Friday 23 February 2024

 

Oro Sunnukun

Ebi ati Ekun Ariwa Nigeria

Yanju Adegboyega



Ohun kan soso t’awon eeyan maa n so po maa n mu ki awon omo orile-ede yii sokan tele ri ni ere boolu alafesegba. Sugbon lasiko ta a wa yii, ohun kan soso to so gbogbo omo orile-ede yii papo ni ebi, o ga’ja f’owo meke.

Lasiko ta a wa ni kekere, aalo apagbe kan wa, ta a maa n pa laarin ara wa. Itan ijapa ari aja ni. Itan ohun lo si nii se pelu ai si ounje niluu ati ebi opapanla. Ninu aalo yii, a ri eko to nii se nipa iwa okanjua ati ohun to see se ko gbeyin re.

Itan ohun lo bayii, lasiko kan seyin, iyan mu pupo niluu awon eranko, eyi to si sokunfa owongogo ounje. Ni atako si asotele si ariran ti won ranse si lati ba won beere lowo Olorun fun ona abayo si isoro yii, nise ma ni ebi ati owon ounje yii maa tun n le sii. Owon ounje yii buru to bee ti won ti fi gbogbo ounje ti won ko pamo sinu aka tan patapata.

Nigba to d’ojo kan, gege bi olori fun gbogbo awon eranko, kiniun pe ipade gbogbo awon eranko jo, awon agba sa kuku ti soro pe, ebi kii wonu, ki oro miran o wo o, won si tun ni, ohun ta o je s’agba ohun ti a o jee. Pelu bi ebi se n lu won ni pasan, ni gbogbo awon eranko ra pala de ibi gbagede ipade.

Nigba to si bere oro re, kiniun, eni tie bi foju han lara tie pelu ha fun re “kehe kehe”, o ni ko si ani-ani pe iyan to mu yii n ba onikaluku finra pupo, eyi to si ti sokunfa iku opo awon eranko akegbe won. O toka pe, a fi ki won o gbe igbese kiakia, afaimo ki nnkan o ma buru ju bayii lo.

Bayii ni won pinnu igbese ti won yoo gbe e. Ohun ti won fenu ko si nip e, ki onikaluku maa fa iya won kale, ki won si maa pa won je, ki gbogbo iran eranko ma ba a parun kuro lori ile aye. Won gba pe, ki onikaluku maa mu iya re wa sibi gbagede ipade leyo kookan ki gbogbo won si dijo maa je e, ki iran eranko si le wa laye sii.

Gbigbo ti aja gbo oro yii, eyi ti ko ba fi tele adehun ti gbogbo awon eranko fenu ko le lori yii, iwa imotara-eni nikan aja lo mu ko fi oru oganjo boju mu iya re kuro nile, to si se bee mu un kuro laarin ilu. Se aja nifee iya re pupo, to bee to fi ni, o ya oun lara lati ku, ju ki oun fa a kale fun awon eranko to ku lati pa a je, ki iran eranko le si maa waye lo. Bayii ni aja sa kuro niluu lo sibi kan to fara sin leyin to ti gbe iya re pamo si orun.

Gbogbo awon eranko, to fi mo ijapa, ologbon ewe lo tele adehun ti gbogbo awon eranko jo se. Won n mu iya won was i gbagede ipade, won si jo n je won. Sugbon, lojoojumo, aja maa n lo sibi kan nibi to ti maa n fi orin pe iya re. Orin naa lo bayii:

“Iya, Iya ta’kun wa le o.

Alujanjan kijan.

Gbogbo aye lo pa yeye e je.

Alujanjan kijan.

Emi aja gbe tire, o d’orun.

Alujanjan kijan….

Leyin ti aja ba ti korin bayii tan, iya re yoo ju okun kan sile fun un, eyi ti aja yoo si fi gun oke lo sorun, nibi ti yoo ti je ounje a je yo ati a je ran ikun. Nigba to ya, awon eranko t ku bere sii fura si aja, nitori nise lo n dan, tie eke re si n yo jade. Nigba to di ojo kan, ijapa, ologbon ewe so aja, o si mo asiri re.

Lojo keji, ijapa yo lo sibi ti aja ti maa n pe iya re yii, o yi ohun re pada, o si korin bi aja se maa n ko o. Iya si ju okun sile fun un looto. Bi ijapa se n gun okun yii lo n aja yo, inu re si ru pupo. Lo ba bere sii sunkun, to si n fi ohun-aro korin pe, ohun orin onijibiti ni iya oun f’eti si ati pe se iya oun wa mo ohun oun mo ni? Inu bi iya aja, lo ba fibinu geo kun laarin meji. Bayii ni ijapa ja lule lati oke, ti igba eyin re si fo petepete. Agbara kaka si ni ijapa fi rin de odo ikamudu to ba a to igba eyin re po pada.

Yato si pe, itan yii ko ni logbon, awon Yoruba lo iriri won nipa owon ounje lati salaye idi ti igba eyin ijapa se ri bo se ri lonii.

Sugbon, se ka ma f’eko tan ina funra wa, ebi wa niluu lasiko yii. Te e ba ri fonran fidio kan lori ikanni ayelujara ni nnkan ose meji seyin, e o jerii sii pe looto ni owon ounje n ba orile-ede Nigeria finra. Ninu fonran yii, awon eeyan kan n ja lati gba buredi ogorun-un kan naira laduugbo Isale Eko, bee si ni won n lu ara won nitori ati ri gba nibe. Yato sawon okan-o-jokan isoro ti orile-ede yii n koju, owon gogo awon ohun tie nu n je to n ba Nigeria finra buru to bee, to ti n dunkooko mo emi ati igbaye wa.

Looto, isoro ounje kii kuku se ohun tuntun l’aye. Orile-ede kookan lo n mo ilana ati ogbon to n da soro ebi lodo won. Ta a ba lo sinu iwe iranti, niwon odun 1950 si 1960, orile-ede India nisoro owon ohun t’enu n je. Isele yii le to bee, ti won fi fun ile naa ni inagije orile-ede “abo alagbe”. (Begging bowl nation).

Irufe isele yii ti n sele lat’igba toju ti wa lorunkun, sugbon orile-ede kookan ni yoo wa woroko fi s’ada lori re. Ta a ba lo sinu itan Bibeli, nigba ti iyan nla mu ni orile-ede Farao, iyen Egypt. Farao ra opo ounje lati awon ilu mi-in, won si ko won pamo sinu aka. Koda, won tun se agbega fun Josefu sipo olootu ijoba lati maa samojuto asiko owon ounje naa.

Isele owon gogo awon ohun t’enu n je, to n lo lowo lorile-ede yii lasiko ta a wa yii ti fe pin emi awon eeyan. Ounje atawon ohun mi-in lo ti won koja ibi t’eeyan l’ero ri. Ehonu n fojoojumo waye kaakiri. Bi owo oja atawon ohun t’enu n je se n fojoojumo gb’owo lori n ko’ni lominu. Bi oja se n deru ba owo, ti feree le to bee, ti opo awon molebi ko le da enu won bo mo. Apo simenti ikole ti le ni egberun kan, nigba ti apo iresi ti feree to egbrun lona ogorun-un naira. Lasiko ta a wa yii, owon gogo ounje ti n ti awon omo Nigeria jade sawon oju opopona lati fehonu han l’awon ipinle bii Niger, Kano, Osun ati Eko. Eru si ti bere sii baa won eeyan to mo nnkan ti isele yii le bi.

Ajo to n seto ounje lagbaye, World Food Programme, WFP, ninu iwe re to gbe jade laipe yii ni eru ti n ba pe, wahala ohun le nipa buburu lori awon okoo le lugba omo orile-ede yii, gege bi orile-ede eniyan dudu to ni eeyan to po julo nile Africa ati eekefa l’agbaye. Ko to dasiko yii, ominu ti n ko ajo WFP lori, awon omo orile-ede yi to to milionu merinlelogorin, eyi tii se ida metadinlogoji gbogbo awon omo orile-ede yii. Won toka si awon isele bii rogbodiyan ati eto aabo ti ko dara, bi nnkan se n fojoojumo won ati ipa ti ayipada oju ojo le ni lori ohun t’enu n je. Ajo WFP se afojusun pe, awon omo orile-ede yii ti won to milionu merindinlogbon aabo ni yoo foju wina ebi opapanla nigba ti yoo ba fi di osi kefa si ikejo odun yii lasiko ire-oko yoo ti maa dinku.Wahala to si n sele ni ila oorun ariwa orile-ede yii, eyi to ti so awon eeyan ti ko din ni milionu meji le meji di alai nile lori pelu bo se se akoba fun awon milionu merin le merin mi-in lati ri ounje je l’awon ipinle bii Borno, Adamawa and Yobe kun isoro to wa nile ohun.

E je ka wa pada sibi ipade awon eranko, gbogbo wa pejo lati wa egbo dekun fun alujannu to n je ebi yii. Sugbon, kin i esi t’awon olori wa ni Nigeria fo soro ohun? Ninu oro tie, Aare Tinub u pase ki ile-ise ijoba apapo to wa fun ise ogbin lati ko awon ire oko bii agbado, jero ati gari to to egberun mejilelogoji toonu jade. O tun se ipade po pelu awon gomina nile ijoba Aso Rock lojo alamisi ose to lo, nibi to ti so fun won yanya pe, kiko ounje wole lati ile okeere ko ni ona abayo si isoro to wa nile naa. Tinubu tun rawo ebe sawon gomina lati karamaasiki inawo si eka ipese eso, eran osin ati eto kiko ounje pamo nidii ise ogbin, ki ounje le po yanturu.

Sugbon, nigba ti won yoo maa fesi soro owon gogo ounje, nise l’awon gomina apa ariwa huwa bi omugo, ti won kopa irufe eyi ti aja ko lasiko iyan. Eyi ti won n fogbon ati iwa imotara-eni se nipa siso oro owon ounje ohun di ti eleyameya. Latile wa lo ti je pe, kii si ani-ani pe, iwa imotara-eni nikan l’awon asiwaju oke oya maa n hu, bi igba to je pe kadara won ni lati maa da se ti won nikan, ni atako si ajosepo gbogbo eeyan. Eyi lo mu un wa siranti, oro kan t’awon Yoruba maa n so pe, eni ti yoo sun l’ebi ni, koda ti won bag be abo iyan kan si ori pepe fun un, eku yoo debe lati ja abo ohun bo.

Aja, onimo-tara-eni akoko ni gomina ipinle Niger, Mohammed Umar Bago. Ki ni ifehonu han waye ni Minna ni nnkan bi ose meloo seyin, nise Bago f’ofin de tita awon ohun t’enu n je lopo yanturu fun awon onisowo ounje lati guusu orile-ede yii l’awon oja won. Gege bi aja kan naa, Emir Kano, Alaaji Aminu Bayero naa gbe iya re lo s’orun. Nigba to n gba iyawo aare, Oluremi Tinubu lalejo l’aafin re ni bi ose meji sasiko yii. Bayero ro obinrin akoko lorile-ede yii lati jise fun oko re, Bola Tinubu pe, ebi, iyan ati eto aabo ti ko fara to n daamu orile-ede yii ti di oro ai l’aso lorun paaka, eyi to ye ko ti to apero fun gbogbo omo eriwo.

Nigba to tun soro, nipase ogbufo, leyin opolopo alaye to ti waye lori bi awon eeyan ariwa se n ri olu ilu orile-ede yii gege bi ti won nikan ati anfaani ti igbese ijoba apapo n gbe pelu bi won se n bu enu-ate lu igbese ijoba apapo lati ko awon oofiisi kan ni ile-ise oko ofurufu ati banki agba orile-ede yii lo siluu Eko, Bayero tun m’enu ba oro yii.

Nibi ipade awon omo igbimo alase awon oba alaye ile Hausa to waye lojo wesidee ose to koja lo lohun-un nile Arewa niluu Kaduna, Sultan ilu Sokoto, Muhammad Sa’ad Abubakar atawon oba alaye re naa huwa aja, alujanjan kijan, nigba ti won gbe iya won lo s’orun. Won kilo pe, o see se k’awon eeyan ariwa fehonu nla han ti ise, ebi ati eto aabo to mehe yii ba n te siwaju, ti ijoba o si ri nnkan se si i.

Ko si iro nibe pe, owon gogo ounje to wa nita yii n ta awon eeyan lori. Won tun soro lori bi gbogbo awon isejoba to ti n koja ni Nigeria ko se ni iwa olori rere, eni to ni afojusun ojo ola.

Sugbon, ta a ba fe so ooto oro, o ti pet i ikilo ti n wa pe, orile-ede Nigeria yoo koju isoro own gogo ounje. Ko sese bere lonii, ko sis i okan kan ninu awon olori yii to f’eti si ikilo yii nigba naa. Abi, nigba t’awon Fulani daran daran to n da eran daran n se ikolu s’awon ipinle ta a mo gege bi ibi ti ounje ti n wa bii Benue, Plateau, Adamawa, Taraba, Kaduna, Yobe, Niger ati Jigawa, nibi ti won ti n pese iresi, ata, ege, isu, ogede dodo, ope oyinbo, agbado, ewa, ati epo pupa.

E dakun, ki ni isejoba Muhammadu Buhari se nigba naa? Ogbon won i won da si ifehonu han alagbara awon ekun to ku l’orile-ede yii lasiko naa? E je ka gba pe, isoro ohun fon ina soju ni kete tijoba Tinubu kede iyokuro owo iranwo ori epo lojo to n gba isakooso l’osu karun-un odun to koja ati isodokan iye ti won n se pasipaaro owo ile okeere. Nitori naa, a le se bi pa o mo pe, asiko isejoba Buhari ni isoro oro owon ounje oni bere, nigba t’awon agbe ko le lo sinu oko won mo, nitori iberu bojo ai si eto aabo fun won.

Iwadii ti je ka mo lati awon ipinle to si l’oore-ofe lati maa pese ounje, pelu bi eto aabo se n se segesege pe won ti f’enu ko pe, won o nii je ki awon ounje ohun was i apa guusu mo. Ohun ti mo wa n ro mi pe, ki lo le sele, t’awon ipinle to wa ni guusu naa ba ni k’awom ohun-elo to se pataki lati odo won o ma jade lo si ariwa mo. Ki ni yoo je ipa ti yoo ni? Bi apeere, ki won ma jee ki epo petiroolu de apa ariwa?

Lasiko ti gbogbo omo orile-ede Nigeria foju wina owon gogo ounje, awon asiwaju apa ariwa n fi iwa imotara-eni nikan pariwo pe nnkan o rogbo fun won. E dakun, lasiko ti omo won, Buhari n mu aye nira fun gbogbo awa omo orile-ede yii, eemeloo ni Emir Kano ati Sultan Sokoto pariwo sita? Irufe ogbon alumokoroyi lati je ko dabi igba to je guusu lo n f’ebi p’awon omo Nigeria yii, ti awon eya ariwa fe lo yii ko feree yato si ona lati gbe ebi gbogbo oro isoro Nigeria yii kuro lori ara won.

To ba je p’awon baba nla won ni ariwa ti mojuto iwa “a bimo, ma to o” ti gbogbo eeyan mo si “Alumajiri” lonii, o see se ka ma nisoro awon onisunmomi to n ba fa finra, eyi ti orile-ede Nigeria tin a opolopo tirilionu owo naira le lori, to si ti gba emi opolopo. Eyi to tun fara jo o, nit i okunrin omo bibi ipinle Borno nni, Mohammed Yusuf, eni to je oludasile egbe awon alakatakiti esin Musulumi, Boko Haram. To ba je p’awon onimotara-eni asiwaju ariwa ko faaye gba egbe yii lati gbeeru ni, o see se ki orile-ede Nigeria o ma maa foju wina ai si eto aabo to peye, eyi to sokunfa owon gogo ounje lasiko yii.

Ona abayo kuro ninu isoro owon gogo ounje to n ba wa finra lorile-ede yii kii se k’awon kan o fee so ebi oro di ti igun kan. Koda, ki Tinubu kede ilu o fara ro nidii eto ogbin ko le tan an, nise lo ye ko sun, ko takaaka, gege bi olori ilu lasiko ti nnkan o rogbo yii. Bo se se pataki lati wa ojutuu soro owon gogo ounje yii, ko to maa mu emi lo, lo ye ki ijoba wa ona ti yoo je onigba pipe ati eyi ti ko nii maa gbon owo lo lati wa ona abayo. Ona akoko, ni ka doju koi se ogbin pelu gbogbo okun ati agbara wa.

Asiko yii lo ye ki Tinubu lo wa iru okunrin ojogbonm onimo nipa eto ogbin nni, Adedunmola Hezekiah Oluwasanmi, eni ti gbogbo eeyan n kan saara si lori ilana to lo lori eto ogbin ile-eko giga yunifasiti Obafemi Awolowo lojosi. Okunrin Oluwasanmi yii si gbodo l’awon eeyan to tip o ito omo re nipa eto ogbin si lenu kaakiri orile-ede Nigeria. Nise lo ye ki ijoba se koriya gidi fun awon agbe, ki won si rii daju pee to aabo won fokan bale, eyi ti yoo jee ki won le pinnu tabi gba lati pada s’oko. Eyi ti yoo mu ki ounje o sun wa bo, ti yoo si se bee mu adinku ba owo gegegee ti won fi n le ounje. O ye ki ijoba seto, ki awon eeyan to ba n dokoowo nidii ise ogbin le maa ri ere gidi je, ti ere ajepajude ti yoo tun mu nnkan le fun mekunnu ko si nii si.

Bi apeere, ki lo de ti ijoba ko se koriya fun awon gomina ile Yoruba, ki won pada sidii ogbin koko, eyi to n se daadaa l’oja agbaye lasiko yii, ki won se koriya fun epo pupa ni ila oorun guusu ati awon ohun ogbin to n se daadaa ni ariwa?

Ko si ani-ani pe, lonii, orile-ede India ti gbogbo agbaye fi n seleya nitori iyan ati ebi to foju wina niwon odun 1960 gbe igbese akin, eyi to pada di aseyori ounje a ni to ati a ni seku fun won. Lonii, okan pataki ninu awon orile-ede to n f’ounje ranse s’awon ilu ile okeere fun titan i India.

Olori to ba looto, to si nipinnu le se iru aseyori orile-ede India ni Nigeria naa. Eyi ti gbogbo awon ekun to wa ni Nigeria yoo se maa gbe iya won salo fun ipalara bi aja inu itan ta a so saaju, irufe bi awon eeyan ariwa se n se lasiko yii, nise lo ye ka jo wa ojutuu soro to wa nile yii. Ka si jo fopin si isoro owon gogo ounje to n koju wa. Awon Yoruba ni, afaa to n’iyan o mu ni, omo re o nii je tira o.

Oro Sunnukun re o, e je ka jo foju sunnnukun wo o!