Saturday 15 September 2018

Eedi re o! Eso alaabo ILAKA, oludije sile igbimo asofin yinbon paayan meta l'Oyoo



Eedi re o!
Eso alaabo ILAKA, oludije sile igbimo asofin yinbon paayan meta l’Oyoo
Yanju Adegboyega
Afi bi efun tabi eedi nisele ohun ri lojo sannde, ojo kesan-an osu yii niluu Oyo nigba ti okan ninu awon eso alaabo aladaani to n tele okunrin oludije sile igbimo asofin agba nipinle Oyo, Oloye Oyebisi Ilaka yinbon pa eeyan meta, tawon mi-in si wa nileewosan bayii. Gege baa se gbo, Ilaka lo lo sibi ayeye odun Oranmiyan, eyi ti Alaaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi keta maa n se lodoodun. Gege baa se gbo, ayeye odun Oranyan ohun lo lo nirowo rose pelu awon alejo kaakiri orileede yii ati leyin odi.
Sugbon, lasiko tie to ohun pari, ti okunrin oloselu yii fe maa lo. Awon omo isota lo dena dee lati gbowo lowo re, nibi ti won si ti n se hanran hanran niwaju re lati rii po fun swon lowo, la gbo pe okan ninu awon eso alaabo aladaani, bouncer to telee sadeede yinbon sawon eeyan ohun. A gbo pe, loju ese nibe lawon olopaa ti debi isele ohun, ti won si ti mu okunrin eso alaabo to yinbon naa leyin ti won ti gba ibon to wa lowo re.
Akoroyin wa gbo pe, loju ese nibe lawon meji ti ku. Sugbon, ti eniketa pada ku leyin ti won gbee dele iwosan. Enikan tisele aburu ohun soju re soo di mimo pe, opo awon to farapa yanna-yanna nibe lo ti wa nileewosan ekose isegun, UCH, Ibadan nibi ti won ti n gba itoju lowo.
Nigba to n soro lori isele aburu naa, alukoro ileese olopaa ipinle Oyo, Ogbeni Adekunle Ajisebutu fidii isele ohun mule pelu afikun p’owo tit e eni to yinbon naa ati okunrin oloselu to fun un nibon. O toka pe, ileese olopaa ipinle Oyo ko nii faaye gba kawon eeyan kan maa lero pe won ga ju ofin orileede yi lo.
Ajisebutu mu un wa siranti pe, oga gba olopaa lorileede yii ti pase pe, ki gbogbo awon eeyan to nibon nikawo won lo koo sile nileese olopaa to ba sun mo won. O si wa soo di mimo pe, ileese olopaa yoo fi enikeni towo ba te pelu ohun-ija oloro jofin. Akoroyin wa gbo pe, lasiko taa n ko iroyin yi jo, ogba ewon Agodi ni Ilaka ati eso alaabo ohun wa.

No comments:

Post a Comment