Tuesday 20 April 2021

Ope o! Ile-ise olopaa ti gbawon obirin meta ti won jig be n’Ibadan sile leyin ojo merin lahamo


 

Ope o! Ile-ise olopaa ti gbawon obirin meta ti won jig be n’Ibadan sile leyin ojo merin lahamo

(O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii)

Yanju Adegboyega

Leyin ojo kerin tawon ajinigbe pamo beere owo kan ti lo ji awon eeyan kan gbe ni abule Onipe, ilu kan to wa loju ona Ibadan si Ijebu Ode nijoba ibile Oluyole, ile-ise olopaa ipinle Oyo ti gbawon obinrin meta kan sile bayii, ti won si ti di ominira ara won.

Gege ba a se gbo, awon obinrin ohun ni won jabo lowo awon to ji won gbe ohun ninu igbo lojo jimoh ose to koja, iyen ojo kerindinlogun osu yii, nigba tawon osise olopaa ti oga tesan Idi Ayunre lo gba won sile ni deede aago mesan-an aaro, nitosi ile-ise eleja kan leba igbo kan lagbegbe Ogunmakin.

Awon eeyan toro ohun kan ni Abileko Theresa Okeowo, Abileko Abosede Adebayo ati Abileko Bola Ogunrinde.

Akoroyin wa gbo pe, Abileko Okeowo yii, to je olukoni nile-eko girama kan nipinle Ogun ni obinrin soja kan, Abileko Ogunrinde fi moto gbe oun ati Abileko Adebayo, ti oun je dokita onisegun oyinbo to n toju eyin. Nibi ti won si ti n lo naa lawon to ji won gbe ohun ti ji won gbe lojo monde, ojo kejila osu yii.

Abileko Adebayo, iya olomo meji la gbo po si fun omo re kekere l’oyan lasiko ti won fi ji won gbe naa.

Iroyin kan ta a gbo so pe, nigba tawon olopaa ko je kawon ajinigbe ohun gbadun pelu bi won se n topa kiri inu igbo, won gba lati gba owo kan ta o mo iye to to. Leyin naa si ni won fi ona tawon eeyan naa fi le debit i won yoo ti ri won han won.

Enikan kan to bakoroyin soro ni, awon eeyan naa ko see ri rara, nigba ti won yoo fi ri won ninu igbo, bee si lo han loju won pea are ti mu won, nigba tawon olopaa yoo fi ri won.

Nigba to to n fidii iroyin ohun mule, alukoro ile-ise olopaa ipinle Oyo, Adewale Osifeso ni aseyori naa ko seyin akitiyan awon osise olopaa pelu bi won se tu gbogbo igbiyanju awon ajinigbe naa pale.

Osifeso ni “igbiyanju, ogbon atinuda ati lilo ise iwadii to jingiri, eyi ti komisanna olopaa, Ngozi Onadeko lewaju re lo mu eso rere yii wa.

Alukoro ile-ise olopaa yii toka pe, bi won ko se je kawon ajinigbe ohun rimu mi pelu bi won se n fi gbogbo igba lo kolu ibuba won ati bi won ko se yee topa won lo je ki won fawon eeyan naa sile.

O safikun oro re pe, won ti sayewo ilera awon obinrin yii, bee si ni won ti fa won lawon ebi won lowo pelu afikun pe ise si n lo lati rii powo te awon ajinigbe ohun.

 

No comments:

Post a Comment