Tuesday 20 April 2021

Onijekuje ni o, PDP Oyo kolu Muhydeen Bello


Onijekuje ni o, PDP Oyo kolu Muhydeen Bello

(O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii)

Yanju Adegboyega

Egbe oselu Peoples Democratic Party, PDP nipinle Oyo ti na’ka aleebu si okunrin oniwaasi nni, Sheikh Muhydeen Ajani Bello lori awon oro kan ti won lo so nipa isejoba egbe ohun nipinle naa labe akoso Onimo-ero Seyi Makinde, eyi ti won sapejuwe gege bi ohun ti ko ye ko maa jade lenu eni tawon eeyan n wo gege bi asiwaju esin gidi.

Egbe oselu PDP toka pe, oro ti Bello so ohun ni ko ye omoluabi, ko to ati po fi han gege bi onijekuje. Ninu atejade kan ti alukoro egbe naa nipinle Oyo, Onimo-ero Akeem Olatunji fi sita niluu Ibadan lojo tosde ose to koja. O ni, oro ti Bello so nipa isejoba Seyi Makinde fi han po ti gb’owo abetele lowo awon to gbe waasi ita gba-n-gba to ti soro ohun kale. Eyi to lo lodi si eko ti esin Islami fi ko iran omoniyan.

Bello la gbo po je oludanilekoo ati oniwaasi nibi eto waasi inu aawe tawon ololufe ati alatilyin gomina tele nipinle Oyo, Oloogbe Seneto Abiola Ajimobi gbe kale, akoko iru re leyin iku okunrin naa.

Sugbon, egbe oselu PDP ko je k’oro ti Bello so ohun tutu rara, ki won to ko o pada si i lenu. Alukoro egbe ohun, Akeem Olatunji ni ta a ba wo awon ise idagbasoke ti isejoba Gomina Seyi Makinde gunle atawon erongba amayederun gbogbo tawon eeyan ipinle Oyo n jegbadun re, a o rii daju pe ise ota eni kii pa odu oya ni Bello n je.

Olatunji lo je ohun to bani lokan je pe, Bello ti ko le soro lasiko ti gbogbo nnkan polukurumusu nipinle Oyo labe isakoso to koja, nigba tawon omo isota 1 million boys n soro. Tawon osise ijoba atawon osise-feyinti n ku lera won, nitori ti won ko ri owo-osu ati owo ifeyinti gba. Tawon agbase se kuna lati sise owo ti won gba tabi ki won sise ti ko dara to, nitori owo abetele tawon osise ijoba ti gba lowo won, saaju ki won to sise. Ti ko ri nnkan kan so si bijoba APC to kogba sile se n fooro emi awon ara-ilu nipase fi fi won sinu ise ati osi, pelu bi owo se wa nile fun ijoba to nigba naa. O ni ti Bello ba wa n soro lati fi ibi to fi si ninu oselu han lasiko yii, eyi to le sakoba fawon ara-ilu, ohun to bani lokan je gbaa ni.

Egbe oselu PDP ni bi ko se si ajakale arun COVID-19, ifehonu han EndSARS, wahala Fulani daran-daran atawon isoro eto aabo lasiko isejo APC to kogba sile to, sibe ijoba ohun si je awon osise lowo osu. Bee lo si tun je awon osise-feyinti to ti lo gbogbo igba ti won wa l’abarapa sin ipinle Oyo lowo. Sibe, isejoba APC to kogba sile ko ri tiwon ro lori ajemonu won.

Atejade ohun ni gbogbo awon isoro eto aabo taa ka sile yii, lo je abo ikuna ijoba apapo labe isejoba APC, yato si ti ajakale arun COVID-19 nikan, to je gbogbo agbaye lo ba finra. Egbe PDP wa ni, tisejoba APC ba foju wina die ninu ohun toju isejoba PDP labe Seyi Makinde n ri nipinle Oyo, o see se ki won ti ta ipinle naa ni gbanjo fun ile China nipase eyawo ti ko nii see san tan.

Egbe PDP ni okunrin oniwaasi yii ti te eto ti enikeni ti won ba pe ni oniwaasi ni loju mole, nitori ife owo to ni pelu bo se so waasi re di “owo ree, oja ree”, nilodi si iyinrere ife, alaafia ati ododo ti esin Islam ni ka maa tan kiri.

“Akiyesi wa ti lo sibi oro ibaje kan, oro ti ko fidii mule kan. Oro to tako iwa omoluabi kan ati eyi to fiwa ijekuje han ti won ni Sheikh Muhydeen Ajani Bello so nibi idanilekoo inu aawe Ramadan olodoodun niranti Abiola Ajimobi to waye lojo wesde, ojo kerinla osu kerin niluu Ibadan.

“A o ba ma tie ronu po ye ka fesi soro ohun, nitori ibowo fun osu alaponle Ramadan, sugbon a ro o po ye ka je ki gbogbo eeyan mo ki ni ooto to wa nidii waasi “owo ree, oja ree” naa, ka ma lo faaye sile fun okunrin oniwaasi yii lati f’ero ti ko ye sokan awon omo-iya wa ninu esin Islam.

“Lakoko, ta a ba wo ti osu alaponle Ramadan, nibi tawon musulumi kaakiri agbaye ti n gb’aawe won pelu irele okan, nise lo ye ki oniwaasi gidi maa tan iyinrere ife, alaafia ati ododo lona ati fun awon omo orile-ede Naijiria nireti, nipase ohun ti won ti foju wina labe ijoba apapo ti egbe oselu APC n sakooso re, eyi to mu kawon igun kan maa pe ipe fun ki won pin orile-ede yii.

“Nitori naa, awon eeyan rere ipinle Oyo, to ti n reti ki won gbo waasi to le ji okan won lenu okunrin oniwaasi yii ri ijakule to lagbara ninu re, nitori to je funra won ni won yan ijoba ti Sheikh Bello n gbiyanu lori asan lati bu enu-ate lu yii sipo, nitori tijoba APC ti su won. Eyi to je ki won pawopo le e nipo. Ta a ba si wa wo ipa tawon isele to n bani lokan je gbogbo to n se lorile-ede yii lonii ni lori awon omo Naijiria bii, tawon daran-daran atawon agbe ati tawon agbebon. Eyi fi han gba-n-gba pe Sheikh Muhydeen Bello ti kuna lati p’akiyesi ijoba apapo labe akoso Aare Muhammadu Buhari lati ji giri si ojuse re, eyi to fi fe maa fenu tembelu Gomina Seyi Makinde to n se daadaa fawon eeyan re.

“Looto, isejoba maa n te siwaju ni, bee si la o ni fe maa soro nipa eni to ti ku. Sibe, o ye ka le salaye awon nnkan kan fawon eeyan wa, lati le ko won lekoo, ki oye si ye won bi awon orile-ede agbaye mi-in se n dagba soke.

“Ijoba PDP to wa lode bayii, labe akoso Gomina Seyi Makinde nigbagbo ninu isejoba to duro deede, eyi lo si je ko maa sawon atunse to ye lori awon ise idagbasoke, tijoba to kogba sile kuna lati se bo se ye. Eyi ti ko ba fi pa won ti, ko si lo maa bere omi-in lati le gba oriyin ti ko nilaari nidii oselu, irufe eyi ti APC ko ba se.

“Ko le wa lakosile, gomina wa ti peregede, o si fi gbooro je’ka pelu bi gbogbo eeyan se nifee re kaakiri tibu-tooro ipinle Oyo. Eyi si farahan pelu bo se n rin yan fanda laarin awon odo to n fehonu han lasiko ipe fun fifagile iko olopaa SARS.

“Ni ti asesile, awon ise asesile to nilaari ati ipa rere wo lo n toka si tisejoba Ajimobi se nipinle yii pelu obitibiti gbese, lai si ise idagbasoke kan to see fi han?

“Bee si ni laarin igboro ilu Ibadan, to je olu ilu ipinle Oyo. Opo awon ibaje ati ise asepati nipase ai lafojusun isejoba ti oniwaasi n yin lo kunle, taa le foju ri.

“Idagbasoke wo lo wa n so nipa re, nigba tisejoba Ajimobi pa ona Moniya si Iseyin ti. To si je kawon agbe maa daamu, tawon ire-oko won si n baje?

Ju gbogbo re lo, isejoba APC labe Ajimobi gbe ise agbase to fori sanpon niye owo to to bilionu meji jade pelu owo oogun oju awon omo bibi ipinle Oyo.

“Ki nidagbasoke rere ohun to wa ninu ijoba to pa ile itaja Agbowo ti lati baje. O si n mura lati so o di tara re ni, ki Olorun to gbe GSM wole sipo?

“Ki ni ka ti so nipa oju-ona Akobo Oju-Irin ati afikun afara ti yoo mu ko rorun fawon eeyan to n rin ona naa. Pelu bawon eeyan to wa lagbegbe ohun se n foju wina to. Nje oniwaasi wa rin ona Iseyin wo, ko to maa so ohun to so. Ona Onipepeye/Alaska si papako ofurufu ti Ajimobi pati fun odun mejo n ko? Ise ti n lo nibe bayii, nipase Onimo-ero Seyi Makinde. Se oniwaasi le l’oun o ri atunse to ti bawon ikorita ni Challenge, ibudoko Iwo Road, Challenge ati Ojoo. Se oju re fo si ise akanse “E je kina wa”, igbese kin-in-ni ati ikeji. Atunse awon ile iwosan alaboode mokandinloodunrun ati ona to yato ti won fi n seto inawo owo ipinle ati owo to n wole labele?

“Ni bayii ti oniwaasi wa ti sadeede le soro lati sise owo to gba lowo awon to sagbateru waasi inu osu alaponle yii, a fe gba oniwaasi “owo ree, oja ree” naa nimoran lati p’ohun po pelu awon eeyan to n beere fun isejoba rere lodo ijoba apapo ti APC n dari, ko to di pawon to n pepe fun ki Naijiria pin yoo rona lo mo won lowo. Nitori ti Seyi Makinde ti n seto ijoba rere lo.

“Gege bi oniwaasi, to n lo “awa ati awon” lati maa sapejuwe APC ati PDP. Eyi ti fi han gbogbo aye, egbe oselu ti Sheikh Ajani Bello wa. Sugbon, isejoba PDP to wa lode nipinle Oyo bayii ko nii je ki enikeni mu un kuro nidii afojusun re. Ona yoowu ti enikeni si le fe gba lati mu ijakule ba, yala oselu ni tabi esin ni, ni ko ni wo ibe.

“Egbe oselu PDP nipinle Oyo wa n ki gbogbo awon omo-iya wa ninu esin Islam ku ajoyo osu oloore Ramadan, a si n ro gbogbo won lati ma wo tawon onibaje, sugbon ki won tele eko Ramadan nipa ki won je omo orile-ede rere to n pa ofin mo ati ololufe alabagbe won. Ki won si niberu Olorun pelu ba o se jo maa fowo sowopo pelu Gomina Seyi Makinde lati gbe ipinle Oyo gun oke agba.


 

No comments:

Post a Comment