Tuesday 28 June 2016

E pa ede Yoruba ni dandan lawon ileewe alakoobere ati girama - OLUBADAN




Foto ; Awon akekoo ohun pelu Olubadan ile Ibadan, Oba Saliu Adetunji, Aje Ogungunniso kin-in-ni.
E pa ede Yoruba ni dandan lawon ileewe alakoobere ati girama - OLUBADAN
Yanju Adegboyega
 Olubadan ile Ibadan, Oba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunniso kin-in-ni ti ke sawon gomina ile Yoruba lati pa kiko ati kika ede naa ni dandan lawon ileewe alakoobere ati girama. Oba Adetunji soro yi lasiko to n gbalejo awon akekoo omo ile America bii meedogun kan to n ko ede Yoruba (2016 Yoruba Group Study Abroad, YGPA) nile-eko giga yunifasiti Ibadan laafin re to wa Popoyemoja.
Oba alaye yi toka pe,igbese ohun pon dandan nile Yoruba lati le daabo bo ojo iwaju ede abinibi agbegbe ohun. Eyi to so pe 'o n fojoojumo ku', to si wa ni, o nilo igbese kanmo kia. Ki awon obi lo ko asa siso ati kiko awon omo won ni ede naa nigba gbogbo.
“Nise ni mo maa n fi gbogbo igba se mo lori bi ede wa, Yoruba se n ku lojoojumo, nipase ai lakasi awon obi kan to ko ede abinibi won sile. Ti won o si tun je kawon omo won soo pelu.”
Olubadan kedun pe awon obi ati ijoba ko se ohunkohun  “lati doola ede wa lona iparun” pelu afikun pe, “mo paa lase pe, ede taa gbodo maa so laafin ni Yoruba ati ko gbodo si ede mi-in ju Yoruba lo.”
Oba Adetunji wa gbawon obi ati alagbato nile Yoruba nimoran lati maa se koriya fawon omo won, lati maa so ati ko ede Yoruba, pelu afikun pe “eya yooeu ti ede re ba ti ku, oun funra re ti parun”.
Saaju lawon asiwaju iko ohun, Ojogbon Moses Mabayoje lati yunifasiti ile Florida ati Omidan Tolu Ibikunle lati eka eko ede Yoruba ni yunifasiti ile Ibadan salaye pe abewo iko naa si Oba Adetunji je lara eto fun awon akekoo naa lati ni imolara ede, eyi ti won nifee si ati lati fi ara ro ara pelu asa Yoruba.
Nigba ti won n lu Olubadan logo enu lori abewo won sii, awon eeyan naa be oba alaye ohun lati rawo ebe sawon ijoba leleka-jeka lati pese aaye kan nibi ti won yoo maa se  awon ohun to jo mo itan nipa Ibadan lojo si. Nibi tawon akekoo ede Yoruba yoo ti maa ni oore-ofe lati mo nipa ilu naa atawon akoni re to ti koja lo.

No comments:

Post a Comment