Wednesday 29 June 2016

Ikanni-ayelujara ede Yoruba, akoko iru re.

E kaabo si GBELEBO, ikanni-ayelujara akoko lede Yoruba.
Nibi te o ti maa je igbadun awon okan-o-jokan iroyin amuludun ati orisirisi idanilekoo to le seni lanfaani.
- Oore-ofe wa fun un yin lati se ikede ati ipolowo oja yin lori ikanni yii lowo ti ko ga ju ara lo.
E le kan si wa lori 0808 948 4270.
Ipolowo oja ni agunmu owo. E ba wa dowo po, e o si rii pe rere ni Oluwa.
Olootu

Tuesday 28 June 2016

E pa ede Yoruba ni dandan lawon ileewe alakoobere ati girama - OLUBADAN




Foto ; Awon akekoo ohun pelu Olubadan ile Ibadan, Oba Saliu Adetunji, Aje Ogungunniso kin-in-ni.
E pa ede Yoruba ni dandan lawon ileewe alakoobere ati girama - OLUBADAN
Yanju Adegboyega
 Olubadan ile Ibadan, Oba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunniso kin-in-ni ti ke sawon gomina ile Yoruba lati pa kiko ati kika ede naa ni dandan lawon ileewe alakoobere ati girama. Oba Adetunji soro yi lasiko to n gbalejo awon akekoo omo ile America bii meedogun kan to n ko ede Yoruba (2016 Yoruba Group Study Abroad, YGPA) nile-eko giga yunifasiti Ibadan laafin re to wa Popoyemoja.
Oba alaye yi toka pe,igbese ohun pon dandan nile Yoruba lati le daabo bo ojo iwaju ede abinibi agbegbe ohun. Eyi to so pe 'o n fojoojumo ku', to si wa ni, o nilo igbese kanmo kia. Ki awon obi lo ko asa siso ati kiko awon omo won ni ede naa nigba gbogbo.
“Nise ni mo maa n fi gbogbo igba se mo lori bi ede wa, Yoruba se n ku lojoojumo, nipase ai lakasi awon obi kan to ko ede abinibi won sile. Ti won o si tun je kawon omo won soo pelu.”
Olubadan kedun pe awon obi ati ijoba ko se ohunkohun  “lati doola ede wa lona iparun” pelu afikun pe, “mo paa lase pe, ede taa gbodo maa so laafin ni Yoruba ati ko gbodo si ede mi-in ju Yoruba lo.”
Oba Adetunji wa gbawon obi ati alagbato nile Yoruba nimoran lati maa se koriya fawon omo won, lati maa so ati ko ede Yoruba, pelu afikun pe “eya yooeu ti ede re ba ti ku, oun funra re ti parun”.
Saaju lawon asiwaju iko ohun, Ojogbon Moses Mabayoje lati yunifasiti ile Florida ati Omidan Tolu Ibikunle lati eka eko ede Yoruba ni yunifasiti ile Ibadan salaye pe abewo iko naa si Oba Adetunji je lara eto fun awon akekoo naa lati ni imolara ede, eyi ti won nifee si ati lati fi ara ro ara pelu asa Yoruba.
Nigba ti won n lu Olubadan logo enu lori abewo won sii, awon eeyan naa be oba alaye ohun lati rawo ebe sawon ijoba leleka-jeka lati pese aaye kan nibi ti won yoo maa se  awon ohun to jo mo itan nipa Ibadan lojo si. Nibi tawon akekoo ede Yoruba yoo ti maa ni oore-ofe lati mo nipa ilu naa atawon akoni re to ti koja lo.

Idije boolu OBA SALIU ADETUNJI bere


Idije boolu Oba Saliu Adetunji bere.
Yanju Adegboyega
Gbogbo eto lo ti to bayii fun idije boolu alafesegba ti won fi sori Olubadan ile Ibadan, Oba Saliu Akanmu Adetunji, akoko iru re. Gege baa se gbo, awon omooba lokunrin ati lobinrin lo sagbekale idije ohun lati fi se awari awon ebun to farasin nidii boolu alafesegba nile yii.
Lasiko to n bakoroyin wa soro nibi iyikoto eto ohun to waye ni gbagede aafin Popoyemoja, Ibadan lojo sannde ose, ojo kerindinlogbon osu yi, alaga igbimo to sagbekale idije ohun, Omooba Ganiyu Adetunji soo di mimo pe, won sagbekale re lati fi sori ayeye ojoobi Oba Adetunji. Eyi ti yoo waye lojo kerindinlogbon osu kejo odun yii ati pe odoodun ni yoo maa waye.
Saaju ninu oro tie, Olubadan ile Ibadan, Oba Saliu Adetunji toka pe, ere idaraya le pese ise fawon odo lorileede yii, tawon ijoba ni eleka-jeka ba le se igbelaruge fun un.
Ojo keji osu kokanla ni idije naa yoo bere niluu Eko. Nigba ti gbogbo asekagba re yoo waye niluu Ibadan.
Ate Idije
Ipinle Eko
Satide 02-07-16         Ibi idije - Ansar-Ud-Deen High School, Onitire
1. Obinrin
Lakeside Ladies vs Royal Ladies - 8 . 00am
2. Okunrin
Alade FA vs Damilola Taylor - 10 . 00am
3. Obinrin
Phoenix Queen vs Ansar-Ud-Deen - 12 . 00noon
4. Okunrin
Lakeside FA vs Strong-Dove - 2 . 00pm
5. Okunrin
D. Ultimate FA vs Solution Boyz - 4 . 00pm
Sannde 03-07-16       Ibi idije - Ansar-Ud-Deen High School, Onitire
1. Okunrin
36 Lion FA vs Patrick Amajor FA - 10 . 00am
2. Okunrin
Tiki-Taka FA vs Rising Stars Academy - 12 . 00noon
3. Okunrin
Morietes FC vs IGI FC - 2 . 00pm
Monde 04-07-16   Ibi idije - Ansar-Ud-Deen High School, Onitire
1. Okunrin
Lakeside FC vs Island FC - 2 . 00pm
2. Okunrin
Oladunjoye FC vs Allahu Saty FC - 4 . 00pm
Fraide 08-07-16   Ibi idije - Ansar-Ud-Deen High School, Onitire
1. Okunrin
Golden Lion FC vs Favor Comrade FC - 2 . 00pm
2. Okunrin
Rising Stars FC vs Apapa-Iganmu Allstar - 4 . 00pm

Monday 27 June 2016

O tan! Oro oko-ere EDA ONILE-OLA fe da wahala sile ninu TAMPAN

Saturday 11 June 2016

E ba wa dupe, OLUBADAN pe ogorun-un ojo lori apere


Ogorun-un ojo ti ADETUNJI di OLUBADAN
Awon Yoruba ni, ojo lo n pe, ipade kii jinna. Oni yii lo pe ogorun-un ojo ti Olubadan ile Ibadan, Oba Saliu Akanmu Olasupo Adetunji, Aje Ogungunniso kin-in-ni gba opa-ase gege bi Olubadan kokanlelogoji.
Ta o ba gbagbe, ojo kerin osu keta odun yii ni Adetunji gba ade ni gbagede Mapo, Oja'Ba niluu Ibadan. Nibi tawon eeyan jankan-jankan kaakiri orileede agbaye ti peju pese. O wa lakosile pe, fun igba akoko lati nnkan bi ogoji odun seyin, ko feree si ibi ayeye kan ti Alaaafin Oyo ati Ooni ile Ife ti jokoo papo bee ri. Sugbon, lojo naa, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi keta ati Ooni Enitan Adeyeye Ogunwusi, Ojaja keji jokoo sojukan. Bee si lawon oba nla-nla kaakiri bii Sultan ti Sokoto, Emir Ilorin, Alake Egba, Oba ilu Eko atawon mi-in ko gbeyin nibe.
A wa n lo asiko yi lati dupe lowo ijoba ipinle Oyo labe idari Sineto Abiola Ajimobi atawon gomina ipinle gbogbo bi Ekiti, Osun, Ogun, Eko ati bee bee lo fun aduroti won. Bee la si gbaa ladura pe ki emi oba ko gun.
Igba odun, odun kan fun Adetunji Akanmu Olubadan. Kaaaaabieeeesi o

Kayeefi n'Ibadan, Won ri aworan obinrin to pon'mo lara ogiri ---Lawon kan ba n lo boo, won ni Yemoja ni.

Kayeefi n'Ibadan, Won ri aworan obinrin to pon'mo lara ogiri
---Lawon kan ba n lo boo, won ni Yemoja ni.
Yanju Adegboyega
NIse lawon eeyan n ro giirigi lo saduugbo Olomi niluu Ibadan lojo Jimoh ose to koja yii, nigba tiroyin kan gba igboro kan pe, won ri aworan obinrin kan to pon'mo seyin ninu ile kan nibe. Gege baa se gbo, ese ko gbero laddugbo ohun titi di ale ojo naa, nigba ti gbogbo eeyan to gbo n lakaka lati fun oju won lounje ati lati ri eemo naa funra won.
Ibi isele ohun, to wa ni ojule kejidinlogoji, Olorunkemi Zone 1, Olomi-Academy lawon eeyan si ti so di mecca lasiko taa n ko iroyin yi jo lowo. Gege baa se gbo, owo irole ojo tosidee ni omobinrin to ni yara kan ninu ile olojule mejo ati boisi kota merin naa, nibi toun gan ti n lo yara to kangun ninu boisi kota ohun ti sakiyesi aworan naa, sugbon to koko n paa mora. A gbo pe, nigba ti oro ohun ko yee mo lo pariwo sita pe kawon eeyan wa wo kayeefi to ri naa. Ti gbogbo eeyan si wa ba wo ohun to ri ohun.
Lasiko ti akoroyin wa debi isele ohun laaro ojo satide, omobinrin to ni yara naa to ko lati daruko re, ti ko si tun gba akoroyin wa laaye lati ya foto aworan naa lo salaye pe, asiko ti oun maa pe ero le aworan ohun lori ko tii ya. O soo di mimo pe, ohun si n gbero lati se awon etutu kan ati pe leyin naa loun yoo se ajodun nla kan fun aworan naa.
Awon eeyan meji kan ti akoroyin wa ba nibe lasiko abewo re ni awon okunrin meji kan ti okan mu tesubaa awon musulumi lowo, sugbon tawon mejeeji n fi ede fo bi awon omo ijo kerubu tabi Cele. Ninu oro ti won n so fun  omobinrin to ni yara ohun ti akoroyin wa gbo ni won ti so pe, iru aworan naa wa lodo molebire kan ri ati pe o se die ti won ti pase pe ki oun pelu jokoo ti oosa naa.
Sugbon, akiyesi akoroyin wa ni pe, omi ojo to n jo lati ara ogiri ile naa lo lapa lara ogiri yara ohun. Eyi to je ko dabi igba ti won ya nnkan sara ogiri naa.
Ju gbogbo re lo, akoroyin wa rii pawon eeyan kan ti n da awon nnkan ti enu n je bi iyo, osan ati omi pio wota jo sidii aworan ohun lati gbadura. Bo ba si se je, isele to ba tele eyi ni yoo so. Sugbon, titi dasiko ti akoroyin wa kuro nibe lawon eeyan si n wo lo sinu ile ohun ti gbogbo eeyan n pe ni ile Iya Indomie lati lo wo ohun iyanu ti awon kan pe ni Yemoja naa.
Foto : Eyi ni enu ona abawole sinu yara ti won ti ri aworan naa.