Ikunle Abiamo o! E wo idi AANU bo se wu lat'igba ti won ti bii.
--- Egberun lona irinwo naira din die lo n wa lati sise-abe.
Yanju Adegboyega
Omo odun merin ni omodekunrin yii, Aanu Rafiu, sugbon, ohun kan to wu nidii re lat'igba ti won ti bii ko je ko lo nile rara. Bee si ni iya re ko le sise kankan, nitori ko seni ti yoo gbee sile fun. Eyi to je ki atije ati atimu nira fun won. Bee owo to le ni egberun lona oodunrun naira ni won fe fi sise-abe fun un. Gege baa se gbo, lati igba ti won ti bi Aanu ni won tin sakiyesi kini ohun tawon onimo isegun oyinbo pe ni 'NEUROFIBROME to wu jade bii baasi eran nibi abala idi re apa osi.
Akoroyin wa gbo pe, oro ohun gan lo si mu ki baba re sa kuro nile, to si fi omo naa sile pe iya re, Aishat nlati maa da gbe bukaata re. Lojo kan, alaga egbe awon akoroyin obinrin lorileede yii, NAWOJ, eka tipinle Oyo, Arabinrin Foluso Lala salabaapade iya omo naa laduugbo kan. Ara abiamo si taa, eyi to je ko pinnu lati beere fun iranwo lodo awon eleyinju aanu omo orileede yii fun ise-abe ti won fe se Aanu.
Gege baa se gbo, leyin ayewo finnifinni nileewosan ekose isegun UCH lawon dokita ti ni ki Aishat lo wa egberun lona orinleloodunrun din marun-un naira, N365, 000 wa fun ise-abe ti yoo mu ki idi re naa pada bo sipo to ye ko wa.
Nigba to n bakoroyin wa soro, Aishat Rafiu to je iya Aanu, eni to loun sese pari iwe girama kewaa soo di mimo pe, lat'igba ti oun ti bi omo naa ni won ti sakiyesi ohun to n se naa, sugbon ti ko si oluranlowo kankan lati sise-abe ti won ni ki won se fun un. Nitori ti baba omo naa ti salo, to si fi oun nikan sile lati maa da gbo bukaata re.
Aishat ko sai toka pe, baba agba omo naa n se iwonba ohun ti apa re ka lati rii pe won n jeun. Sugbon, ohun to mu oun lokan bayii ni bi ise-abe omo naa yoo se je sise kiakia nitori tawon dokita ni bo ba se n pe si ni owo re yoo se maa po sii.
Ninu oro to ba wa so, Arabinrin Lala ni 'nigba ti mo ri omode yen, ara mi bu ma'so. Mo si beere lowo iya re pe, igbese wo lo ti gbe lori oro naa. O si salaye pe oro owo ni, eyi lo je ki n telee lo yoju si awon dokita nileewosan UCH. Nibe si ni won ti so iye ti yoo na-an lati se ise-abe naa. A wa n lo asiko yi lati rawo ebe sawon eleyinju aanu omo orileede yii lati ro ojo iwaju omode yii. Ki won ran wa lowo lori re.
Fun iranlowo owo tabo ohunkohun, e pe alaga egbe awon akoroyin obinrin, NAWOJ nipinle Oyo lori 08023439198 tabi kee pe Olootu si 08038649362
E aeun gan ni o.

No comments:
Post a Comment