Monday 2 August 2021

N’Ibadan, awon toogi kolu Radio Nigeria




 

N’Ibadan, awon toogi kolu Radio Nigeria

-          Opolopo moto atawon irinse olowo iyebiye ni won baje

 (O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii)

Yanju Adegboyega

Awon omo-isota kan ti lo kolu ile-ise redio ijoba apapo, Radio Nigeria ti won tun n pen i Amuludun Fm to wa laduugbo Moniya niluu Ibadan losan-an ojo satide to koja yii. Gege bakoroyin wa se gbo, nise lawon toogi ohun ti won to mejila niye sadeede ya wonu ogba ile-ise redio naa.

Ko seni to tii le so ni pato, idi tawon omo-isota naa fi lo kolu ile-ise redio ohun titi dasiko ta a n ko iroyin yii jo.

Ile-ise redio Amuludun to wa laduugbo Moniya lo je eka ile-ise Radio ijoba apapo ni won da sile lati maa seto fawon eeyan ti ko gbo ede geesi ni nnkan bi odun mewaa le die seyin. Ede Yoruba nikan ni won fi maa n seto lori ile-ise redio ohun.

Enikan to bakoroyin wa soro ni, awon toogi to kolu ile-ise redio naa lo ko awon nnkan-ija oloro bii ada, aake atawon nnkan mi-in to le seeyan lese lowo.

Lara awon osise ile-ise redio ohun to bakoroyin wa soro salaye pawon toogi naa ba opo dukia atawon irinse towo re to opolopo milionu je nibe lasiko ikolu ohun.

Die lara awon dukia ti won baje ni windo awon ofiisi, awon ohun elo ofiisi, moto atawon nnkan mi-in bee bee lo. Osise ile-ise redio ohun kan to bakoroyin wa soro, sugbon to ni ka ma daruko oun ni nnkan olowo iyebiye nile-ise naa atawon osise re padanu.

Nigba to n fidii isele ikolu ohun mule, oga agba ile-ise redio naa, Ogbeni Niyi Dahunsi salaye pe, looto lawon omo-isota kan wa kolu ile-ise naa. Sugbon, o ni won ti ko awon osise eleto-aabo lo sibe lati le dena ikolu mi-in to tun le few aye.

O ni “Ooto ni. Awon osise olopaa, DSS atawon sifu difensi si ti wa nibe bayii lati pese eto-aabo to peye fun ile-ise atawon osise.

Ikolu ile-ise redio yii lo waye leyin bi ojo die tawon toogi kan naa lo kolu ile itaja igbalode Palms to wa laduugbo Ring Road niluu Ibadan kan naa. A gbo p’eeyan kan tile ku ninu ikolu ohun.

 

No comments:

Post a Comment