Thursday 27 September 2018

Ajo EFInA ati banki apapo fe ki ida ogorin eeyan maa fowo pamo titi odun 2020






Ajo EFInA ati banki apapo fe ki ida ogorin eeyan maa fowo pamo titi odun 2020
Yanju Adegboyega
Lona ati mu ki iye awon eeyan to n fowo pamo sile ifowopamo lorileede yii to idaogorin titi odun 2020, lo mu ki ajo kan to n ri si baa se n dawon eeyan lekoo lati maa kowo pamo ati ki won lore-ofe sile ifowopamo, EFInA, banki apapo ile wa atawon eeyan to ni nnkan se nipa fifi owo pamo se pe ipade idanilekoo kan pelu awon akoroyin lati wo bawon ileese iroyin se le sise po lati dawon araalu lekoo.
Eto ohun to waye nileetura kan laduugbo Victoria Island niluu Eko lawon ogunna gbongbo tii da’to lenu igbin nidii oro aje ti kora jo papo. Gbogbo awon akosemose nidii oro aje to wa nibe lo si gba pe, ai nigbagbo awon eeyan ninu awon ile ifowopamo wa lara ohun to n mu ki won fa seyin  lati kowo won pamo si banki.
Nigba to n soro, Temitope Otumara to je akosemose  olubanisoro fun ajo EFInA ni mi mu awon eeyan lati maa fowo pamo kii se lati je ki won kan maa kowo won pamo si banki lasan, bi ko se pe igbese ohun ni yoo so bi oro aje awujo kan yoo se r’ese mule.  O soo di mimo pe, gbogbo wa la gbodo sise papo lati rii pe erongba ohun jo.
Oga agba to wa fun baa se n gbe eto eyawo sile nileese EFInA , Suzanne Adeoye salaye pe, ko si ajo naa to le da sise yii. “Eyi lo si mu ki EFInA pinnu lati sise papo pelu awon ileese iroyin lati le ma dawon araalu lekoo lori anfaani to wa ninu ka maa fowo pamo sawon ile ifowopamo”.
Lara awon to tun gbe idanilekoo kale nibe ni Nimi Akinkugbe, Editi Efiong , oga agba kan lati banki agba ile wa, Aisha Isa- Olatinwo atawon mi-in gbogbo. Bee si lawon asoju awon ile ifowopamo atawon akoroyin latawon ileese akoroyin bii Channels TV, Wazobia, Businessday, EbonyLifeTv, CNBC, Naira-Metrics, Alariya Oodua atawon mi-in bee bee lo.
Aworan:
 Abileko Nimi Akinkugbe, oludari eto Money Matters with Nimi. 
 Ogbeni  Editi Effiong, alase ANAKLE
Foto alayapo: Aisha Isa Olatunwo, Nimi akinkugbe, Temi Otumara, Folasade Agbejule. 
Awon oludari eto: Nimi Akinkugbe, Aisha Isa- Olatinwo , Lehle Balde, Adia Sowho; Ogbeni SEGUN Akerele; Alaga ajo EFInA, Arese Ugwu; oludasile SmartMoneyAfrica, Ugo Dre Okechukwu; oludasile NairaMetric ati Folasade Agbejule

Saturday 15 September 2018

Eedi re o! Eso alaabo ILAKA, oludije sile igbimo asofin yinbon paayan meta l'Oyoo



Eedi re o!
Eso alaabo ILAKA, oludije sile igbimo asofin yinbon paayan meta l’Oyoo
Yanju Adegboyega
Afi bi efun tabi eedi nisele ohun ri lojo sannde, ojo kesan-an osu yii niluu Oyo nigba ti okan ninu awon eso alaabo aladaani to n tele okunrin oludije sile igbimo asofin agba nipinle Oyo, Oloye Oyebisi Ilaka yinbon pa eeyan meta, tawon mi-in si wa nileewosan bayii. Gege baa se gbo, Ilaka lo lo sibi ayeye odun Oranmiyan, eyi ti Alaaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi keta maa n se lodoodun. Gege baa se gbo, ayeye odun Oranyan ohun lo lo nirowo rose pelu awon alejo kaakiri orileede yii ati leyin odi.
Sugbon, lasiko tie to ohun pari, ti okunrin oloselu yii fe maa lo. Awon omo isota lo dena dee lati gbowo lowo re, nibi ti won si ti n se hanran hanran niwaju re lati rii po fun swon lowo, la gbo pe okan ninu awon eso alaabo aladaani, bouncer to telee sadeede yinbon sawon eeyan ohun. A gbo pe, loju ese nibe lawon olopaa ti debi isele ohun, ti won si ti mu okunrin eso alaabo to yinbon naa leyin ti won ti gba ibon to wa lowo re.
Akoroyin wa gbo pe, loju ese nibe lawon meji ti ku. Sugbon, ti eniketa pada ku leyin ti won gbee dele iwosan. Enikan tisele aburu ohun soju re soo di mimo pe, opo awon to farapa yanna-yanna nibe lo ti wa nileewosan ekose isegun, UCH, Ibadan nibi ti won ti n gba itoju lowo.
Nigba to n soro lori isele aburu naa, alukoro ileese olopaa ipinle Oyo, Ogbeni Adekunle Ajisebutu fidii isele ohun mule pelu afikun p’owo tit e eni to yinbon naa ati okunrin oloselu to fun un nibon. O toka pe, ileese olopaa ipinle Oyo ko nii faaye gba kawon eeyan kan maa lero pe won ga ju ofin orileede yi lo.
Ajisebutu mu un wa siranti pe, oga gba olopaa lorileede yii ti pase pe, ki gbogbo awon eeyan to nibon nikawo won lo koo sile nileese olopaa to ba sun mo won. O si wa soo di mimo pe, ileese olopaa yoo fi enikeni towo ba te pelu ohun-ija oloro jofin. Akoroyin wa gbo pe, lasiko taa n ko iroyin yi jo, ogba ewon Agodi ni Ilaka ati eso alaabo ohun wa.