Wednesday 3 November 2021

Ni Saki, WASIU ge ori orebinrin re lati soogun owo


 

Ni Saki, WASIU ge ori orebinrin re lati soogun owo

Yanju Adegboyega

Gbogbo awon eeyan to gbo sisele aburu ohun lo n semo pe, iru odaju eeyan wo ni Ismai Wasiu ati Shittu Mutairu, tawon mejeeji gbimo po pa omobinrin kan, Mujidat, ti won si ge gbogbo eya ara re lati fi soogun owo. Gege ba a se gbo, owo ile-ise olopaa lo te Ismail Wasiu, eni odun mokandinlogbon ati Shittu Mutairu, eni odun marunlelogbon niluu Saki lori iwa odaran to gba omi loju awon eeyan to gbo naa.

Nigba to n soro lori isele aburu ohun, alukoro ile-ise olopaa ipinle Oyo, Adewale Osifeso salaye pawon osise olopaa ni tesan ekun ilu Saki lo mu awon odaran mejeeji ohun leyin tiroyin kan won pe won ba ori eeyan tutu to je ti obinrin kan atawon eya ara mi-in lowo won.

Osifeso ni, nigba towo te awon eeyan mejeeji yii, ni won mo p'ajosepo wa laarin oloogbe naa ati Wasiu. Nitori, oun ni won lo pe e wa silu Saki.

Nigba to n jewo fawon olopaa, Wasiu, eni odun mokandinlogbon to ni afaa ati onisegun ibile l'oun ni afaa l'eni to toju oun dagba, sugbon nitori ajosepo oun pelu awon eeyan to je onisegun ibile, ti won si n gba oun nimoran lati darapo mo won lo je k'oun tun maa se isegun ibile naa.

O ni "Lodun 2013, mo kuro ni Saki lo siluu Eko nibi ti mo ti n sise omo-odo laduugbo Magodo. Ore mi kan lo mu mi lo sibe. Leyin odun meta, mo pada si Saki. Mo si bere ise isegun ibile.

"Gege bi mo se so. Afaa l'eni to toju mi dagba. Molebi ni wa. Nigba ti mo pada de Saki, mi o mo bi won se n tumo Kuraani. Mo kan se Wolimot ni. Mo maa n lo si mosalasi lo sadura leekookan sa. Nitori naa, mo da ise Afaa ati isegun ibile papo.

"Ise etutu ti mo se fun omo Yahoo kan ni akoko ti maa se, o si sise fun un daadaa. O l'oun fe se oogun owo, mo si lo ori eeyan gbigbe fun un. Nipase enikan ta a jo lo sile-iwe alakoobere ni mo ti mo omo Yahoo naa. Ise okada ni eni naa n se, o si maa n gbe omo Yahoo yen kiri. O mo pe omo Yahoo ni. Mi o mo oruko re. Ibadan lo ti wa se etutu naa.

"Mo lo ba eeyan mi kan ti oun naa je onisegub ibile, to tun je bi omo-iya si mi laduugbo. Mo mo po maa n ni ori eeyan gbigbe lowo. Sugbon, nigba ti mo de odo re, ko ni lowo lasiko yen. Nitori naa, o mu mi lo sodo ore re kan. Iyen naa o ni.

"O fun mi ni nomba dokto to n gbe laduugbo kan naa pelu mi. Mi o mo po n se iru nnkan bee. Mo kan mo pe, o ni soobu kemisti ni, o si maa n toju awon eeyan ninu yara kan nile re. Mo lo sodo re, o si ni ki n san egberun lona ogota naira fun eyo kan.

"Mo ni, mi o lowo to to bee. Mo si fun un egberun lona aadota naira. O ta a fun mi, mo si lo lati se etutu yen. Etutu naa gba, nitori ti omo Yahoo yen foonu mi lati dupe lopolopo.

"Nigba t'omo Yahoo yen wa. Emi ni mo so fun un pe, yoo nilo ori eeyan lati se etutu naa. Inu iwe akosile Afaa to toju mi dagba yen ni mo ti ri i leyin to ku.

"Lati se etutu yen.  A o wa ori eeyan gbigbe, owo eranko iro meji, ori ejo oka meji, ori ejo olufa meji, apori ti won fi igi iroko se, ori sinaapu ati ose dudu. A o lo gbogbo re papo, leyin naa la o da oti sinaapu yen si i. A o wa yi gbogbo re papo mo ose dudu naa. A o ko gbogbo re sinu awo abomafo funfun to ni omori, a o si gbe e sori apoti naa. Leyin naa la o gbe ori sinaapu to ku si i legbee.

"To ba fe lo o. Omo Yahoo yen maa mu oti ogogoro yen, ko to lo fi ohun ta a pop o yen we. O foonu mi pe, ise naa je pelu ileri p'oun si maa wa san esan oore ti mo se e naa. Sugbon, mi o tii foju kan rara, ki awon olopaa to wa mu mi. Looto, o fun mi ni egberun lona igba naira ki n to bere ise re.

Etutu eleekeji

"NIgba ti mo pari ise yii. Mo ro o ninu ara mi po ye ki n wa ona ti mo le fi maa r'owo gidi. Mo lo wonu iwe akosile Afaa, mo si rii pe, t'eeyan ba lo ori eeyan tutu, t'eeyan si mo oruko eni naa daadaa. Yoo mu esi gidi wa, ju k'eeyan lo gbigbe lo.

"Mo lo sodo Mutairu lati salaye fun un pe, Mujidat lo wa lokan mi lati lo. O ti so fun tele p'oun n gbero lati soogun owo, leyin ti egbo kan to wa l'ese re nigba to lasidenti ti san. A ti soro bi ose kan, saaju asiko ti Mujidat wa si Saki.

Bi mo se mo Mujidat

"Ikeja ni mo ti mo Mujidat niluu Eko. Ipase ore mi kan ti mo pade ninu moto akero, nigba ti mo n lo s'Ekoo ni mo ti mo on. Mo maa n lo sodo re daadaa, nibe lo ti mu emi ati Mujidat mo ara wa nile-itura kan to ti n sise omo oloja irole. Mo maa n ba a lajosepo daadaa, nigba yoowu ti mo ba wa n'Ikeja. Bayii la se di ore. Nigba ti mo pada si Saki, mo ni nomba foonu re lowo, a si jo n sore sibe naa.

"Mo maa n fowo ranse si i. Lati bii egberun marun-un si ogun egberun. Lasiko yii, mi o ba a so nnkan kan. Olugbohun ti ko le ko, ni mo lo fun un. Saaju asiko yii, o ti wa ki mi bi eemeji ri. Lasiko yii, nigba to de ni deedee aago mefa irole, mo lo olugbohun fun un pe, ko wo inu yara ti mo ti maa n sise. O wole, mo si wa pelu re. Mutairu naa wa wow a, o si jade lo pada.

"Ni deedee aago mewaa ale. Mo ni ki Mujidat tele mi lo sona ibi kan, o si tele mi lai beere nnkan kan. Oogun ti mo lo lataaro si n sise lara re. Awa meteeta kori sinu igbo. Mo ni ko jokoo sile. Mo si mu oogun yen jade, mo tun lo o fun un.

"Bi mo se n pofo, Mutairu n ni ki Mujidat maa ni "Ase". Merin ni gbogbo ofo yen, bi mo se n pe e, lo n se ase si i.

"Leyin naa ni mo ni ko sun sile, mo ni ki Mutairu de owo re. Mo yin in lorun. Nigba ti mo ri bi oju re se ri pelu irora, ara mi o gba a mo. Mo ni ki Mutairu je ka fi sile, nitori mi o se iru re ri. Sugbon, o ni ka pari ise naa. Mi o le yin in lorun mo, nitori naa Mutairu gba a lowo mi. O si pari re.

Igba tie mi ti kuro lara re. Mo fi obe kan ge ori ati owo re mejeeji. Mo tun yo okan re, nigba ti Mutairu yo itan re mejeeji ati nnkan-omobinrin re. A gbe okutu re lo sibi kan legbe apata kan ninu igbo, a si gbe e ju sibe. A ko itan re pamo sinu igbe, a si fi ewe bo o. A gbe ori re, okan, owo ati nnkan-omobinrin re wa sile. Mi o mo nnkan ta a le lo nnkan-omobinrin re fun, mo kan sa yo o kuro lara re pelu ireti p’enikan le f era ni. Mutairu lo nilo owo.

Bowo se te wa

Ni deedee aago meji oru la dele. Ba a se dele, mo gbo ohun tisa ile-ku kan, to dabi baba si mi, ta a si ji n gbe nile. Mo lo sita lo to, mo si tan ina atetan foonu mi. O beere pe, ta a lo tan ina foonu oun, mo si ni emi ni. Ile wa koju si titi ni, oun si wa legbee titi. Aso oogun mi ni mo. Aabo lo wa fun ati isora. O ri aso yen, o si beere ohun ti mo n se. Mo da a lohun pe, mo n se awon ise kan ninu ile ni.

“Bawon meji ninu awon to n so adugbo wa, ti won n pe ni Soludero se de niyen. Mutairu naa tan ina atetan foonu re, o si pa a pada. O tun tun un se. Afaa yen sakiyesi re, o si beere pe ta a ni. Mo ni Mutairu ni. Oluko ile keu yen wa ni, ki won lo ye inu yara ti mo ti n sise wo. Bi won se ri ori eeyan tutu yen atawon eya ara ni yii. Inu ike ibomi kan la gbe ori yen si, a si da ogogoro si i. A si ko owo, okan ati nnkan-omobinrin naa sinu ike mi-in, bee la da ogogoro si i lati le ma je ko tete baje.

“Mutairu ti koko n wa awawi, sugbon emi jewo ohun ta a se. Won ni ki n mu won lo sibi ta a gbe okutu re si ati ibi ta a ko itan re si. Awon iko Amotekun naa tun de, won si ni ki n ko okutu, itan pelu ori atawon eya ara to ku ti won ba nile. Won fi moto gbe mi lo si tesan olopaa, won si fa mi lawon olopaa lowo.

Ki ni yoo sele si i leyin oran to da yii.

“Mo nigbagbo pe, ohun ti Olorun ti kadara fun irin-ajo aye mi ni yii. Mi o mo nnkan tijoba maa se nipa oro mi. Sugbon, nigba tawon molebi mi gbo nipa isele naa, nise ni won n sunkun pe mo ti ba aye won je. Iyawo meji ni mo ni. Okan bimo meji ti ojo-ori won je odun meta ati odun kan. Nigba ti omo ekeji ko tii ju osu merin si marun-un lo.

Ninu oro ti Shittu Mutairu

“Mo lasidenti l’Ekoo. Mo subu lori okada, awon dokita si gbiyanju lati toju mi. Sugbon, oju-egbo yen kan n ke sii ni. Mo ro o ninu ara mi pe, oju-egbo to n ke yii kii soju lasan ati pe apa awon dokita onisegun oyinbo le ma ka a.

“Mo wa si Saki, omo-iya mi kan si n ba mi toju egbo naa pelu egboogi ibile. Fun bi osu mefa, mi o le jade ninu yara mi. Leyin naa, nigba tara de mi die. Maa jade, lo jokoo sabe igi kan. Bayii ni mo se mo Wasiu. Awon eeyan to n koja maa n fun mi lowo bii aadota tabi ogorun-un kan naira. Wasiu atawon aladuugbo mi-in maa n gb’ounje wa fun mi.

Lenu ojo meta yii, o so fun mi pe omobinrin kan n wa oun bo ati p’oun si n gbero lati lo o fun etutu fawon onibaara oun. Mo gba lati darapo mo on, nitori ohun ti mo n koju. O seleri lati ran mi lowo lati ki egbo mi san ni kete ti owo ba ti jade nidii etutu naa. nibi ti mo ti jokoo sidii apata ni omobinrin naa de. Wasiu wa ba mi, o ni ki n maa bo ninu yara ise oun. Mo lo. Mo si ri omobinrin naa. Wasiu ni ki n maa lo. Mo si pada sidii apata.

“Ni deedee aago mewaa ale, oun ati omobinrin naa ba mi nidii apata, a si wonu igbo lo. O so fun omobinrin naa lati jokoo, awa naa si darapo mo on.

 “O gbe oogun kan, olugbohun jade. Mi o mo nnkan to n so, sugbon a n se ase.

“O ni ki omobinrin naa sun sile, o si mu omiran jade. O wo o si apa re. o tun mu oogun mi-in jade, o fi le aya ati ikun omobinrin naa. Mo sa rii pe, ko so nnkan kan

“O ti fi oogun kan le mi lati ki mi laya, nitori naa okan mi ti di. Eru o si ba mi. O fun mi ni gbere loju ati ni ara, emi naa si fun un. Sugbon, otooto lawon ebu ta a lo si gbere wa.

“O yin omobinrin naa lorun, nigba tie mi di i lowo mu. Leyin iseju die, o lo ti re oun, mo si gba a lowo re. Nigba to ya o pada sibi orun re. Leyin naa lo mu obe jade, o si ge ori re. O tun ge owo re mejeeji, o si lo ti re oun. O ni ki n ge nnkan-omobinrin re, mo si ge e. O tun ni ki n ge itan re, sugbon mo ni bi won se n ge e. O gba a lowo mi, o si ni ki n die se naa mu, nigba to n ge e.. Mo beere ohun to fe fi itan yen se, o si l’oun fe fun dokita kan laduugbo wa ni.

“A bo sinu igbo, a si ko itan ati okutu omobinrin naa sibe, a kori sile. Nigba ta a de inu yara ise re nile, mo n tan ina foonu mi, mo si n pa a, ka le maa fi reran. Nigba yen ni Afaa to n gbe nibe wa, to si beere pe taa niyen.

“Wasiu lo ba a nita, o si l’oun n se nnkan ninu yara ise oun. Nigba yen, awon ode Soludero to n so adugbo yen n koja, Afaa si pe won lati wa ye yara naa wo. Won wo o, won si bawon eya ara naa.

“Awon ero pe le wa lori, Wasiu si mu awon ode yen lo sibi ta a ko okutu atawon eya ara to ku si. Leyin naa ni won fa wa le olopaa lowo.

Nigba takoroyin beere pe n je oun ati Wasiu mo nnkan ti ofin wi nipa ipaniyan. Mutairu ko le soro, sugbon Wasiu ni oun nimo nipa ofin. Nitori ti oun o ni eko iwe.

Nipa ohun ti esin musulumi so, esi re ni pe, ki won pa eni to ba paayan.. Sugbon, Wasiu ni owo t’oun n wa lo mu k’oun huwa naa.