. O soo di mimo pe, ohun si n gbero lati se awon etutu kan ati pe leyin naa loun yoo se ajodun nla kan fun aworan naa.
Awon eeyan meji kan ti akoroyin wa ba nibe lasiko abewo re ni awon okunrin meji kan ti okan mu tesubaa awon musulumi lowo, sugbon tawon mejeeji n fi ede fo bi awon omo ijo kerubu tabi Cele. Ninu oro ti won n so fun  omobinrin to ni yara ohun ti akoroyin wa gbo ni won ti so pe, iru aworan naa wa lodo molebire kan ri ati pe o se die ti won ti pase pe ki oun pelu jokoo ti oosa naa.
Sugbon, akiyesi akoroyin wa ni pe, omi ojo to n jo lati ara ogiri ile naa lo lapa lara ogiri yara ohun. Eyi to je ko dabi igba ti won ya nnkan sara ogiri naa.
Ju gbogbo re lo, akoroyin wa rii pawon eeyan kan ti n da awon nnkan ti enu n je bi iyo, osan ati omi pio wota jo sidii aworan ohun lati gbadura. Bo ba si se je, isele to ba tele eyi ni yoo so. Sugbon, titi dasiko ti akoroyin wa kuro nibe lawon eeyan si n wo lo sinu ile ohun ti gbogbo eeyan n pe ni ile Iya Indomie lati lo wo ohun iyanu ti awon kan pe ni Yemoja naa.
Foto : Eyi ni enu ona abawole sinu yara ti won ti ri aworan naa.

No comments:

Post a Comment