Tuesday 16 February 2016

OLUBADAN tuntun soro; o ni nise lawon SERIKI n japoro.

Olubadan tuntun, Agba Oye Saliu Adetunji ba ALARIYA OODUA soro
Won maa n pa owe kan niluu Ibadan, won a ni "Oro oye Ibadan ko ni eja tabi akan ninu. Titi aye, akan ni yoo maa se". Eyi lo d'Ifa fun jije oye Olubadan ile Ibadan. Laipe yii ni awuyewuye kan sele leyin ti Olubadan ile Ibadan, Oba Samuel Osundiran Odulana Odugade kin-in-ni teri gb'aso nibi ti Oloye kan lati igun Seriki, Oloye Oyediji ni oun nipo naa to si. Bee, Oloye Saliu Adetunji to je Balogun ile Ibadan lawon igbimo Olubadan ni won fe nipo naa.
Akoroyin wa, YANJU ADEGBOYEGA ni gbolohun pelu Olubadan to n bo nipo naa laipe yii. E maa ba wa kalo...
Ibeere : - Kee to debi tee de lonii, tee ba boju weyin, yoo to odun meloo tee ti ro'le?
Idahun : - Bi ogoji odun l le die ni.
Ibeere : - Oju opo n ko?
Idahun : - Ti Balogun ni mo wa.
Odo baba wa, Olubadan Adebimpe ni Odinjo si ni mo ti bere oye jije.
Ibeere : - Taa ba wo asiko naa si isin-in, opo ipenija ni yoo wa. Nje a le gbo die nipa awon ipenija yii, ka fi kogbon?
Idahun : - Se e ri teeyan ba ti gba ona kan wole, ko si wahala. Sugbon, awon ohun to sele laarin igba yen, ti enikan mo on mo rii pe won gbe mi kuro nibi to ti ye ki n ti lo odun meta, lati le da mi pada seyin. Awon omo to je looya ni ki n je kawon o pe ejo. Mo ni mi o p'ejo. Mo ti gbaa ni kadara mi.
Nigba ti mo lo, ohun ti mo ti se sile, ti mi o pari. Gbogbo awon ti won n gbe lo sibe ko rii se, emi ni Olorun pada fun se. Ijoba ibile Ona-Ara ni. Lojo naa, ti oun si wa ni Mapo, o ye ki won fun mi ni Ariwa Ibadan. Ko je ki won o fun mi, o lo agbara re. Sugbon, Olorun ti sedajo tie naa.
Ibeere : - Eyin agba maa n so pe, mo koo a maa ni apeere. Popoyemoja nile yin, ibo ni oko yin nijoba ibile wo?
Idahun : - Onipepeye loruko aba wa. Ijoba ibile Oluyole lo bo si.
Ibeere : - Nigba ti Kabiyesi to waja wa laye, won sakitiyan lori oro aafin tuntun. Sugbon, ko tii niyanju titi olojo fi de. Igbese wo l'eyin fe gbe lati rii pe ise pari lori re loju ojo?
Idahun : - E seun. Oluwa yoo ran wa se. Nigba temi ati gomina n soro, a soro debe. Mo si mo pe pelu ogo Olorun, ti mo ba de ori apere, a o tun jo soo. Olorun yoo si ba wa see.
Ibeere : - Iyen okan. Awon afojusun nnkan daadaa wo le tun ni fun ilu Ibadan lasiko yin?
Idahun : - Ki Olorun fori ji baba wa Olubadan to gbe'se, gbogbo ohun ti won ba n fe naa la jo maa n so. Ohun kan to si mumu laya gbogbo wa, taa n be Olorun si ni ipinle Ibadan. A si ti kuro nigboro Ibadan nitori re ri, taa lo siluu Abuja. Agbejoro Akinjide lo lewaju wa lo nigba naa.
A o mo pe, eni to wa nibe lasiko naa ko nii see. Tee ba wo ilu Ibadan, e o rii pe kii se ilu mo. O ti di aye, awon ilu to dabi pe won ti wa lominira ara won. Won o to wa.
Sugbon, Olorun ma jee ka ri ogun abinu eni. A o mo nnkan taa se fun onitohun, nitori taa mo pe awon eeyan kan lo wa nidii re. Debi pe, Alaaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi gan fi enu sii pe ki won fun wa nipinle Ibadan.
T'eyin naa ba wo Ibadan lonii, e o rii pe o koja ohun teeyan n pe niluu.
Ibeere : - Taa ba ni ka woo. Ki Olorun ba wa te Olubadan ana safefe rere, ajosepo wo lo wa laarin yin nigba aye won?
Idahun : - Ajosepo to po ni. Nitori pe, baba mo pe emi nibi keta si won. Eni to si je oga temi, to je Balogun nigba naa, Agba Oye Sulaimon Omiyale, ti baba ba jokoo, awon a jokoo tele won. Emi naa yoo jokoo. A o jo wa maa so ohun taa n fe fun Ibadan.
A dupe lowo Olorun pe lonii, emi ni mo wa nipo Balogun. Ipo Balogun ti mo si wa ohun, awon eeyan ti n pe mi ni Olubadan lai tii gba opa-ase. Adura mi ni pe ki n le gba opa-ase. Ko si soju eyin naa. Ti won ba si wa gbe ade le wa lori tan, Olorun je ka pe nibe.
Ibeere : - E ti so daadaa nipa Olubadan to gbe'se. Nje e le so die nipa iwa won?  Nje a ri ohun taa le fi se eko ninu iwa won?
Idahun : - Baba feran ilu Ibadan pupo. O si feran gbogbo awa taa je ijoye re, nitori pe t'oro kan ba wa. Ko too fesi lee, yoo koko beere lowo awa taa je ijoye re. Ohun taa ba si so pe ko se ni yoo se. Baba kii da nnkan se.
Ibeere : - Lenu asiko ti won lo je ipe Olorun yii, orisirisi ero lo ti wolu Ibadan. Lara won ni aare orileede yii tele, Oloye Olusegun Obasanjo. A si gbo pe, won sabewo sodo yin. Ohun taa gbo ninu iroyin ni pe ipade atilekun mori se le jo se. Ki lawon ohun tee jo so?
Idahun : - E seun. Omooya lemi ati Oloye Obasanjo. Oro omooya la si jo so. Eyi ti kii se ohun taa le so fun un yin rara.
Ibeere: - A o gboo to ba ya. Abi bawo ni?
Idahun : - Ti Olorun ba so pe, e o gboo. O see se kee gboo. Nitori pe, iya kan lo bi awa mejeeji, bi mo se so saaju. Nitori naa, oro aarin ara wa la so. A tun ti jo soro laaro yi lori foonu. A nifee ara wa pupo ni.
A jo maa n damoran gan-an ni, nigba to n sejoba. Mo si dupe lowo Olorun pe, odun mejo to lo nipo, ko si aburu, nitori, to maa n tele imoran. Nitori naa, mo dupe lodo Olorun.
Ibeere : - Ki le ri soro awon igun kan to n so pawon ni oye Olubadan to si?
Idahun : - Se e ri awon yen. Se e mo pe, elomi-in a maa ja watiwati lori idaamu to ba baa. Won o le ma ja watiwati, sugbon watiwati won ko de ibikan nitori pe, ko si ohun to n je oruko ti won n je yen mo.
Ibeere : - Oro se wa di pe, emi lo ye ki n bo sori apere baba mi. Ti won si ti n dana, ti won n se ti won n so?
Idahun : - Se e rii, ti won ba pa adie tabi eran. Yoo maa ja watiwati, o si le se bee fun bi iseju mewaa tabi ju bee lo. Iru re lo n sele yen. Ko si nnkan to n je Seriki mo.
Lasiko baba mi, egbon mi, Oloye Akinloye. Oun naa ja watiwati pe ki Seriki le wole si oju opo Olubadan. Omooya si lemi atie, mo si n so fun un nigba yen pe, egbon mi, e lo wole si igun to ba wu yin ninu Balogun tabi Otun. Igun seriki tee wa yi, ko sona nibe. Yoo ni se mi o mo pe looya loun ni. Maa ni, mo mo pe looya ni yin.
Nigba tee lo siluu siluu oyinbo lodun 1944 lo ko'se looya. Nigba tee de, sebi e ba wa nibi taa n se ilu lo ni. Tee wa ki wa pe e ti de o.
Mo ni tee ba je looya, ko le ju ti Rotimi Williams lo. Nitori naa, e ma fokan sii. Ko le bo sii.
Yoo ni aburo mi, Akanmu yoo bo sii. Maa ni egbon mi, e wa nnkan mi-in so. 
Nitori naa, igun meji, yala Balogun tabi Otun nii je Olubadan. Oro eeyan je looya ko lo wa nile yi, asa ati ise ile Ibadan ni.
Ibeere : - Se ohun tee n so bayii ni pe, e o ri iwe ipejo kankan?
Idahun : - Won pe ejo. Sebi akowe wa la ran lo.
Ibeere : - Se e si ro pe, iyen ko le da nnkan sile?
Idahun : - Sebi ile-ejo ti so fun won pe, ko soro nibe.
Ibeere : - Sugbon, eni yi so pe, o niye owo toun na lori oro yi. Eyin naa le si kuku wa ninu igbimo Olubadan. Se ooto ni po gb'owo ranse?
Idahun : - Eni ti won ba gb'owo ranse si, e ni kawon funra won o soo. Ki won so bi eni naa gbaa lowo won ati eni ti won fi ran.
Lenu igba to gbo pe, emi ni mo fe joba yii, won ti wa ba mi. Ti mo si so fun won pe ki won o m'enu kuro nibe.
Ibeere : - Bo se je pe eya kaakiri agbaye lo wa niluu Ibadan yi, nje o see se ki enikan de ade pe oun ni oba awon eya oun niluu Ibadan?
Idahun : - Eni to ba je Yibo tabi Hausa ko le de ade kankan niluu Ibadan. Eni to ba fe de ade ko lo to fun un niluu re. To ba si ti dee, to ba ti fe wo ilu Ibadan yoo gbe nnkan re pamo ni.
Ibeere : - Ohun to fa ibeere yi wa ni pe, gbogbo igba la maa n gbo oba kinni kan. Awa naa si dake, a o soro. Bee ni igbimo Olubadan ko wi nnkan kan?
Idahun : - Se e rii, tee ba gbo pe eeyan je nnkan kan niluu Ibadan. Nitori, Olubadan funra re fowo sii ni. Sugbon, pe Olubadan lowo sii ko fun won loore-ofe ati de ade. Olori eya won lo fi won je.
Ibeere : - Lenu igba ti Olubadan gbe'se, nje eyin atawon oloye to ku si n rira?
Idahun : - A n rira. Koda, won wa nibi lanaa. A jo lo sepade pataki kan, nibi ti won ti wa f'owo sii pe ki n je Olubadan. Won ti se iwe ti gbogbo won buwo lu, won ti fi ranse si gomina atawon afobaje pe ki won o maa mura sile. Won ti yan eni bayii ni Olubadan, eni naa si ni Saliu Adetunji.

No comments:

Post a Comment