Wednesday 2 December 2020

Ope o! Ija WASIU AYINDE ati molebi BARRISTER ti pari


Ope o! Ija WASIU AYINDE ati molebi BARRISTER ti pari

Yanju Adegboyega

Ede aiyede ati aawo to wa laarin okunrin olori olorin Fuji nni, King Wasiu Ayinde Marshal ati molebi eni tigbagbo wa p’oun lo da orin Fuji sile, to tun je baba ti K1 yan nidii orin, Alaaji Sikiru Ayinde Barrister lo ti pari bayii.

Gege bi atejade ti Wasiu Ayinde fi sori ikanni ayelujara re, Olasunkanmi Marshal, ojo monde ose yii ni gbogbo aawo ohun wa sopin nipase ipade petu sija kan ti okunrin asiwaju olorin Juju nni, to tun je oludamoran pataki si Barrister nigba aye re, Oloye Ebenezer Obey Fabiyi pe.

Ipade ohun lo si waye nile Obey to wa laduugbo Ikeja nitosi opopona Obafemi Awolowo.

Gege bi atejise ohun se ka “bi gbogbo ogo se n je ti Olorun, mo layo lati kede ajosepo otun laarin Oloogbe Omowe Sikiru Ayinde Barrister ati emi (Olasunkanmi Ayinde Marshal) Mayegun ile Yoruba gege bi Olori Ebi. Ni ile baba wa agba, Ajihinrere Ebenezer Obey Fabiyi to wa n’Ikeja nitosi opopona Obafemi Awolowo. Nisoju Alaaji Adisa Osiefa, ore timotimo oloogbe. Lara awon to tun wa nibe aare ati akowe egbe onifuji, FUMAN lorile-ede yii.

Gbogbo awon omo ati iyawo lo peju pese sibe ati nipase imo-ero ayelujara zoom.

Ajosepo otun idunnu yii lo je ibere ayeye iranti odun kewaa ti Sikiru Ayinde Barrister doloogbe, eyi ti yoo waye lojo kerindinlogun osu kejila odun yii.”

Leyin ipade ohun ni gbogbo awon to wa nibe ya foto ajumoya lati fidii oro naa mule.

Pelu atejise yii, igbagbo gbogbo eeyan ni pe ajosepo otun ti pada saarin molebi Barrister ati Wasiu Ayinde. Ta o ba gbagbe, ni kete ti Barrister ku tan ni wahala be sile laarin molebi re ati Wasiu Ayinde lori awon oro kan ti won lo so nipa Barrister. Oro ohun si le to bee, ti Barry Made fi n korin bu Wasiu Ayinde, to sit un so okan-o-jokan kobakungbe oro si i ninu awon fonran ati iforowero to se pelu awon ile-ise redio.

 

 

No comments:

Post a Comment