Monday 2 August 2021

N’Ibadan, awon toogi kolu Radio Nigeria




 

N’Ibadan, awon toogi kolu Radio Nigeria

-          Opolopo moto atawon irinse olowo iyebiye ni won baje

 (O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii)

Yanju Adegboyega

Awon omo-isota kan ti lo kolu ile-ise redio ijoba apapo, Radio Nigeria ti won tun n pen i Amuludun Fm to wa laduugbo Moniya niluu Ibadan losan-an ojo satide to koja yii. Gege bakoroyin wa se gbo, nise lawon toogi ohun ti won to mejila niye sadeede ya wonu ogba ile-ise redio naa.

Ko seni to tii le so ni pato, idi tawon omo-isota naa fi lo kolu ile-ise redio ohun titi dasiko ta a n ko iroyin yii jo.

Ile-ise redio Amuludun to wa laduugbo Moniya lo je eka ile-ise Radio ijoba apapo ni won da sile lati maa seto fawon eeyan ti ko gbo ede geesi ni nnkan bi odun mewaa le die seyin. Ede Yoruba nikan ni won fi maa n seto lori ile-ise redio ohun.

Enikan to bakoroyin wa soro ni, awon toogi to kolu ile-ise redio naa lo ko awon nnkan-ija oloro bii ada, aake atawon nnkan mi-in to le seeyan lese lowo.

Lara awon osise ile-ise redio ohun to bakoroyin wa soro salaye pawon toogi naa ba opo dukia atawon irinse towo re to opolopo milionu je nibe lasiko ikolu ohun.

Die lara awon dukia ti won baje ni windo awon ofiisi, awon ohun elo ofiisi, moto atawon nnkan mi-in bee bee lo. Osise ile-ise redio ohun kan to bakoroyin wa soro, sugbon to ni ka ma daruko oun ni nnkan olowo iyebiye nile-ise naa atawon osise re padanu.

Nigba to n fidii isele ikolu ohun mule, oga agba ile-ise redio naa, Ogbeni Niyi Dahunsi salaye pe, looto lawon omo-isota kan wa kolu ile-ise naa. Sugbon, o ni won ti ko awon osise eleto-aabo lo sibe lati le dena ikolu mi-in to tun le few aye.

O ni “Ooto ni. Awon osise olopaa, DSS atawon sifu difensi si ti wa nibe bayii lati pese eto-aabo to peye fun ile-ise atawon osise.

Ikolu ile-ise redio yii lo waye leyin bi ojo die tawon toogi kan naa lo kolu ile itaja igbalode Palms to wa laduugbo Ring Road niluu Ibadan kan naa. A gbo p’eeyan kan tile ku ninu ikolu ohun.

 

O tan! Won ni EFCC ti gbese le banki ile asofin ipinle Oyo, nitori iwa ijekuje -


 

O tan! Won ni EFCC ti gbese le banki ile asofin ipinle Oyo, nitori iwa ijekuje

-          Ni Ogundoyin ba tu gbogbo igbimo ile ka

-          Iro ni, ko si nnkan to jo bee – Olayanju, agbenuso ile

( ((O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii.)

Yanju Adegboyega

Alaga igbimo ile igbimo asofin ipinle Oyo to wa fun eto iroyin, Kazeem Olayanju ti pase pe, ki ajo to n gbogun ti iwa ibaje nidii owo nina, EFCC gbese kuro lori banki oludari to wa nidii oro owo ninu ile igbimo ohun ti won gbese le.

Lojo Wesde ose to koja yii ni Olayanju fi oro naa sita fun akoroyin niluu Ibadan. Se laipe yii niroyin gba igboro kan pe ajo EFCC ti gbese le banki oludari to wa nidii oro owo ninu ile igbimo ohun, Abileko B O Ogundipe.

Akoroyin wa gbo pe, gbigbe ti ajo EFCC gbese le banki obinrin ohun ni ko nii fun loore-ofe lati le gbowo jade nibe. Gege ba a se gbo, ajo EFCC se eyi, nitori ti obinrin naa ko lati je ipe ajo naa, nigba ti won kowe ranse pe e ni.

A gbo pe, ajo ohun ti koko kowe pawon osise ile igbimo naa kan lori owo ti won na lati rawon moto kan ti won lowo re to bilionu kan le niye.

Eyi si waye nipase iwe ehonu kan ti won ni okunrin agbejoro ilu Abuja kan, Tosin Ojaomo ko sowo si EFCC. A gbo pe, Ojaomo fesun kawon omo ile asofin naa pe, moto ti won ti lo ri, ti won si tun se ni won lo ra. O ni, moto aloku lawon moto ti won ta ni tuntun fawon omo ile igbimo asofin naa.

Akoroyin wa gbo lojo wesde ose to koja naa pe, ajo EFCC gbese le banki ohun lati le sise iwadii lori oro naa ni.

Nigba ti Olayanju fesi le oro ohun, o ni looto ni ajo EFCC gbese le banki oludari oro owo naa. Sugbon, o salaye pe won ti pase ki won gbese kuro lori re pelu afikun pe akanti ti oludari oro owo ni won gbese le, kii se tawon asofin rara.

Olayanju salaye pe, ise ti eni to ko iwe ehonu naa lo n se. O ni “EFCC ti pase ki won gbese kuro lori akanti oludari oro owo, leyin ti won ti pari iwadii won. Eyi to fi han pe, ko ni ebo leru re niyen.

“Gege bi ise iwadii to n lo lowo lori awon moto tile igbimo asofin ipinle Oyo, looto ni ajo EFCC ti koko gbese le akanti oludari owo ile igbimo. Sugbon, kii se tawon omo ile rara, yala ti abenugan tabi omo ile.

“O pon dandan ka so eyi fun un yin. Agbasese ta a gbe ise fun ye ko ra moto Toyota Camry ti odun 2009, eya ti America fawon asofin.

“Gbogbo omo ile lo si ti gba ti won, ti won ti n lo moto Toyota Camry ti odun 2009, eya ti America fun bi osu mejo bayii. Ko si seni kan to saroye yala fun ile ni tabi fun enikeni lori moto re.

Sugbon sa, alaga ile igbimo asofin ipinle Oyo, Onarebu Adebo Ogundoyin ti kede ituka gbogbo awon igbimo ile pelu afikun pe igbese naa yoo tun mu kise ofin sise tun le maa te siwaju ni.

Lojo tosde ose to koja yii ni Ogundoyin kede ituka gbogbo igbimo merindinlogoji naa, saaju ki won to sun ijokoo ojo naa siwaju. O si wa salaye pe laipe yii ni won yoo maa kede awon mi-in fawon eeyan.

Bo tie je pe, Ogundoyin ko so idi ti won fi tu awon igbimo ohun ka. O ni “awon igbimo yii je okan ninu awon opo to gbe ile igbimo asofin duro. Odun keji wa ni yii ninu ile igbimo. Awon eeyan si n reti ka sagbeyewo ipo wa, won fe ka jafafa ninu ise ofin sise wa pelu. Nigba ta a ba sagbekale awon igbimo mi-in, yoo fawon omo ile igbimo lati le ni iriri otun, yoo si fun won lanfaani lati nimo sii.

Gege bi alaga ile se so, ituka ohun ba ilana ile mu, nitori to maa n seranwo lati mu ki ise ofin sise lo bo se ye. O fokan awon eeyan bale pe gbogbo aba ofin mewaa to si wa nile lawon igbimo pajawiri yoo mojuto.

 

“Nigba ta a ba pari ise lori aba ofin mewaa ohun, yoo je aba ofin metalelaadorin tile ti fowo si laarin odun meji pere tile asofin eleekesan-an yii ti bere. Eyi to ti koja ise ti gbogbo awon ile igbimo asofin to ti siwaju wa lo. Aba ofin metalelaadota pere nile asofin kejo le fowo si laarin odun merin. E wa foju wo iye aba ofin ta o fowo si laarin odun merin tiwa. Nise la n gbiyanju lati fi apeere to dara lele fawon ile igbimo to n bo leyin wa ni.

 

O wa dupe lowo gbogbo awon omo ile igbimo to sise ninu awon igbimo ti won tuka naa pelu afikun pe gbogbo aseyori tile igbimo asofin naa se ninu odun meji ko seyin ise asekara ati ifara-eni jin.