Tuesday 12 July 2016

WALL of PRAISE fi kanga igbalode ati ile-iyagbe ta ileewe lore.

WALL of PRAISE fi kanga igbalode ati ile-iyagbe ta ileewe lore.
Ijo omoleyin krisiti kan, Wall of Praise Christian Centre nibamu pelu akosile Iwe Mimo Bibeli to ni "Olorun fe oninu dundun oloore ti fi kanga igbalode kan ati ile-iyagbe ta ileewe Orile Oko Community ati ilu naa lore. Koda, pelu ero jenereto ti won yoo maa lo lati fa omi ohun ni pelu.
Ijo ohun, eyi ti ko ni nnkan se pelu ijoba (NGO) labe idari Ajihinrere Samson ati iyawo re Alufaa-obinrin Abigail Adegboyega lawon eeyan ilu Orile Oko si ti kan saara si fun igbese naa. Lasiko to n soro nibe, akowe ijoba ibile Ariwa Remo, Ogbeni Sorinola Rasheed to soju ijoba nibi ayeye ohun ni ileese iranse Wall of Praise ti ko oruko re sinu iwe itan rere lawujo awon ajo ti kii se tijoba lorileede yi
"Nipase ohun taa ri lonii, ileese iranse yi ni yoo je ajo ti kii se tijoba akoko ti yoo fi irufe ohun nla bayii ta ileewe kan lore lorileede yii. Eyi ti yoo so oruko re di manigbagbe fawon akekoo to wa nileewe naa bayii ati awon to tun n bo." Oga agba ileewe naa, Ogbeni Oladimeji ti ko le pa idunnu re mora toka pe omo iko agunbaniro kan to sinru ilu nileewe ohun lo ti koko se irufe akanse ise bee nileewe naa. Sugbon, to je salanga ni "eyi ti ileese iranse yi ti so di ti igbalode bayii."
Adari ileese iranse ohun, Ajihinrere  Adegboyega ni akanse ise naa je imuse iran ise iranse toun n sise to. Pelu afikun pe, ko ni nnkan kan se pelu ireti esan oselu kankan. To si wa ke sawon akekoo ileewe naa lati maa jowu nnkan daadaa bi eyi nigba ti won ba dagba. Bee lo dupe lowo ijoba ipinle Ogun fun oore-ofe to fun un lati pese awon nnkan amayederun yi, to si wa gbawon obi nimoran lati samojuto awon omo won daadaa, ki won le wulo funra won lojo iwaju. Ko sai ke sijoba apapo lati se ona to so ilu naa papo pelu ipinle Eko.
Lara awon eeyan to tun soro nibe ni, okan lara awon igbimo ileese iranse naa, oludasile ijo Christ Disciple Faith Ministry niluu London, Aposteli
Stephen Popoola, eni to lu Ajihinrere ati Alufaa Adegboyega logo enu fun afojusun won ohun.

No comments:

Post a Comment