Thursday 3 December 2020

EFUNSETAN sojoobi aadorin odun n’Ibadan


EFUNSETAN sojoobi aadorin odun n’Ibadan

-          Sugbon, awon gbajumo onitiata kan o si nibe

Yanju Adegboyega

Gbongan Mauve 21 to wa laduugbo Ring Road, Ibadan ko gbero lojo sannde, ojo kokandinlogbon osu kokanla lasiko ti Ajihinrere Abileko Iyabo Ogunsola, eni ti gbogbo awon ololufe ere tiata ati sinima tun mo si Efunsetan n sayeye ojoobi odun aadorin odun re.

Gege ba a se gbo, inu osu keta odun yii lo ti ye ki ayeye ohun waye. Sugbon, won ni lati sun un siwaju dojo sannde ose yii nitori ase ijoba lori ona ati dena itankale aisan Corona Virus tabi COVID-19 to n da gbogbo agbaye laamu.

Sugbon, akiyesi akoroyin wa to wa nibi eto ohun ni pe, looto lawon osere ori-itage atawon onitiata to loruko wa nibe. Sugbon, awon gbajumo osere kan tawon eeyan fe ri ko si nibe rara. Bee, ko seni to le so ni pato, idi ti gbogbo won ko fi si nibe.

Looto lawon eeyan bii aare egbe osere TAMPAN tele, Ogbeni Dele Odule, Oloye Lere Paimo atawon osere mi-in wa nibe. Sugbon, awon gbajumo osere bii aare egbe naa lasiko yii, Ogbeni Bolaji Amusan. Awon ti ko tun si nibi ayeye ohun ni Oga Bello, Aluwe, Iya Awero, Peju Ogunmola, Funke Akindele atawon mi-in to je irawo osere. Bee si la o reni so idi ti gbogbo won ko fi si nibe.

Ojo keedogun osu keta odun 1950 ni won bi Felicia Iyabode Ogunsola, oun si ni abikeyin Alagba Fajembola laduugbo Yemetu niluu Ibadan. Ile-iwe alakoobere St. Paul ni Yemetu lo ti bere iwe kika, leyin naa lo lo sile-eko girama Anglican Girls, Orita Mefa. Lat’igba to ti wa nile-iwe alakoobere lo ti maa n sere ori-itage, bee si ni ko fi sile nile-eko girama naa.

Lodun 1966, enikan mu un mo okunrin kan to n je Ogbeni Boladale, eni ti gbogbo eeyan tun mo si “Eda kekere tabi Baba kekere” ninu egbe osere Duro Ladipo. Lasiko ohun, okunrin yii ni maneja egbe osere ti Isola Ogunsola, eni ti gbogbo eeyan tun mo si I sho pepper. Egbe osere Ogunsola yii nilo awon osere-binrin.

Nitori ife to ni sise ere ori-itage sise, Iyabo gba lati tele egbe osere Ogunsola lo oko ere lawon ipinle oke oya tabi ile Hausa. I sho rii pe, omobinrin yii mo’se ju k’eeyan padanu re lo. Eyi lo je ko denu ife ko o, nigba ti won yoo si fi pada de lati irin-ajo ere ti won se lo sile Hausa. Oyun lo gbe wa sile. Bayii lo di iyawo Ogunsola, ti tohun si se gbogbo ohun to ye ko se lori re lati fe e nisu-loka. Lati odun 1966 yii lo si ti bere ise ere onise gege bi akosemose.

Lodun 1976, aluyo de fun un lasiko to kopa Iyalode Efunsetan ninu ere onise ti won se eda re ninu iwe Efunsetan Aniwura ti Ojogbon Akinwumi Isola ko. Lasiko ta a n so yii, awon ile-eko girama n ka iwe ohun. Ki awon akekoo si le loye re daadaa lo je ki won pinnu lati se e ni ere ori itage, Nigba ti Olorun yoo si se e, egbe osere Isola Ogunsola lo yege ninu awon egbe osere to gbiyanju lati se e.

Bayii ni oruko Iyabo Ogunsola di gbajumo nipase ere onise to so itan Iyalode ile Ibadan nigba kan ri naa. Okiki re si kan kaakiri gbogbo orile-ede yii ati oke okun. Gbogbo ibi ti won ba si ti lo sere yii lawon ipinle kaakiri orile-ede yii lawon ero ti maa n wo bi omi. Yato si pe won se ere Efunsetan ni ori itage, iwe iroyin atigbadegba kan, Atoka tun gbe e jade fawon eeyan lati ka.

Opo ere onise ati fiimu agbelewo ni Iya Efun, gege bawon eeyan se maa n pe e ti kopa. Bee loun pelu ti se awon eyi to je tie paapaa awon ere onise to je ti iyinrere bii Omo oloja irole ati Adehun agan.

Lodun 1992, o pinnu lati sise fun Olorun, nitori lati iwon odun 1970 lo ti n ri ipe, sugbon ti ko feti sii. Pelu adehun laarin oun ati oko re, o lo foruko sile nile-eko ekose ise iranse Christian Light Bible College, Ogbere, Ibadan nibi to ti kekoo ise iranse. O si ku die ko pari eko re ni oko re, Isola Ogunsola ku lojo kejidinlogbon osu kejila odun 1992.

Leyin to pari eko re, o bere ise iranse taara. Lati le lo ilana ise to n se fi sise Olorun, o lo sile-eko ekose ere onise ti ile-ise iranse Mount Zion niluu Ile-Ife lodun 1995. Leyin naa lo ti kekoo gboye imo ijinle dokita ni The Lord Bible School, Eko lodun 1999.

Mama Efun kii se osere ori itage nikan, onkorin ati akewi ni pelu. Opolopo rekoodu ofrin adura lo si ti se. Lara re ni Adura mi gba, 1 2 3, By fire by mercy, Next level, Akiikitan, Adura ibewo, My testimony lo ti so nipa igbesi aye re ati bo se di iranse Olorun. In Jesus name, Redeemer and winner, Sword of fire ati Aanu leekan si i.

 

Wednesday 2 December 2020

Ope o! Ija WASIU AYINDE ati molebi BARRISTER ti pari


Ope o! Ija WASIU AYINDE ati molebi BARRISTER ti pari

Yanju Adegboyega

Ede aiyede ati aawo to wa laarin okunrin olori olorin Fuji nni, King Wasiu Ayinde Marshal ati molebi eni tigbagbo wa p’oun lo da orin Fuji sile, to tun je baba ti K1 yan nidii orin, Alaaji Sikiru Ayinde Barrister lo ti pari bayii.

Gege bi atejade ti Wasiu Ayinde fi sori ikanni ayelujara re, Olasunkanmi Marshal, ojo monde ose yii ni gbogbo aawo ohun wa sopin nipase ipade petu sija kan ti okunrin asiwaju olorin Juju nni, to tun je oludamoran pataki si Barrister nigba aye re, Oloye Ebenezer Obey Fabiyi pe.

Ipade ohun lo si waye nile Obey to wa laduugbo Ikeja nitosi opopona Obafemi Awolowo.

Gege bi atejise ohun se ka “bi gbogbo ogo se n je ti Olorun, mo layo lati kede ajosepo otun laarin Oloogbe Omowe Sikiru Ayinde Barrister ati emi (Olasunkanmi Ayinde Marshal) Mayegun ile Yoruba gege bi Olori Ebi. Ni ile baba wa agba, Ajihinrere Ebenezer Obey Fabiyi to wa n’Ikeja nitosi opopona Obafemi Awolowo. Nisoju Alaaji Adisa Osiefa, ore timotimo oloogbe. Lara awon to tun wa nibe aare ati akowe egbe onifuji, FUMAN lorile-ede yii.

Gbogbo awon omo ati iyawo lo peju pese sibe ati nipase imo-ero ayelujara zoom.

Ajosepo otun idunnu yii lo je ibere ayeye iranti odun kewaa ti Sikiru Ayinde Barrister doloogbe, eyi ti yoo waye lojo kerindinlogun osu kejila odun yii.”

Leyin ipade ohun ni gbogbo awon to wa nibe ya foto ajumoya lati fidii oro naa mule.

Pelu atejise yii, igbagbo gbogbo eeyan ni pe ajosepo otun ti pada saarin molebi Barrister ati Wasiu Ayinde. Ta o ba gbagbe, ni kete ti Barrister ku tan ni wahala be sile laarin molebi re ati Wasiu Ayinde lori awon oro kan ti won lo so nipa Barrister. Oro ohun si le to bee, ti Barry Made fi n korin bu Wasiu Ayinde, to sit un so okan-o-jokan kobakungbe oro si i ninu awon fonran ati iforowero to se pelu awon ile-ise redio.