Wednesday 20 July 2016

FUJI TO BAM: PASUMA se bebe niluu Oyo

Alaaafin ilu Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi keta ti gboriyin fun ileese oloti Nigerian Breweries lori akitiyan re lati rii pe orin fuji ko reyin ninu awon orin to ku. Oba Adeyemi soro yii lasiko idije ti irawo fuji tuntun ti eka ileese naa Goldberg sagbekale re, eyi to waye ni papa isere Durbar.
Lasiko to n bakoroyin wa soro nibi eto naa, oga agba kan nileese ohun, Ogbeni Funso Ayeni salaye pe, idagbasoke orin fuji lo je ileese re logun. O ni "taa ba n soro eto alarinrin tileese a-pon-oti Nigeria Breweries gbe kale, ti won fi oti Goldberg ta koko re, eyi ti won pe ni FUJI TO BAM. Odu ni eto naa kii se aimo fun tagba-tewe, paapaa lawujo awon onifaaji.
Eto Fuji to Bam yii ni won sagbekale re lati maa sawari awon ogo ati irawo tuntun nidii ise orin fuji. Lara anfaani ti won n fun awon onifuji to sese n dide bo ni ki awon naa le korin po pelu awon agba-oje olorin fuji.
Ogbeni Ayeni so pe aseyori nla ni eto yi ti se laarin odun kerin ti won ti bere ati pe otolorin ni todun yi, nitori won yoo gbe ise agbase rekoodu fun olorin to ba gbegba oroke, yato si owo ti won maa n fun won lateyinwa. 
Lara awon gbajumo olorin to wa nibe ni Oba Asakasa, Abass Akande Obesere; Oga Nla fuji, Wasiu Alabi Pasuma atawon irawo onifuji mi-in.
Lara awon oludije to yan-an yo nibi idije ibi keta si asekagba (Quarter Final), ti yoo si lo koju ara won ninu idije to kangun si asekagba (Semi Final) ni, Alausa Olalekan; Kuteyi Sikiru; Olowokere Ayoola; Sadiq Ishola; Mufutau Alabi; Idris Morakinyo; Alayo Owoomo; Temitope Ajani; Yusuf Atanda; Abdul Amoo Ajibola.
Awon to ku ni, Olaniregun Habeeb; Oluwagbemiga Adeyeye; Bukola Omo-Daddy; Adewale  Saheed Ishola; Ilesanmi Sogo; Abiodun Oloto; Wasiu Omo Bello; Sir Shina Akanni Ademola; Tayelolu Akanni Confidence ati Oyeniyi Ismaila

No comments:

Post a Comment