O tan! ANTP yo ASAOLU danu, JIMOH ALIU lo gba'po re
Yanju Adegboyega
Pelu igbese tawon asaaju egbe osere tiata, ANTP gbe laipe yii, oro to n ja nile lori ipo aare egbe naa ti fori ti sibi kan bayii. O si ti foju han gba-n-gba bayii pe, Omowe Victor Asaolu ti kuro nipo gege bi olori egbe naa. Asiri iroyin kan to tu sakoroyin wa lowo lopin ose to koja yii ti fidii re mule pe, igbimo alase ati maje-o-baje egbe ti ko okunrin naa patapata.
Gege bi enikan to wa ninu ipade nla kan to waye nile egbe osere, ANTP to wa ninu oja agbaye Expoyo laduugbo Samonda, Ibadan lojo tosidee ose to koja, igbimo alakooso egbe ANTP ti fi onte lu iyansipo aare egbe naa nigba kan ri, Oloye Jimoh Aliu gege bi aare egbe naa tuntun. Bee si ni won yan Oloye Yemi Elebuibon gege bi igbakeji re.
Alaaji Kareem Adepoju, eni ti gbogbo eeyan tun mo si Baba Wande ni won yan gege bi akowe, nigba ti won fowo si Ogbeni Jare Adeniregun gege bi akapo.
Akoroyin wa gbo pe, gbogbo omo egbe to wa nibi ipade alagbara ohun lo fohun sokan lori iyansipo awon eeyan naa. Ti won si sapejuwe po ti fese mule loju ese nibe.
Ju gbogbo re lo, owo kilanko Omowe Victor Asaolu ti yo kuro lawo isejoba egbe osere ANTP. Eyi to si ti wa fopin si wahala to ti n fi gbogbo igba waye lori oro ipo aare egbe naa.
Ta o ba gbagbe, o feree je pe ojumo kan ijangbon kan ninu egbe osere ANTP lat'igba tile-ejo giga ijoba ipinle Oyo kan to wa niluu Ibadan ti gba ipo aare egbe naa fun Asaolu, to si yo Omooba Jide Kosoko kuro. Ase ile-ejo ohun lo si faa tawon kan ti idajo naa ko dun mo ninu fi lo da egbe osere tuntun kan ti won pe ni TAMPAN sile.
Ni bayii, Alariya Oodua le fi gbogbo owo soya pe, igbimo agba egbe ANTP ti yo Asaolu nipo bayii. Jimoh Aliu, eni ti Asaolu se akowe egbe labe akooso re lasiko to se aare saaju lo si gba ipo re naa.

No comments:
Post a Comment