Wednesday 22 July 2020

O ma se o! SEGUN AINA, onitiata ku n’Ilorin

Yanju Adegboyega
Ajalu nla mi-in tun ja lawujo awon osere ori-itage lose to koja, nigba ti okan ninu awon agba osere ilu Ilorin, Alagba Dare Segun Aina naa tun ku. Gege ba a se gbo, ojo Tusde, ojo kerinla osu yii lokunrin naa ku leyin to ti saisan fun bi ose meta gbako.  Gege bi okan ninu awon to sun mo okunrin naa nigba aye re, Ogbeni Idowu Alarape se salaye fun akoroyin wa. Oko-ere okan ninu awon omo-ise re lo ti de lati ilu Olomi Oja, nigba to sakiyesi po fe re oun. Loju ese la si gbo po gba ile-iwosan lo, sugbon to pada ku sile-iwosan naa.
Omo bibi ilu Oke Opin nijoba ibile Ekiti, ipinle Kwara ni Alagba Dare Segun Aina.  O lo sile-iwe alakoobere niluu Oke Opin, leyin naa lo te siwaju nile-iwe girama Anglican, Oke Opin. Leyin to pari iwe mewaa, o lo ko’se ere ori-itage lodo Oloogbe Alagba Afolabi Ogundele, eni tawon eeyan tun mo si “baba Caleb” lodun 1980, odun 1985 lo si da duro gege bi oga nidii ise tiata.
Leyin to di ominira ara re, o kori siluu Eko, nibi to ti da ise po pelu okunrin gbajumo onitiata mi-in, Oloogbe Gbodorogun. Won si jo n gbe ere ori-itage kaakiri awon ilu ati adugbo niluu Eko, koda won maa n lo sere fun won lawon orile-ede to mule ti orile-ede yii, bii Cotonou.  Odun 1995 lo pada siluu abinibi re, Kwara to sit un n te siwaju ninu ise ere onise, sugbon ise awon to maa n to itage gan lo mu lokunkundun.
Yato si ise tiata, Oloogbe Aina tun n sise awon to maa n bawon gb’oku jo, ti won si maa n sinku. Koda, o ni moto ti won fi maa n gbe oku lo si ite, bee lo si n kan posi ta fawon eeyan.  Alarape sapejuwe okunrin naa gege bi eni to niwa pupo. O salaye pe, kii fa ijangbon rara. O ni ti oselu egbe ba de, to ba nifee sipo kan. Sugbon, to ba rii p’elomi-in naa nifee sipo ohun, nise ni yoo fi sile fun eni naa.
Nigba aye re, Alagba Aina ti figba kan je alaga egbe awon osere, ANTP nijoba ibile Irepodun, ipinle Kwara ri. Bee lo ti je oludari ariya (Social Director) fun egbe osere TAMPAN lodun 2005. Meji ninu awon omo re, okunrin kan, obinrin kan lo n sise ere ori-itage lasiko yii, Seun ati Adeola.
Opo awon gbaju gbaja osere ori-itage lo ti ba sise papo bii  Oloogbe Ogun Majek; Fokoko;  Iya Tuudi; Abeni Agbon; Oloogbe Ajileye;  Oloogbe Dagunro; Olofa Ina;  Iya Iroko; Lalude atawon mi-in bee bee lo. Eni odun mejidinlogota ni lasiko iku re.
Akiyesi : O ti jade ninu iwe iroyin ALARIYA OODUA ose yii.