O tan! Oro oko-ere EDA ONILE-OLA fe da wahala sile ninu TAMPAN.
Yanju Adegboyega
O see se ki wahala to wa laarin egbe awon osere tiata, ANTP ati egbe osere adeyalo re, TAMPAN gba ona mi-in yo lasiko yi. Ki awon omo egbe osere tuntun naa si kan awon asiwaju egbe naa labuku. Gege baa se gbo, awon omo egbe osere tuntun naa n naga lati kopa ninu fiimu olowo nla kan ti okunrin gbajumo agba osere nni, Oloye Lere Paimo n se lowo niluu Lagun, Ibadan bayii.
Akoroyin wa gbo pe, nise ni okunrin oludari ise ohun, Abiodun Adekanbi pase fawon omo egbe TAMPAN to yoju si oko-ere naa lati lo gba iwe-ase wa lowo aare won, Ogbeni Dele Odule ti won ba setan lati kopa ninu fiimu ohun.
Se saaju asiko yii la gbo pe, awon asiwaju egbe osere TAMPAN ti pase pe kawon omo egbe naa ma pe awon omo egbe osere ANTP sise yoowu ti won ba fe se, ki won si ma yoju si eyi tawon tohun naa ba n se. Gege baa se gbo, igbagbo won ni pe, ti won o ba pe awon eeyan naa sise, to si nira fun won lati jeun. Won yoo wa darapo mo egbe tiwon.
Sugbon, oro kan sele laipe yii, nigba tawon agba egbe kan lo kopa ninu ise kan ti Oloye Kareem Adepoju ti gbogbo eeyan tun mo si Baba Wande pe siluu Osogbo, eyi to mu ki egbe gbe igbimo kan dide lati da seria fun won. Sugbon, ti oro ohun ko f'ori ti sibi kan titi dasiko yi.
Enikan tie ni, ohun to fe mu kawon omo egbe gboju agan sawon asiwaju egbe osere TAMPAN lasiko yi ni bi won se ni Dele Odule funra re so pe, ti Baba Wande ba tun pe oko-ere mi-in lola. Oun gan-an wa lara eni akoko ti yoo debe lati kopa. A gbo pe, oro ohun dun awon omo egbe pupo, nitori ti won ni awon asiwaju egbe ti ko won sina pupo nipase ase ti won pa nigba naa. Eyi ti won lo ti mu ki opo won so awon anfaani lati di gbajumo nu, ti won si tun ti tipa bee di ota awon ti won ko pe sise.
Ju gbogbo re lo, ise olowo nla ti Eda Onile-Ola gba naa lakoroyin wa gbo pe awon osere ti ko din ni eedegbeta ni yoo kopa ninu re yato sawon osise mi-in gbogbo. Enikan to bakoroyin wa soro salaye pe, okunrin oludasile ileese Telifisan aladaani akoko lorileede yii, Galaxy, Ogbeni Steve Ojo lo gbe owo nla ti won fi n sise naa kale.
A gbo pe, okunrin yii lo gba ise agbase lati maa fun awon ileese telifisan kaakiri orileede yii ni awon ere onise. Koda, a gbo pe, odidi ere tiata odun kan, eyi tii se ose mejilelaadota gbako ni won n se lowo niluu Lagun naa bayii.

No comments:
Post a Comment