Thursday 25 February 2016

Awon toogi ja n'Ibadan, leeyan mefa ba ku

N'Ibadan, awon omo-isota ja, won paayan repete.
Nise l'oro di "boo lo, o yago" fun mi lona lojo tusidee ose to koja yii laduugbo Oja'Ba niluu Ibadan nigba tawon omo isoa kan kolu ara won, ninu eyi taa gbo pe ko din leeyan mefa to ba isele ohun rin. Tawon olugbe adugbo naa ko si le lo tabi bo nidii ise oojo won.
Awon egbe omo isota ohun ti won pe ni Idowu ati Zaccheus la gbo po n ba igun omo isota mi-in ti enikeni ko moruko re ja, sugbon ta o le so pato ohun to fa wahala laarin won naa. Bi awon kan se n so pe, ija "emi ju o, iwo o ju mi" ni, bee lawon kan so pe oro owo kan lo dija laarin won.
Yato si eyi, awon kan ni igun omo-isota Ekugbemi ati Oluomo lo n bara won fa wahala. Eyi to wu ko, ooto ibe ni pawon olugbe adugbo naa ko le sun oorun asundiju fun bi ojo meta ninu ose to koja naa. Nitori taa gbo pe, ojo sannde ose to lo lohun-un ni won ti bere ijangbon naa.
Akoroyin wa gbo pe, wahala sele nirole ojo tusidee, nigba tawon igun Idowu gbiyanju lati gbesan ija kan to ti waye saaju nibi ti okan ninu awon omo eyin re ti ku. Eni to ba wa soro ni, eyi lo mu ki won lo dena de awon omo igun keji ti won o daruko naa pelu iranlowo awon igun omo-isota Zaccheus laduugbo Gege Adero, Ibadan.
Elomi-in to tun ba wa soro salaye pe, ohun to fa wahala ohun gan ni bi Idowu se lo da ariya kan tawon kan n se laduugbo Mapo ru, eyi ti won pe ni "Obo Day". Eni naa ni, nise ni Idowu yii maa n fonnu kiri pe omo egbe ajijagbara ile Yoruba, OPC loun. Bee, won ti lee ninu egbe naa nigba to se asemase kan. Eni yii so fun akoroyin wa pe, nise lawon to n se ariya to lo daru naa luu ni alubami, eyi to si mu ko pada lo ko awon omoleyin re wa lati wa gbeja re.
Enikan tisele naa soju re ni awon ohun-ija oloro bii akufo igo ni won koko n lo fi ja, sugbon nigba ti yoo fi di ojo wesidee, won ti bere sii lo awon ohun-ija oloro bi ibon ati ada. Gbogbo awon oloja to wa laduugbo naa lo n sare pale oja won mo, nigba tawon omo isota yii n le ara won wonu agboole to wa nibe.
Nigba tawon olopaa si de sibe ni wahala ohun tun ro'le die. Tit dasiko taa n ko iroyin yi jo lawon olopaa si wa kaakiri agbegbe ohun pelu oko ijagun lati le rii pe alaafia joba. 
Akoroyin wa gbo pe, awon ohun-ija oloro tawon omo-isota yii n ko kiri lai beru lo mu ki opo awon ontaja adugbo naa ti soobu won pa fun opolopo wakati. Bi awon kan n so pe eeyan meta lo ku, lawon kan n so pe mefa leni to ku. Sugbon, olopaa ni enikan soso lo ku nibe.
Eni to ba wa soro ni "a o mo nnkan to sele gan. A gbo pe, irole tusidee ni won ti bere, ti won n fi akufo igo bara won ja. Sugbon, laaro yii ni won sadeedee bere sii lo awon ohun-ija bii ibon.
"Nise la ha saarin won nibi, koda a o le ta nnkan kan lataaro taa ti de. Nigba ta o le si soobu. O ga gan-an ni o," 
Sugbon, enikan so pe "eeyan mefa lo ti ku lenu igba ti won bere wahala won. Lale ojo tusidee ni won sa omokunrin kan to n bo lati enu ise re ni Gate. Ojo wesidee ni omokunrin yen ku nileewosan UCH. Oun si lo n toju iya re to ti darugbo. Bee si ni won pa omo ileewe kan, to wo aso sukuu sorun."
"Awon mefa lo ti ku, nitori mo gbo tawon kan ninu won n so pe, o di merin si meji bayii. Sugbon, a o mo igun omo-isota ti won n ba ja titi dasiko yi."
Nigba to n soro lori isele naa, alukoro ileese olopaa ipinle Oyo, Ogbeni Adekunle Ajisebutu fidii isele naa mule. Sugbon, o ni enikan soso lo ku nibe.
Ajisebutu ni, "Enikan soso lo ku. Komisanna si ti pase pe ki awon olopaa maa wa laduugbo naa ni tosan-toru lati le daabo bo emi ati dukia awon eeyan nibe. Owo ti te awon eeyan kan pelu. 
Lasiko taa n ko iroyin yi jo, alaafia pada sibe, bee si nileese olopaa ti so poun o nii foju rere wo enikeni to ba n da omi alaafia ilu ru".

Sunday 21 February 2016

Ojo kerin osu keta ni OLUBADAN tuntun yoo gb'ade.
Olubadan ile Ibadan tuntun, Agba Oye Saliu Adetunji ti fidii re mule pe, ojo kerin osu to n bo yii ni ayeye igbade re yoo waye. Lasiko to n gbalejo gbajumo olorin juju nni, Oloye Ebenezer Obey Fabiyi laafin re ni Popoyemoja ni Adetunji soo di mimo pe, leyin okan-o-jokan ifikun-lukun pelu awon ti oro gberu ni won mu ojo naa.
gege bo se so, lara awon idi ti igbade ohun ko fi waye saaju asiko yii ni lati se eye to ye fun Olubadan ana, Oba Odulana Odugade. Eyi to wa sopin lose to koja yii. O ni "ni tooto, awon igbimo Olubadan ko so nikan, sugbon won gbodo fi oruko Olubadan tuntun sowo si gomina ipinle Oyo, Olola julo Abiola Ajimobi fun ibuwolu.
"Ni kete tee ba si ti koja iyen, ki won fun un yin lojo lo ku. Nitori naa, ojo Jimoh, ojo kerin osu keta ni ayeye igbade naa yoo waye ni Oja'Ba, nibi tawon Olubadan isaaju opa-ase. Sugbon, ojo satide, ojo karun-un ni aweje wemu yoo waye nibi kan ti won ko tii kede.."
Foto : Oludije sile igbimo asoju-sofin lekun idibo Ibadan South West ati North West ninu idibo to koja labe asia egbe oselu Accord, Oloye Adegboyega Taofeek Adegoke lasiko abewo to se si Olubadan tuntun laafin re ni Popoyemoja lojo sannde.

Thursday 18 February 2016

Taa l'oba orin ninu awon eeyan yii? Wasiu Ayinde, Adewale Ayuba, Remi Aluko, Sule Malaika, Obesere ati Osupa


Wednesday 17 February 2016


N'Ibadan, ELEHA bimo marun-un leekekan naa.
- O n beere fun iranlowo omo Nigeria.
Yanju Adegboyega
Titi dasiko tee n ka iroyin yii, nise loro obinrin Eleha kan, Sakirat Rasaq si n se gbogbo eni to gboo ni ha hin, pelu bo se bi omo marun-un leekan soso. Koda, opo awon eeyan to gbo soro ohun, sugbon ti won o gbagbo lo n sare lo sileewosan ekose isegun UCH to wa niluu Ibadan nibi ti ise iyanu nla naa ti sele. 
 Akoroyin wa gbo pe, baba awon omo marun-un ohun, Alfa Yusuf Ewenje, eni odun mejilelogbon lo je afaa akomonikeu. Nigba ti iya awon omo ohun Sakirat, eni odun mejidinlogbon je iyawo ile. Gege bo se wi, Ewenje ni awon mo pe marun-un l'omo to wa ninu iyawo oun lasiko ti won lo ya foto inu re nigba to oyun naa wa ni osu meta.
O ni : “Aworan inu re taa ya nileewosan Adeoyo lo ti koko fi han pe omo marun-un lo wa ninu re. Nibe si ni won ti so fun wa pe, o nilo lati sinmi daadaa lori ibusun. Lati ojo naa ni won ti n toju re titi di ana (Ojo monde), nigba taa wa sibi lati gbebi re. “Bi mo se wa yii, ko si nnkan kan lowo mi, nitori pe keu ti mo n ko awon omo ni mo fi n ri owo mu lo senu. Mo fe kawon eleyinju aanu omo orileede yii lati dakun wa saanu mi. Mo n lo asiko yii lati ke si Gomina Abiola Ajimobi, iyawo won, Arabinrin Florence, minisita fun eto ilera, Ojogbon  Isaac Adewole atijoba apapo orileede yii lati dakun dide iranlowo si mi. Ayo tiwon naa ko nii dibanuje.
Iya ibarun-un naa, Sakirat lasiko ton bakoroyin wa soro sapejuwe ara re gege bi eni to soriire pupo. Bo tie je pe, ko gba ki enikeni ya foto oju re, nitori igbagbo esin re ti ko faaye ko si oju sile fun un. Sibe, leyin to ti gba ase lowo oko atiyawo re, alukoro ile-ekose isegun UCH, Ogbeni  Deji Bobade pada ya foto re, eyi ti akoroyin wa ri gba lori ikanni ayelujara facebook re.
Bobade soo di mimo pe, alaafia ni iya atawon omo re ohun wa, sugbon o salaye pe "won nilo iranlowo owo gan ni.”
Taa ba renikeni to nifee lati ran iya olomo yii lowo, nomba akanti banki re ni: RASAQ BABATUNDE YUSUF
GTBANK
0131404208



Tuesday 16 February 2016

N'Ibadan, Eleha bi omo marun-un leekan naa.

N'Ibadan, Eleha bi omo marun-un leekan naa.
- O n beere fun iranlowo lodo ijoba
Omobinrin Eleha kan, Sakirat Rasaq, eni odun mejidinlogbon to je iyawo ile. Ti oko re, Afaa Yusuf Rasaq to n komo ni keu lo bi omo marun-un leekan naa sileewosan ekose isegun, UCH niluu Ibadan lonii.
Iroyin to kan wa ni po nile iranlowo. Tee ba ni ohunkohun lati se fun un, e kan sawon alase ileewosan UCH.

OLUBADAN tuntun soro; o ni nise lawon SERIKI n japoro.

Olubadan tuntun, Agba Oye Saliu Adetunji ba ALARIYA OODUA soro
Won maa n pa owe kan niluu Ibadan, won a ni "Oro oye Ibadan ko ni eja tabi akan ninu. Titi aye, akan ni yoo maa se". Eyi lo d'Ifa fun jije oye Olubadan ile Ibadan. Laipe yii ni awuyewuye kan sele leyin ti Olubadan ile Ibadan, Oba Samuel Osundiran Odulana Odugade kin-in-ni teri gb'aso nibi ti Oloye kan lati igun Seriki, Oloye Oyediji ni oun nipo naa to si. Bee, Oloye Saliu Adetunji to je Balogun ile Ibadan lawon igbimo Olubadan ni won fe nipo naa.
Akoroyin wa, YANJU ADEGBOYEGA ni gbolohun pelu Olubadan to n bo nipo naa laipe yii. E maa ba wa kalo...
Ibeere : - Kee to debi tee de lonii, tee ba boju weyin, yoo to odun meloo tee ti ro'le?
Idahun : - Bi ogoji odun l le die ni.
Ibeere : - Oju opo n ko?
Idahun : - Ti Balogun ni mo wa.
Odo baba wa, Olubadan Adebimpe ni Odinjo si ni mo ti bere oye jije.
Ibeere : - Taa ba wo asiko naa si isin-in, opo ipenija ni yoo wa. Nje a le gbo die nipa awon ipenija yii, ka fi kogbon?
Idahun : - Se e ri teeyan ba ti gba ona kan wole, ko si wahala. Sugbon, awon ohun to sele laarin igba yen, ti enikan mo on mo rii pe won gbe mi kuro nibi to ti ye ki n ti lo odun meta, lati le da mi pada seyin. Awon omo to je looya ni ki n je kawon o pe ejo. Mo ni mi o p'ejo. Mo ti gbaa ni kadara mi.
Nigba ti mo lo, ohun ti mo ti se sile, ti mi o pari. Gbogbo awon ti won n gbe lo sibe ko rii se, emi ni Olorun pada fun se. Ijoba ibile Ona-Ara ni. Lojo naa, ti oun si wa ni Mapo, o ye ki won fun mi ni Ariwa Ibadan. Ko je ki won o fun mi, o lo agbara re. Sugbon, Olorun ti sedajo tie naa.
Ibeere : - Eyin agba maa n so pe, mo koo a maa ni apeere. Popoyemoja nile yin, ibo ni oko yin nijoba ibile wo?
Idahun : - Onipepeye loruko aba wa. Ijoba ibile Oluyole lo bo si.
Ibeere : - Nigba ti Kabiyesi to waja wa laye, won sakitiyan lori oro aafin tuntun. Sugbon, ko tii niyanju titi olojo fi de. Igbese wo l'eyin fe gbe lati rii pe ise pari lori re loju ojo?
Idahun : - E seun. Oluwa yoo ran wa se. Nigba temi ati gomina n soro, a soro debe. Mo si mo pe pelu ogo Olorun, ti mo ba de ori apere, a o tun jo soo. Olorun yoo si ba wa see.
Ibeere : - Iyen okan. Awon afojusun nnkan daadaa wo le tun ni fun ilu Ibadan lasiko yin?
Idahun : - Ki Olorun fori ji baba wa Olubadan to gbe'se, gbogbo ohun ti won ba n fe naa la jo maa n so. Ohun kan to si mumu laya gbogbo wa, taa n be Olorun si ni ipinle Ibadan. A si ti kuro nigboro Ibadan nitori re ri, taa lo siluu Abuja. Agbejoro Akinjide lo lewaju wa lo nigba naa.
A o mo pe, eni to wa nibe lasiko naa ko nii see. Tee ba wo ilu Ibadan, e o rii pe kii se ilu mo. O ti di aye, awon ilu to dabi pe won ti wa lominira ara won. Won o to wa.
Sugbon, Olorun ma jee ka ri ogun abinu eni. A o mo nnkan taa se fun onitohun, nitori taa mo pe awon eeyan kan lo wa nidii re. Debi pe, Alaaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi gan fi enu sii pe ki won fun wa nipinle Ibadan.
T'eyin naa ba wo Ibadan lonii, e o rii pe o koja ohun teeyan n pe niluu.
Ibeere : - Taa ba ni ka woo. Ki Olorun ba wa te Olubadan ana safefe rere, ajosepo wo lo wa laarin yin nigba aye won?
Idahun : - Ajosepo to po ni. Nitori pe, baba mo pe emi nibi keta si won. Eni to si je oga temi, to je Balogun nigba naa, Agba Oye Sulaimon Omiyale, ti baba ba jokoo, awon a jokoo tele won. Emi naa yoo jokoo. A o jo wa maa so ohun taa n fe fun Ibadan.
A dupe lowo Olorun pe lonii, emi ni mo wa nipo Balogun. Ipo Balogun ti mo si wa ohun, awon eeyan ti n pe mi ni Olubadan lai tii gba opa-ase. Adura mi ni pe ki n le gba opa-ase. Ko si soju eyin naa. Ti won ba si wa gbe ade le wa lori tan, Olorun je ka pe nibe.
Ibeere : - E ti so daadaa nipa Olubadan to gbe'se. Nje e le so die nipa iwa won?  Nje a ri ohun taa le fi se eko ninu iwa won?
Idahun : - Baba feran ilu Ibadan pupo. O si feran gbogbo awa taa je ijoye re, nitori pe t'oro kan ba wa. Ko too fesi lee, yoo koko beere lowo awa taa je ijoye re. Ohun taa ba si so pe ko se ni yoo se. Baba kii da nnkan se.
Ibeere : - Lenu asiko ti won lo je ipe Olorun yii, orisirisi ero lo ti wolu Ibadan. Lara won ni aare orileede yii tele, Oloye Olusegun Obasanjo. A si gbo pe, won sabewo sodo yin. Ohun taa gbo ninu iroyin ni pe ipade atilekun mori se le jo se. Ki lawon ohun tee jo so?
Idahun : - E seun. Omooya lemi ati Oloye Obasanjo. Oro omooya la si jo so. Eyi ti kii se ohun taa le so fun un yin rara.
Ibeere: - A o gboo to ba ya. Abi bawo ni?
Idahun : - Ti Olorun ba so pe, e o gboo. O see se kee gboo. Nitori pe, iya kan lo bi awa mejeeji, bi mo se so saaju. Nitori naa, oro aarin ara wa la so. A tun ti jo soro laaro yi lori foonu. A nifee ara wa pupo ni.
A jo maa n damoran gan-an ni, nigba to n sejoba. Mo si dupe lowo Olorun pe, odun mejo to lo nipo, ko si aburu, nitori, to maa n tele imoran. Nitori naa, mo dupe lodo Olorun.
Ibeere : - Ki le ri soro awon igun kan to n so pawon ni oye Olubadan to si?
Idahun : - Se e ri awon yen. Se e mo pe, elomi-in a maa ja watiwati lori idaamu to ba baa. Won o le ma ja watiwati, sugbon watiwati won ko de ibikan nitori pe, ko si ohun to n je oruko ti won n je yen mo.
Ibeere : - Oro se wa di pe, emi lo ye ki n bo sori apere baba mi. Ti won si ti n dana, ti won n se ti won n so?
Idahun : - Se e rii, ti won ba pa adie tabi eran. Yoo maa ja watiwati, o si le se bee fun bi iseju mewaa tabi ju bee lo. Iru re lo n sele yen. Ko si nnkan to n je Seriki mo.
Lasiko baba mi, egbon mi, Oloye Akinloye. Oun naa ja watiwati pe ki Seriki le wole si oju opo Olubadan. Omooya si lemi atie, mo si n so fun un nigba yen pe, egbon mi, e lo wole si igun to ba wu yin ninu Balogun tabi Otun. Igun seriki tee wa yi, ko sona nibe. Yoo ni se mi o mo pe looya loun ni. Maa ni, mo mo pe looya ni yin.
Nigba tee lo siluu siluu oyinbo lodun 1944 lo ko'se looya. Nigba tee de, sebi e ba wa nibi taa n se ilu lo ni. Tee wa ki wa pe e ti de o.
Mo ni tee ba je looya, ko le ju ti Rotimi Williams lo. Nitori naa, e ma fokan sii. Ko le bo sii.
Yoo ni aburo mi, Akanmu yoo bo sii. Maa ni egbon mi, e wa nnkan mi-in so. 
Nitori naa, igun meji, yala Balogun tabi Otun nii je Olubadan. Oro eeyan je looya ko lo wa nile yi, asa ati ise ile Ibadan ni.
Ibeere : - Se ohun tee n so bayii ni pe, e o ri iwe ipejo kankan?
Idahun : - Won pe ejo. Sebi akowe wa la ran lo.
Ibeere : - Se e si ro pe, iyen ko le da nnkan sile?
Idahun : - Sebi ile-ejo ti so fun won pe, ko soro nibe.
Ibeere : - Sugbon, eni yi so pe, o niye owo toun na lori oro yi. Eyin naa le si kuku wa ninu igbimo Olubadan. Se ooto ni po gb'owo ranse?
Idahun : - Eni ti won ba gb'owo ranse si, e ni kawon funra won o soo. Ki won so bi eni naa gbaa lowo won ati eni ti won fi ran.
Lenu igba to gbo pe, emi ni mo fe joba yii, won ti wa ba mi. Ti mo si so fun won pe ki won o m'enu kuro nibe.
Ibeere : - Bo se je pe eya kaakiri agbaye lo wa niluu Ibadan yi, nje o see se ki enikan de ade pe oun ni oba awon eya oun niluu Ibadan?
Idahun : - Eni to ba je Yibo tabi Hausa ko le de ade kankan niluu Ibadan. Eni to ba fe de ade ko lo to fun un niluu re. To ba si ti dee, to ba ti fe wo ilu Ibadan yoo gbe nnkan re pamo ni.
Ibeere : - Ohun to fa ibeere yi wa ni pe, gbogbo igba la maa n gbo oba kinni kan. Awa naa si dake, a o soro. Bee ni igbimo Olubadan ko wi nnkan kan?
Idahun : - Se e rii, tee ba gbo pe eeyan je nnkan kan niluu Ibadan. Nitori, Olubadan funra re fowo sii ni. Sugbon, pe Olubadan lowo sii ko fun won loore-ofe ati de ade. Olori eya won lo fi won je.
Ibeere : - Lenu igba ti Olubadan gbe'se, nje eyin atawon oloye to ku si n rira?
Idahun : - A n rira. Koda, won wa nibi lanaa. A jo lo sepade pataki kan, nibi ti won ti wa f'owo sii pe ki n je Olubadan. Won ti se iwe ti gbogbo won buwo lu, won ti fi ranse si gomina atawon afobaje pe ki won o maa mura sile. Won ti yan eni bayii ni Olubadan, eni naa si ni Saliu Adetunji.

Ede YORUBA nikan la o maa so laafin Ibadan - ADETUNJI, Olubadan tuntun. E kaa siwaju

Yoruba nikan l'ede l'aafin bayii - Adetunji
Yanju Adegboyega
Balogun ile Ibadan, eni tireti wa pe yoo bo sipo Olubadan, Agba-Oye Saliu Adetunji ti soo di mimo bayii pe ede Yoruba nikan ni won yoo maa so ninu aafin lati asiko yi lo. O salaye pe, gege bi isedale ati asa, awon oba nigbagbo wa po ni gbogbo ohun isura iran won lowo, eyi to ni idi naa to fi ye ki won maa gbe asa ati ise won laruge niyen.
Adetunji, eni to soo di mimo pe ile lati n ko eso rode ni ko si ohun to buru to ba je ile Ibadan ni yoo siwaju ninu igbelaruge ede Yoruba. Nitori to kuku wa lakosile pe, Ibadan naa ni gbogbo ohun akoko daadaa ti sele lorileede yii.
Ko sai wa mu un da gbogbo awon eeyan to n wa kii ku oriire loju pe, okan pataki lara ise ti oun yoo mu se ni ona lati rii pe ipinle Ibadan je dida sile laipe. Nigba to n te siwaju ninu oro, Adetunji soo di mimo pe awon eeyan bii Balogun ile Ibadan tele, Agba-Oye Sulaimon Omiyale ati baba isale awon oloselu ipinle Oyo tele, Oloye Lamidi Adedibu pelu awon agbaagba Ibadan kan lo n yo oun lenu lati wa je Mogaji agboole oun. Eyi ti oun si wa n gun akaso naa diedie ati pe metalelogun ni akaso ti oun gun de aaye ti oun wa ohun bayii. 
O ni, odun 1976 ni oro idasile ipinle Ibadan ti bere. Opo igbese ati akitiyan lo si ti waye lati rii po bo sii. 
Adetunjji, eni to wo aso agbada leesi olowo nla kan ni ise rekoodu olorin toun n gbe jade n lo deedee niluu Eko atawon ibomi-in ti eka re wa. O wa ni, eni to ba ko gbogbo ile aye re le Olorun lowo nikan lo le se irufe awon aseyori ti oun ti se laarin odun 1976 ti oun di Mogaji si asiko yi. 
"Idasile ipinle Ibadan lohun to koko je mi logun bayii, a ti lo siluu Abuja bi eemeta. Eni to si wa nibe tele seleri fun wa, a o si maa tera mo on ni. Mo si nigbagbo pe yoo see se lasiko temi." 
"Inu mi yoo dun, nigba ti won ba da ipinle Ibadan sile fun wa. Eyi ti yoo mu idagbasoke ba ile Ibadan lapapo"
"Mo dupe lowo Olorun, Olorun nikan nii gbe eeyan depo Olubadan, nitori kii se gbogbo eni to gun awon akaso yen naa lo n de ipo Olubadan. Awon eeyan bi Oloogbe Omiyale ati Adedibu lo n yo mi lenu lati wa ro'le." 
Lara awon to ti wa ki Olubadan to kan naa ni omo igbimo agbaagba ile Ibadan ti Ambasado Olusola Saanu lewaju won. Awon omo egbe Oluyole Club niluu Eko, eyi ti Giiwa ile-eko giga yunifasiti Obafemi Awolowo tele, Ojogbon Niyi Osuntokun lewaju won. Baale Kunmi Omikunle ko awon Onisese Osemeji leyin wa, nigba ti awon olori ebi Oyakojo ko awon egbe alagbo-eleweomo to wa l'oja Bode wa sibe.
Alaaji Rasheed Ayinde Merenge lo siwaju awon oloye egbe olorin fuji, FUMAN wa lati se "ago l'aafin". Lara awon to wa nibe ni aare egbe, Alaaji Moroof Shado; akowe, Alaaji Gani Composer; Kolotiti; Alaaji Taofeek Omoowo pelu alaga egbe nile Ibadan, Santora

Polowo oja re lori ikanni GBELEGBO, akoko iroyin Yoruba lori ero ayelujara.

Won sinku OLUBADAN ODUGADE, gbogbo eeyan n so pe eni rere lo. Sugbon, awon ka ni eewo ni. Won kii te oku oba sita gba-n-gba.

Won sinku Olubadan ODUGADE, gbogbo eeyan lo n so peni rere lo.
- Sugbon, awon kan ni eewo ni. Won kii te oku oba sita gba-n-gba nile Yoruba.
Yanju Adegboyega
Ojo Jimoh ose to koja, ojo kejila osu yii ni won fi ara Olubadan ile Ibadan, Oba Samuel Osundiran Odulana Odugade kin-in-ni fun ile leyin isin idagbere to waye fun un ninu ijo Peteru mimo, Aremo niluu Ibadan. Eyi to pari ayeye isinku olojo mesan-an tijoba ipinle Oyo gbe kale lati bu ola fun oba alaye naa.
Sugbon bi eto isinku ohun ti dun to, larinrin to, opo awon eeyan lo ti n bu enu-ate lu bi won se n gbe oku re kiri. Ti won si tun n tee sile lawon ibi kookan fun odidi ose kan naa. Ileewe girama Igbo Elerin nijoba ibile Lagelu ni won ti koko te oba alaye naa nite-eye fawon araalu lati maa woo lojo monde ose to lo. Leyin naa ni won tun tee sinu agboole baba re, Ladunni laduugbo Oja'Gbo nirole ojo naa.
Lojo wesidee ojo kewaa osu yii ni won tun tee sile fawon araalu lati dagbere fun un ni gbongan nla Mapo. Ti won si tun tee sinu ile awon loba-loba to wa nile igbimo asofin ipinle Oyo lojo tosidee ose kan naa.
Eyi si lawon eeyan to mo nipa asa ati ise Yoruba si n toka si gege bi eyi ti ko ba oju mu rara. Enikan to je agba awo nile Ibadan, Baba Awo Olalekan Atikiriji salaye pe, ko ba ilana isedale ile Yoruba mu lati maa te oku oba alaye sita gba-n-gba fawon eeyan lati maa wo, nitori eni-owo ni won.
"Kii se nnkan to bojumu rara nile Yoruba lati maa te oku oba sita fawon eeyan lati maa wo, nitori eni-owo ni won.
Bo tie je po salaye pe, kii se pe iwa ohun ni aburu kankan to le se fun ilu. Sugbon, o ni sibe nise lo ye ki won pa oku naa mo. Eyi ti won fi n gbee kiri yii. Nigba to n soro lori isele naa, Otun Olubadan ile Ibadan, Agba Oye
Lekan Balogun sapejuwe tite ti won n te Olubadan nite-eye naa gege bi ona lati fun awon omo bibi ati olugbe ilu Ibadan loore-ofe "lati fife won si eni to ti je olori won han si gbogbo aye.”
“Erongba to wa leyin tite ti won te Olubadan nitee-eye ni lati fawon araalu to ti se olori le lori lanfaani ati fife ti won ni sii han gbogbo aye. Eni to kopa to po ni Oba Odulana, kii sii se ile Ibadan tabi ipinle Oyo nikan. Bi ko se ni gbogbo orileede Nigeria lapapo. Lati moriri ipa to ti ko ninu amuludun ati igbaye gbadun awon eeyan re lo je ki won te oku re ni Igbo-Elerin ati ni agboole baba re ni Aremo, Oja’gbo.
O ni “eto yi ni won se fun awon eeyan to ti se olori fun lat'igba yi wa loore-ofe ati kii po digboose. Ko to di pe won yoo sin oku re. Eto yi si ba ode-oni mu fun okunrin naa tigbagbo wa pawon eeyan re feran, ki won le bu ola fun un.”
Sugbon, ni asa ati ise ile Yoruba, eewo ni lati te oku oba alaye sile fawon eeyan lati maa pe wo.
Ojo tosidee, ojo kerinla osu kerin odun 1914 ni won bi Oba (Omowe) Samuel Osundiran Odulana Odugade kin-in-ni sinu idile Alagba Odulana Ayinla ni Igbo Elerin, ijoba ibile Lagelu.
Ohun kan to mu kawon omo Ibadan yato ni pe, yato si agboole won nigboro. Won tun gbodo ni oko lawon ilu to wa labe Ibadan. Nitori naa, yato si aba Fadina ni Igbo Elerin, Oba Odulana tun je omo agboole Ladunni laduugbo Oja'Gbo nigboro Ibadan.
Se omo ti yoo ba je Asamu, kekere ni yoo ti maa j'enu samusamu. Lati kekere ni Samuel ti bere sii fi amin asiwaju han, nigba to di odun 1922 nigba to je eni akoko ti yoo lo sileewe ninu molebi re.
Ileewe alakoobere Saint Andrews, Bamigbola lo ti bere iwe kika re. Leyin naa lo wa sigboro Ibadan, ileewe St Peters, Aremo lo si ti pari eko re lodun 1936. Nitori tawon ileewe girama sowon die nigba naa, o foruko sile fun ile-eko gbele (Correspondence College) lati safikun eko ati imo re.
Leyin to kuro nile-eko, o sise fungba die nileese UAC gege bi akowe ire-oko, ko to gba ise olukoni nileewe CMS, Jago nijoba ibile Ona-Ara asiko yi laarin odun 1938 si 1942.
Nitori ife to ni sile baba re, Oba Odugade lo darapo mo omo-ogun Iwo Oorun ile Africa (West African Volunteers Force) lati doju ija ko oga ogun ile Jamani, Adolf Hitler lasiko ogun agbaye eleekeji. Leyin ti ogun ohun pari lodun 1945, oun lo wa nidii idanilekoo fawon abode ogun niluu Eko to je olu-ilu orileede yii tele. O sise re ohun daadaa to bee ti won fun un ni ami-eye, eyi to mu kileese eto eko ijoba oyinbo fun un nise lodun 1946.
Ise re tuntun yii lo si fun un loore-ofe lati sunmo awon omowe asiko naa. Lara won si ni okunrin oludasile opo ile-eko, Oloye T.L Oyesina, eto to da ileewe girama Ibadan Boys High School sile atawon eeyan nla-nla asiko naa.
Odun 1959 lo feyinti lenu ise oba lati lo sin awon eeyan re nigba to dije dibo wole sile igbimo asofin to keyin saaju ominira orileede yii lodun naa. Asiko yii gan ni Olootu ijoba orileede yii, Alaaji Abubakar Tafawa Balewa yan an gege bi akowe ile igbimo asofin re. Ipo yii lo si mu ko wa nibi ipade nla awon orileede to n se asepo oro-aje (Commonwealth Conference) niluu London lodun 1963. Lodun yii kan naa lo di minisita keji fun oro osise. Bee si lo ti figba kan tabi omi-in sise okan-o-jokan fun orileede yii, eyi to mu kijoba Oloogbe Aare Musa Yar Adua fun un ni ami idanilola orileede yii, CFR. Bee si lo gba ami idanilola omowe ti ile-eko yunifasiti ekose imo-ero ilu Akure, ipinle Ondo lodun 2005.
Odun 1972 lo je Mogaji agboole won, to si to titi to fi je Olubadan ogoji lojo Jimoh, ojo ketadinlogun osu kejo odun 2007.
Ki Olorun tee safefe rere

Agogo Ogbon

Agogo Ogbon!!!
Oko-eru eleekeji
Mo ro oro ohun, omi le roro loju mi.
Nigba ti maa fi lanu lati soro, poroporo l'omi n da sile loju mi. Gbogbo takada ti mo si n ko apileko yii si lo tutu jigbinni.

Bi ipolongo ominira l'oro ohun bere.

Agbekale iro ohun daa pupo, to bee ta o sakiyesi.

Lati le di ilumo-on ka, won so fun wa pe oro ibi ko ju'bi laarin okunrin ati obinrin ni.

Nigba naa, won waasu fun wa pe, oro eto omoniyan ati eto awon omode lawon n gbe kiri.

Lati fa oju awon obinrin mora, won sapamo sabe irolagbara awon obinrin.

Awa kan n ri gbogbo re, gege bi ara ilaju.

Nitori eyi, a kan saara si won. A si fi iwa omugo korin rere ki won.

Won ti di wa loju to bee, ta o sakiyesi igba ti won gbe oro ibi ko ju'bi sile. Ti won si f'oro ojuse eni gbigba se ati siso "ohun to to" di "eyi ti ko to".

Won so fun wa pe, oro agboye laarin ara wa ni. Abi, ki lo buru ninu tiyawo re ba rise ju oko lo. Ko gba ipo olori ile, ki oko si maa gb'ase lowo re?

Won so fun wa pe, a l'ase lori eya-ara wa. A le see bo se wu wa.

Won so fun wa pe, ti okunrin ba le "lajosepo pelu obinrin to wuu, nigba to ba wuu". Bee lo ye ko ri fun obinrin naa.

Won seto "ife ofe ati ore pelu ere". Won si je ko ye wa pe, nise la n lo eto wa labe ofin lati gbadun eya-ara wa.

A si gba bee. Odo langba wo ni ko nii gba?

Nigba taa soro nipa awon "ARUN IBALOPO", won fi ora idaabo bo, kondoomu lo wa. Koda, won bere sii pin in fun wa lofee lawon ileewe girama wa.

Won so fun wa pe, lati omo odun merindinlogun lati ni eto lati se ohun to wu wa.

Eyi si je ka maa ri awon obi ati oluko wa bi aja inu iwe, ti ko le gbo debi ti yoo bu eeyan je. Nigba ti won o letoo lati ba wa wi mo.

A n soro nipa ominira to dun!

Nigba taa soro nipa oyun airotele laarin awon odomobinrin, won so fawon obi wa lati maa ko wa nipa ilana ifeto somo bibi lati kekere.

Won sagbekale ilana eko ibalopo tuntun lawon ileewe wa, gege bi ona lati tun fogbon pin kondoomu fun wa sii.

Opo ninu wa lo tun pada gbe oyun esin, bee la si n soro.

Nipa bee, won pinnu lati fi ofin gbe oyun sise lese. Gege bi ohun to tona.

Ona ati ran wa lowo naa ni o.

E o rii pe, ojo-ola wa je won logun gan ni. Bee si ni won fe rii daju pe a gbe ile aye wa ni kikun.

Oyun sise si jo nnkan gidi loju wa.

A gba lati maa se bee.

Abi, ki nidii taa fi maa bimo ta o fe tabi ta o nii le toju saye?

Okan wa da wa lebi lori iwa yii, nitori to jo ipaniyan.

Sugbon, won ni ka ma seyonu.

Gege bi alaye won, ohun taa n se ni pe ka gbe "ole-inu" ta o fe jade lasan, kii se pe a n pa omo.
Bee la tun gba si won lenu, a si moju kuro nibe.

Won tun ni ko ye ka maa beru orisa, esin, awon obi wa tabi awujo.

Leyin naa, won so fun wa pe, a ni ominira lati fi aye wa se ohun to wu wa. Niwon igba, ta o ba ti pa enikeni lara tabi te eto elomi-in loju.

Loju ese nibe, a o nibowo fun OLORUN mo.

O ya wa lara lati maa gba boolu, se faaji tabi ka maa wo awon fiimu ologbonrangandan lojo Jimoh ati Sannde.

A tun pinnu lati gbidanwo ibalopo ako s'ako ati abo s'abo. O si jo igbadun, bee ni won tun n se koriya fun wa.

Nigba taa so fun won pe, awujo tiwa koro oju siru iwa bee. Won fi ofin gbee lese, won si ni koda a le fe ara wa sile gan bii l'oko-l'aya.

A tun pinnu lati te siwaju nipa igbidanwo oogun oloro.
Won takoo loju gbogbo aye, sibe a n rii ra bo se wu wa.

Ju gbogbo re lo, omo kekere si ni wa. Ko si ohun ti awon agbofinro le se fun wa, won o le fiya je wa nitori ojo-ori wa.

A n wa eni awokose, bee ni won fun wa lawon gbajumo osere won to ti ko aimoye oko tabi iyawo. Gbajumo olorin ti oogun oloro ati ogogoro ti di baraku fun atawon gbajumo elere idaraya ti won se isekuse kiri pelu iyawo oniyawo tabi oko oloko.

Won so fun wa pe, awon ilumo-onka yii laluyo, bee si ni won l'ominira. Nitori naa, ka maa gbero lati da bii won.

Opolopo wa bere sii fon ara (pumping iron), fin ara wa (getting tattos). Bee si la n gun abere oogun oloro (injecting steroids), ka le jo agbalagba, ka si "laluyo" bi awon eni awokose wa.

A bere sii ri awon ti ko sagbere gege bi awon ope.

Lati le jo awon eni "awokose" wa, awa naa bere sii sare le gbogbo ohun to ba ti wa ninu iro.

Bee la n ya foto awon eni "awokose" wa taa gba po ti laluyo, to si tun joju ni gbese ninu awon iwe iroyin. Taa n lee mo inu ile wa.

A bere sii lo oogun to n din ora ku ninu ara, ka le ri bii won.

A sakiyesi pe, tipatipa ni won fi n wo aso sorun, a si bere sii ko ise won.

Nigba ti oju fe maa kun wa, won mu wa mo awon ile ijo won ati pati ale.

Won ni ka gbe omoluabi ti, ka sa ti jaye ori wa.

Koda, nigba ti won fipa bawon kan lara wa lopo, won ni ka panumo. Ka maa ba faaji wa lo.

Opo ninu wa ni oti amupara ti di baraku fun, sugbon won so fun wa pe ara ona lati so pe omo nla ni wa ni. Nitori naa, la ba mura sii.

Lasiko kan, a sakiyesi pe a ti di eru won lai mo.

A sakiyesi pe, a o nidii kankan lati wa laye month. Bee si ni aye gan ko nitumo kankan mo.

Nitori ati maa joju ni gbese, opo ninu wa lo ti ko arun buruku "anorexia nervosa".

Opo ninu wa to bara won ninu ajosepo oko atiyawo lo soro fun lati je olooto.

Opo lo si n bere sii ronu ati gba emi ara won.

Opo mi-in ni arun ibalopo.

Opo ninu wa lo nisoro to nii se pelu opolo.

Aimoye ni ko le tesiwaju ninu eko won mo nipase oyun airotele, oogun oloro ati oyun sise to yiwo.

Nikorita yii lati rii pe, ojo iwaju wa ti baje nisoju wa.

A bere sii wa taa lo ye ka di ebi oro ohun ru.

Leyin opolopo iwadii ti ko so eso rere kan, a gba pe a o tie kuku mo "taa ni won" gan.

Igba naa ni oju wa wale. A si ranti oro ti awon baba wa maa n so fun wa pe:
“Ominira to na ti po ju, oko-eru ni to farasin ni”.

A tun ranti igba tawon iya wa maa n so fun wa pe:
“Ominira ti ko ba ti si eni to n ye'ni lowo re wo. Ko yato si keeyan o wa ninu igbekun igbalode”.

Lasiko ohun, oro ohun ti bowo sori fun wa.

A ti ra iro ominira "won".

Boya, ko tii pe ju fun eyin.

A je pe, kee ma je ki iro ati itanje won o je yin o..

E ma je ki oro tutu ominira won o tan yin je.

Iro lasan ni gbogbo re!

A le fidii eyi mule nipa ipo ajosepo wa, oogun oloro lilo, oyun airotele, iwa jagidi jagan ati bee bee lo.

E sora. E dakun, kee si kilo fawon odo to ku, ki isele yii ma mu gbogbo iran yii l'eru.

Nitori to ba je looto la NIFEE OLORUN, gege baa se n so. O ye ka yago fun gbogbo ohun to KORIRA.......