Ajo EFInA ati banki apapo fe ki ida
ogorin eeyan maa fowo pamo titi odun 2020
Yanju Adegboyega
Lona ati mu ki iye awon eeyan to n
fowo pamo sile ifowopamo lorileede yii to idaogorin titi odun 2020, lo mu ki ajo
kan to n ri si baa se n dawon eeyan lekoo lati maa kowo pamo ati ki won lore-ofe
sile ifowopamo, EFInA, banki apapo ile wa atawon eeyan to ni nnkan se nipa fifi
owo pamo se pe ipade idanilekoo kan pelu awon akoroyin lati wo bawon ileese
iroyin se le sise po lati dawon araalu lekoo.
Eto ohun to waye nileetura kan
laduugbo Victoria Island niluu Eko lawon ogunna gbongbo tii da’to lenu igbin
nidii oro aje ti kora jo papo. Gbogbo awon akosemose nidii oro aje to wa nibe
lo si gba pe, ai nigbagbo awon eeyan ninu awon ile ifowopamo wa lara ohun to n
mu ki won fa seyin lati kowo won pamo si
banki.
Nigba to n soro, Temitope Otumara to
je akosemose olubanisoro fun ajo EFInA ni
mi mu awon eeyan lati maa fowo pamo kii se lati je ki won kan maa kowo won pamo
si banki lasan, bi ko se pe igbese ohun ni yoo so bi oro aje awujo kan yoo se r’ese
mule. O soo di mimo pe, gbogbo wa la
gbodo sise papo lati rii pe erongba ohun jo.
Oga agba to wa fun baa se n gbe eto
eyawo sile nileese EFInA , Suzanne Adeoye salaye pe, ko si ajo naa to le da
sise yii. “Eyi lo si mu ki EFInA pinnu lati sise papo pelu awon ileese iroyin
lati le ma dawon araalu lekoo lori anfaani to wa ninu ka maa fowo pamo sawon
ile ifowopamo”.
Lara awon to tun gbe idanilekoo kale
nibe ni Nimi Akinkugbe, Editi Efiong , oga agba kan lati banki agba ile wa, Aisha
Isa- Olatinwo atawon mi-in gbogbo. Bee si lawon asoju awon ile ifowopamo atawon
akoroyin latawon ileese akoroyin bii Channels TV, Wazobia, Businessday,
EbonyLifeTv, CNBC, Naira-Metrics, Alariya Oodua atawon mi-in bee bee lo.
Aworan:
Abileko Nimi Akinkugbe, oludari eto Money
Matters with Nimi.
Ogbeni
Editi Effiong, alase ANAKLE
Foto alayapo: Aisha Isa Olatunwo,
Nimi akinkugbe, Temi Otumara, Folasade Agbejule.
Awon oludari eto: Nimi Akinkugbe,
Aisha Isa- Olatinwo , Lehle Balde, Adia Sowho; Ogbeni SEGUN Akerele; Alaga ajo
EFInA, Arese Ugwu; oludasile SmartMoneyAfrica, Ugo Dre Okechukwu; oludasile
NairaMetric ati Folasade Agbejule
No comments:
Post a Comment