Wednesday 20 July 2016

FUJI TO BAM: PASUMA se bebe niluu Oyo

Alaaafin ilu Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi keta ti gboriyin fun ileese oloti Nigerian Breweries lori akitiyan re lati rii pe orin fuji ko reyin ninu awon orin to ku. Oba Adeyemi soro yii lasiko idije ti irawo fuji tuntun ti eka ileese naa Goldberg sagbekale re, eyi to waye ni papa isere Durbar.
Lasiko to n bakoroyin wa soro nibi eto naa, oga agba kan nileese ohun, Ogbeni Funso Ayeni salaye pe, idagbasoke orin fuji lo je ileese re logun. O ni "taa ba n soro eto alarinrin tileese a-pon-oti Nigeria Breweries gbe kale, ti won fi oti Goldberg ta koko re, eyi ti won pe ni FUJI TO BAM. Odu ni eto naa kii se aimo fun tagba-tewe, paapaa lawujo awon onifaaji.
Eto Fuji to Bam yii ni won sagbekale re lati maa sawari awon ogo ati irawo tuntun nidii ise orin fuji. Lara anfaani ti won n fun awon onifuji to sese n dide bo ni ki awon naa le korin po pelu awon agba-oje olorin fuji.
Ogbeni Ayeni so pe aseyori nla ni eto yi ti se laarin odun kerin ti won ti bere ati pe otolorin ni todun yi, nitori won yoo gbe ise agbase rekoodu fun olorin to ba gbegba oroke, yato si owo ti won maa n fun won lateyinwa. 
Lara awon gbajumo olorin to wa nibe ni Oba Asakasa, Abass Akande Obesere; Oga Nla fuji, Wasiu Alabi Pasuma atawon irawo onifuji mi-in.
Lara awon oludije to yan-an yo nibi idije ibi keta si asekagba (Quarter Final), ti yoo si lo koju ara won ninu idije to kangun si asekagba (Semi Final) ni, Alausa Olalekan; Kuteyi Sikiru; Olowokere Ayoola; Sadiq Ishola; Mufutau Alabi; Idris Morakinyo; Alayo Owoomo; Temitope Ajani; Yusuf Atanda; Abdul Amoo Ajibola.
Awon to ku ni, Olaniregun Habeeb; Oluwagbemiga Adeyeye; Bukola Omo-Daddy; Adewale  Saheed Ishola; Ilesanmi Sogo; Abiodun Oloto; Wasiu Omo Bello; Sir Shina Akanni Ademola; Tayelolu Akanni Confidence ati Oyeniyi Ismaila

Monday 18 July 2016

Eegun Oloolu kilo fawon araalu.

Eyi ni bi eegun Oloolu yoo se rin
-- Bee lo kilo fawon araalu
Yanju Adegboyega
Ojo Monde - To ba ti kuro nile re ni Ode Aje, yoo gba Oranyan de Idi Arere bo si aafin Olubadan, Oba Saliu Adetunji ni Popoyemoja. Yoo gba ibe de Oja'Ba lo si Ogbori Efon nile Balogun ile Ibadan, Agba Oye Owolabi Olakulehin. Yoo gba ibe lo si Alafara Olubadan lo si Atipe de Oke Ofa, Baba Isale. Leyin naa ni yoo lo sile Otun Olubadan, Agba Oye Lekan Balogun ni Ali Iwo. Ibe si ni yoo gba dari sile re.
Ojo Tusidee - To ba ti kuro nile re ni Ode Aje, yoo gba Oja'Gbo de ile Balogun ile Ibadan, Agba Oye Owolabi Olakulehin. Yoo gba Ita Baale de Ogbori Efon nile Ekerin Olubadan, Agba Oye Abiodun Daisi. Ibe ni yoo gba de ile Olubadan ni Popoyemoja. Ko to maa lo sile Osi Olubadan, Agba Oye Rasidi Ladoja ni Born Photo. Leyin naa ni yoo lo sile Asipa Olubadan, Agba Oye Eddy Oyewole ni Foko ati ile Osi Balogun, Agba Oye Tajudeen Ajibola ni Agbeni. Yoo gba ibe de ile Fijabi ati Mogaji Olujide Osofi ni Oja'Ba, de ile Omiyale ati Olunloyo.
Yoo gba ibe dele Arabinrin Odunola ati Mogaji Olu-okun pelu Mogaji Ekolo ni Oke Ola de Ile Tuntun, lo si Odinjo nile Eekarun-un Balogun, Agba oye Lateef Adebimpe. Leyin naa ni yoo ile Dauda Gbedeogun ni Modina, lo sile Ege. Ibe si ni yoo gba de ile Otun Balogun, Agba Oye Femi Olaifa ni Idi Aro. Ko to pada sile re.
Ojo Wesidee - Yoo gba Oke Adu lo sile ijoba ipinle Oyo, Gomina Abiola Ajimobi. Leyin naa ni yoo lo sile Otun Olubadan, Agba Oye Lekann Balogun ni Ali Iwo, leyin naa ni yoo lo sodo Amofin Niyi Akintola, Amofin Ajobo, Amofin Azeez ati Amofin Afolabi ni Gate. Yoo gba Yemetu lo si Adeoyo de odo Mogaji Kadelu ati Oloye Afolabi ni Temidire, leyin naa ni yoo gba Labiran pada sile re.
Tosidee - Ago olopaa Agugu ni yoo gba koko gba lo si, leyin naa ni yoo lo sile Mogaji Agugu, Oloye Ogunsola Anisere. Ibe ni yoo gba de odo Alaaji Elewure, Abileko Adijat Alagbe, Abileko Olanisebe ati Mogaji Ayegbokiki. Ibe si ni yoo gba de odo Alaaji Kokodowo, leyin naa ni yoo lo sodo Baale Atolu ati Ifa Boys ni Gbaremu. Ibe ni yoo gba lo si Sekoni, yoo de odo Lemoomu Aje ati Baale Akamo.
Leyin naa ni yoo de odo Jekayinfa, Alaaji Olorunlogbon, Falere Fagbenro ati Yisau Ajoke. Yoo de odo Oloye Adesina ni Gangansi, ibe ni yoo gba lo sodo Baale Ewuola, yoo de odo Baale Eniayenfe, Seriki Muritala Babalola, Baale Osuolale ati Alaaja Sijuade. Ibe ni yoo gba de odo Mogaji Aje, Oloye Raimi Oyerinde, yoo gba ibe de Ogbere Idi Osan de odo Bose omo Titilayo ni Maaku, pada si Oremeji, nibi ti yoo gba pada sile re n'Ile Aje.
Ikilo Pataki!!!
Eeegun Oloolu fi asiko yi kilo fawon onimoto atiu olokada lati rii pe, won ko gbe obinrin pade re. Nitori ti yoo maa yoju wonu awon moto lati rii pe ko si obinrin nibe.
Enikeni to ba tapa si ikilo yii yoo da ara re lebi.

Tuesday 12 July 2016

WALL of PRAISE fi kanga igbalode ati ile-iyagbe ta ileewe lore.

WALL of PRAISE fi kanga igbalode ati ile-iyagbe ta ileewe lore.
Ijo omoleyin krisiti kan, Wall of Praise Christian Centre nibamu pelu akosile Iwe Mimo Bibeli to ni "Olorun fe oninu dundun oloore ti fi kanga igbalode kan ati ile-iyagbe ta ileewe Orile Oko Community ati ilu naa lore. Koda, pelu ero jenereto ti won yoo maa lo lati fa omi ohun ni pelu.
Ijo ohun, eyi ti ko ni nnkan se pelu ijoba (NGO) labe idari Ajihinrere Samson ati iyawo re Alufaa-obinrin Abigail Adegboyega lawon eeyan ilu Orile Oko si ti kan saara si fun igbese naa. Lasiko to n soro nibe, akowe ijoba ibile Ariwa Remo, Ogbeni Sorinola Rasheed to soju ijoba nibi ayeye ohun ni ileese iranse Wall of Praise ti ko oruko re sinu iwe itan rere lawujo awon ajo ti kii se tijoba lorileede yi
"Nipase ohun taa ri lonii, ileese iranse yi ni yoo je ajo ti kii se tijoba akoko ti yoo fi irufe ohun nla bayii ta ileewe kan lore lorileede yii. Eyi ti yoo so oruko re di manigbagbe fawon akekoo to wa nileewe naa bayii ati awon to tun n bo." Oga agba ileewe naa, Ogbeni Oladimeji ti ko le pa idunnu re mora toka pe omo iko agunbaniro kan to sinru ilu nileewe ohun lo ti koko se irufe akanse ise bee nileewe naa. Sugbon, to je salanga ni "eyi ti ileese iranse yi ti so di ti igbalode bayii."
Adari ileese iranse ohun, Ajihinrere  Adegboyega ni akanse ise naa je imuse iran ise iranse toun n sise to. Pelu afikun pe, ko ni nnkan kan se pelu ireti esan oselu kankan. To si wa ke sawon akekoo ileewe naa lati maa jowu nnkan daadaa bi eyi nigba ti won ba dagba. Bee lo dupe lowo ijoba ipinle Ogun fun oore-ofe to fun un lati pese awon nnkan amayederun yi, to si wa gbawon obi nimoran lati samojuto awon omo won daadaa, ki won le wulo funra won lojo iwaju. Ko sai ke sijoba apapo lati se ona to so ilu naa papo pelu ipinle Eko.
Lara awon eeyan to tun soro nibe ni, okan lara awon igbimo ileese iranse naa, oludasile ijo Christ Disciple Faith Ministry niluu London, Aposteli
Stephen Popoola, eni to lu Ajihinrere ati Alufaa Adegboyega logo enu fun afojusun won ohun.

O tan! ANTP yo ASAOLU danu, JIMOH ALIU lo gba'po re

Tuesday 5 July 2016

O ma se o! Iya MUFU LANIHUN ku.

Iroyin a gbo sogba nu!!!
Iya okunrin gbajumo onisowo ilu Ibadan nni, Alaaji Mufutau Ajadi Lanihun, Giwa Adinni ipinle Oyo ku laaro yii.
Osu yii lo pe odun kan ati osu merin ti Lanihun funra re ku leyin aisan ranpe. Ta o ba gbagbe, iya re wa laye lasiko iku re. Koda, nise ni won mu iya naa kuro ninu ile, ki won to le sin oku re.,

Sunday 3 July 2016

Ede aiyede laarin osise atijoba Oyo: egbe awon obinrin akosemose pe fun idasi Olubadan

Ede aiyede laarin osise atijoba Oyo: egbe awon obinrin akosemose pe fun idasi Olubadan
Yanju Adegboyega
Nitori ti ede aiyede to n lo laarin ijoba ipinle Oyo ati egbe awon osise n ko won lominu, egbe awon obinrin akosemose bii meedogbon kan, eyi to wa lati awon egbe kaakiri orileede yii ti kesi Olubadan ile Ibadan, Oba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunniso kin-in-ni lati da soro ohun.
Awon obinrin ohun ti Ojogbon Adetoun Ogunseye ati AbilekoBola Doherty pelu awon mi-in ko sodi lo fi aidunnu won han si bi wahala naa se n tesiwaju ati ipa buruku to ti n ni lori awujo, pelu afikun pe gege bi baba fun gbogbo eeyan, eni ti ko si ninu egbe oselu kan tabi ni afojusun ipo oselu. Oba alaye, eni odun metadinlogorin yii lo wa nipo to daa pupo lati wa ojutuu si aigbora-eni ye to wa laarin igun mejeeji naa.
Arabinrin Doherty ni 'Gege bi iya, inu wa ko dun si wahala to n lo lowo laarin ijoba ati osise nipinle Oyo ati ipa to ti n ni lori awujo wa. Awon osise ko lo sibiise, awon akekoo ati oluko ko lo sileewe, eyi kii se nnkan to dara rara. Gege bi ajo ti kii se tijoba, NGO, eyi to ko egbe awon obinrin akosemose bii FIDA, FOMWAN, NCWS, YWCA, AGES atawon mi-in sinu, a nigbagbo pe, oba alaye bii ti yin, eyi ti ko ni nnkan kan se pelu egbe oselu kan tabi omi-in lo le da si oro ohun.
Nigba to n fesi, Olubadan ile Ibadan, Oba Saliu Adetunji so pe,oun ko nii kaare lati maa da si wahala to wa laarin ijoba ati osise, titi ti oro naa yoo fi niyanju. Gege bi oba alaye yii se wi, o ni, enikeni ko setan lati di ebi oro naa ru enikeni ninu awon igun mejeeji. Sibe, bi awon akekoo se n jokoo kale, lai lo sileewe je ohun to n fun gbogbo eeyan ni efori.
O fi okan awon eeyan naa bale lati kan si gomina ipinle Oyo, Sineto Abiola Ajimobi ati awon asiwaju egbe osise lai nii pe rara, pelu ireti lati wa ojutuu si aawo naa. Ki alaafia le tun pada joba nile yi.
Nigba to n dupe lowo awon egbe obinrin naa fun bi won se so ero okan won ohun jade lori wahala to wa laarin osise atijoba, Oba Adetunji toka pe, pelu atileyin Olorun, awon akekoo yoo pada sinu kilaasi lati maa kekoo won ni kete ti igun mejeeji to n ja ba ti gba ifikun-lukun laaye.
Ewe, Oba Adetunji ti da si oro aawo kan to wa laarin igbimo awon apoogun oyinbo, Pharmacitical Council of Nigeria ati awon egbe to n ta oogun kemiisti, National Association of Patent Medicines Dealers (NAPPMED). To si ti petu sawon mejeeji. Nigba to n dupe lowo awon asoju ajo PCN fun agboye won. Oba Adetunji ro awon kemiisti to wa nile Ibadan lati tele ofin ati ilana to ro mo ise ti won n se.

Friday 1 July 2016

Ikunle Abiamo o! E wo idi AANU bo se wu lat'igba ti won ti bii.