Monday 28 October 2019

Owo te tewon de, to ji okada ni Bariga


Owo tewon de, to ji okada ni Bariga
Ade Oniroyin
Owo ileese olopaa ti te okunrin kan to sese de lati ogba ewon, Folarin Moses lori esun po fipa gba okada lowo okunrin kan, Olayemi Agbamuche laduugbo Bariga niluu Eko.
Nigba to n fidii isele ohun mule, alukoro ileese olopaa ipinle Eko, Bala Elkana salaye pe bi olobo isele ohun se taoga olopaa tesan Bariga lo ti dawon olopaa sita, ti won si mu odaran naa, pelu afikun pe laipe yii ni won da odaran naa sile logba ewon lori esun kan naa.

Owo te Deborah to ji moto jiipu gbe


Owo te Deborah to ju moto jiipu gbe
Ade Oniroyin
Owo ileese olopaa ipinle eko ti te omobinrin alagbata kan, Deborah Nwachukwu lori esun po ji moto jiipu kan, foonu was arrested for allegedly stealing a Jeep, Samsung S10, aago owo, awon ohun ikunra oloorun towo re to milionu kan naira ati owo gbe lodo okunrin kan ti won poruko re ni Patrick laduugbo Ikeja nipinle Eko.
Alukoro ileese olopaa, Bala Elkana salaye pe Patrick pade Nwachukwu  nile-itaja kan, o si pee lati wa baa tun ile re se pelu adehun lati fun un ni egberun lona ogun naira. Gege bo se wi, Patrick ni adehun a ti jo lajosepo naa wa laarin won. O soo di mimo pe, leyin ti won lasepo tan, ni Patrick sun lo.
“ Bo se sakiyesi pe, okunrin yi ti sun lo fonfon. Nise lo ko foonu re mejeeji, aago owo ohun ikunra oloorun, owo ati moto jiipu re. Bayii lo si salo, leyin to ti tii mole. Awon osise olopaa otelemuye ti oga olopaa tesan Ikeja, Gbenga Ogunsakin lewaju re lo si mu omobinrin ohun, ti won si gba gbogbo ohun to ji na. Won ti gbe odaran yi lo siwaju ile-ejo, ti won si ti fi pamo si ahamo.

Kayeefi! Baba pa omo re lasiko to n ba iyawo re ja


Kayeefi!
Baba pa omo re lasiko to n ba iyawo re ja
Ade Oniroyin
Owo ileese olopaa ipinle Eko ti te okunrin kan,  Ayobami Isiaka lori esun po pa omo re, omo odun kan laduugbo Ijaye nitosi Iseri niluu Eko.
Gege bi alukoro ileese olopaa ipinle Eko, Bala Elkana se so ninu atejade kan to fi sita lojo sannde ana, Ayobami pa omo re ohun t’oruko re n je Nana lasiko tie de aiyede kan waye laarin oun atiyawo re. akoroyin wa gbo pe, nise ni okunrin yii sadeede gba omo lowo iyawo re, to si la ori re mole.
O soo di mimo pe, nise loei Nana fo yanga yanga loju ese nibe pelu afikun pe omooya Ayobami lo mu esun ohun lo si ago olopaa. Ninu oro re, Elkana ni “lojo sannde, ojo kerindinlogbon osu yii ni deedee aago meje ku iseju mewaa, okunrin kan,  Alaaji Garuba Isiaka mu esun lo si ago olopaa pe lojo naa, lasiko toun wa ni Berger, ni aburo oun kan, Alaaji Mohammad Isiaka foonu pe, Ayobami Isiaka ti fi tipatipa gba omo re obinrin omo odun kan, Nana lowo iya re, to si lee mole”
“Ori omo naa fo tutu, to si ku loju ese nibe. Ti ko ba si si tawon olopaa to tete de ibi isele ohun, nise lawon eeyan to wa nitosi ki ba luu pa. Laipe ni yoo si foju ba ile-ejo.”