Tuesday 16 February 2016

Won sinku OLUBADAN ODUGADE, gbogbo eeyan n so pe eni rere lo. Sugbon, awon ka ni eewo ni. Won kii te oku oba sita gba-n-gba.

Won sinku Olubadan ODUGADE, gbogbo eeyan lo n so peni rere lo.
- Sugbon, awon kan ni eewo ni. Won kii te oku oba sita gba-n-gba nile Yoruba.
Yanju Adegboyega
Ojo Jimoh ose to koja, ojo kejila osu yii ni won fi ara Olubadan ile Ibadan, Oba Samuel Osundiran Odulana Odugade kin-in-ni fun ile leyin isin idagbere to waye fun un ninu ijo Peteru mimo, Aremo niluu Ibadan. Eyi to pari ayeye isinku olojo mesan-an tijoba ipinle Oyo gbe kale lati bu ola fun oba alaye naa.
Sugbon bi eto isinku ohun ti dun to, larinrin to, opo awon eeyan lo ti n bu enu-ate lu bi won se n gbe oku re kiri. Ti won si tun n tee sile lawon ibi kookan fun odidi ose kan naa. Ileewe girama Igbo Elerin nijoba ibile Lagelu ni won ti koko te oba alaye naa nite-eye fawon araalu lati maa woo lojo monde ose to lo. Leyin naa ni won tun tee sinu agboole baba re, Ladunni laduugbo Oja'Gbo nirole ojo naa.
Lojo wesidee ojo kewaa osu yii ni won tun tee sile fawon araalu lati dagbere fun un ni gbongan nla Mapo. Ti won si tun tee sinu ile awon loba-loba to wa nile igbimo asofin ipinle Oyo lojo tosidee ose kan naa.
Eyi si lawon eeyan to mo nipa asa ati ise Yoruba si n toka si gege bi eyi ti ko ba oju mu rara. Enikan to je agba awo nile Ibadan, Baba Awo Olalekan Atikiriji salaye pe, ko ba ilana isedale ile Yoruba mu lati maa te oku oba alaye sita gba-n-gba fawon eeyan lati maa wo, nitori eni-owo ni won.
"Kii se nnkan to bojumu rara nile Yoruba lati maa te oku oba sita fawon eeyan lati maa wo, nitori eni-owo ni won.
Bo tie je po salaye pe, kii se pe iwa ohun ni aburu kankan to le se fun ilu. Sugbon, o ni sibe nise lo ye ki won pa oku naa mo. Eyi ti won fi n gbee kiri yii. Nigba to n soro lori isele naa, Otun Olubadan ile Ibadan, Agba Oye
Lekan Balogun sapejuwe tite ti won n te Olubadan nite-eye naa gege bi ona lati fun awon omo bibi ati olugbe ilu Ibadan loore-ofe "lati fife won si eni to ti je olori won han si gbogbo aye.”
“Erongba to wa leyin tite ti won te Olubadan nitee-eye ni lati fawon araalu to ti se olori le lori lanfaani ati fife ti won ni sii han gbogbo aye. Eni to kopa to po ni Oba Odulana, kii sii se ile Ibadan tabi ipinle Oyo nikan. Bi ko se ni gbogbo orileede Nigeria lapapo. Lati moriri ipa to ti ko ninu amuludun ati igbaye gbadun awon eeyan re lo je ki won te oku re ni Igbo-Elerin ati ni agboole baba re ni Aremo, Oja’gbo.
O ni “eto yi ni won se fun awon eeyan to ti se olori fun lat'igba yi wa loore-ofe ati kii po digboose. Ko to di pe won yoo sin oku re. Eto yi si ba ode-oni mu fun okunrin naa tigbagbo wa pawon eeyan re feran, ki won le bu ola fun un.”
Sugbon, ni asa ati ise ile Yoruba, eewo ni lati te oku oba alaye sile fawon eeyan lati maa pe wo.
Ojo tosidee, ojo kerinla osu kerin odun 1914 ni won bi Oba (Omowe) Samuel Osundiran Odulana Odugade kin-in-ni sinu idile Alagba Odulana Ayinla ni Igbo Elerin, ijoba ibile Lagelu.
Ohun kan to mu kawon omo Ibadan yato ni pe, yato si agboole won nigboro. Won tun gbodo ni oko lawon ilu to wa labe Ibadan. Nitori naa, yato si aba Fadina ni Igbo Elerin, Oba Odulana tun je omo agboole Ladunni laduugbo Oja'Gbo nigboro Ibadan.
Se omo ti yoo ba je Asamu, kekere ni yoo ti maa j'enu samusamu. Lati kekere ni Samuel ti bere sii fi amin asiwaju han, nigba to di odun 1922 nigba to je eni akoko ti yoo lo sileewe ninu molebi re.
Ileewe alakoobere Saint Andrews, Bamigbola lo ti bere iwe kika re. Leyin naa lo wa sigboro Ibadan, ileewe St Peters, Aremo lo si ti pari eko re lodun 1936. Nitori tawon ileewe girama sowon die nigba naa, o foruko sile fun ile-eko gbele (Correspondence College) lati safikun eko ati imo re.
Leyin to kuro nile-eko, o sise fungba die nileese UAC gege bi akowe ire-oko, ko to gba ise olukoni nileewe CMS, Jago nijoba ibile Ona-Ara asiko yi laarin odun 1938 si 1942.
Nitori ife to ni sile baba re, Oba Odugade lo darapo mo omo-ogun Iwo Oorun ile Africa (West African Volunteers Force) lati doju ija ko oga ogun ile Jamani, Adolf Hitler lasiko ogun agbaye eleekeji. Leyin ti ogun ohun pari lodun 1945, oun lo wa nidii idanilekoo fawon abode ogun niluu Eko to je olu-ilu orileede yii tele. O sise re ohun daadaa to bee ti won fun un ni ami-eye, eyi to mu kileese eto eko ijoba oyinbo fun un nise lodun 1946.
Ise re tuntun yii lo si fun un loore-ofe lati sunmo awon omowe asiko naa. Lara won si ni okunrin oludasile opo ile-eko, Oloye T.L Oyesina, eto to da ileewe girama Ibadan Boys High School sile atawon eeyan nla-nla asiko naa.
Odun 1959 lo feyinti lenu ise oba lati lo sin awon eeyan re nigba to dije dibo wole sile igbimo asofin to keyin saaju ominira orileede yii lodun naa. Asiko yii gan ni Olootu ijoba orileede yii, Alaaji Abubakar Tafawa Balewa yan an gege bi akowe ile igbimo asofin re. Ipo yii lo si mu ko wa nibi ipade nla awon orileede to n se asepo oro-aje (Commonwealth Conference) niluu London lodun 1963. Lodun yii kan naa lo di minisita keji fun oro osise. Bee si lo ti figba kan tabi omi-in sise okan-o-jokan fun orileede yii, eyi to mu kijoba Oloogbe Aare Musa Yar Adua fun un ni ami idanilola orileede yii, CFR. Bee si lo gba ami idanilola omowe ti ile-eko yunifasiti ekose imo-ero ilu Akure, ipinle Ondo lodun 2005.
Odun 1972 lo je Mogaji agboole won, to si to titi to fi je Olubadan ogoji lojo Jimoh, ojo ketadinlogun osu kejo odun 2007.
Ki Olorun tee safefe rere

No comments:

Post a Comment