Thursday 25 March 2021

Eyi ni bi Segun Awolowo, looya se ku lasiko to n bow a gbejo baba re ro ni kootu


 


Eyi ni bi Segun Awolowo, looya se ku lasiko to n bow a gbejo baba re ro ni kootu

E tun kaabo lose yii, sabala itan manigbagbe. Lose to koja, a gbiyanju wa oro awuyewuye bi isakooso orile-ede Naijiria se bo sowo Hausa/Fulani gunle. A so bi Zik se tan Awolowo atawon iko re je pelu bo se pe ipade awuruju siluu Asaba, sugbon ti ko yoju rara. A soro lori idi ti Zik fi l’oun o le sise po pelu eya Yoruba ati ohun to faa.

 

A menuba bi awon omo Yoruba seto ikowojo kan lodun 1947. A so bi owo ohun se le ni egberun metala aabo owo pon-un ati bi won se kowo naa fun egbe oselu NCNC pe ki Zik lewaju awon eekan egbe mefa mi-in lo siluu London lati lo fehonu han lori awon ofin onikumo ti Gomina Arthur Richard gbe kale.

 

A o sai so bi irin-ajo ohun ko se so eso rere kankan, nitori iwa odale ati igbeyin bebo je to waye ati bi won se n bu ara won, ti won si n na’ka aleebu si Zik. A so bi Zik ninu awijare re se fesun kan awon omo Yoruba to wa ninu iko ti won ran lo siluu London ohun pawon nisoro oun

 

A so bi Zik ati H O Davies se n so oko oro sira won ninu iwe iroyin, eyi to feree fa ija eleyameya laarin awon  Yoruba ati Igbo to n gbe niluu Eko nigba naa ati bi Gomina Arthur Richard ati akowe re, Hugh Foot se sare pe ipade laarin awon mejeeji sile ijoba lati ki won nilo pelu bi Zik ti se pinnu pe “won ko gbodo gba Yoruba laaye lati dari Naijiria” to si je pe Fulani lo lo ba sasepo.

 

Lose yii, a o so nipa bi omo Oloye Obafemi Awolowo se ku ninu ijamba moto loju ona Eko si Sagamu lasiko to n bow a gbejo baba re ro ni kootu. Osu yii lo pe odun merinlelaadota tiroyin buruku ti ko wu enikeni lati gbo ohun sele. Nise ni ofo nla se gbogbo ekun Iwo Oorun, koda orile-ede Naijiria, nigba ti iroyin iku Segun Awolowo gba igboro. Bawon abiyamo se n ba Mama HID sunkun, lawon baba naa n ba Awolowo daro nitori oorun to wo losan-an gangan naa.

 

Ti Segun Awolowo ba wa laye lasiko yii ni, ogunjo osu kin-in-ni odun yii ni ko ba p’eni odun mejidinlogorin. O si see se ko ti di agbejoro agba, SAN tabi adajo ile-ejo to ga julo lorile-ede yii. Koda, o le ti di aare orile-ede yii tabi ko ti se gomina ipinle Ogun. O si le ti je asofin agba, iyen seneto.

 

Yoruba ni ile laa wo, ka to so’mo loruko. Eyi si maa n farahan daadaa ninu oruko ti won maa n so omo won l’opo igba. E je ka ya kuro lori oro taa n ba bo na. Awon oko atiyawo kan lati ipinle Bendel atijo lo gbe ni abule kan, Alaro niwon odun 1970. Ile okunrin kan ti won n pe ni Baba Idowu si ni won de si. Gege bi ise Yoruba, won mu awon took-taya yii bi okan lara won. Ede Yoruba won ko fi bee dan moran, sugbon nigba to ya, eyi oko ti bere sii maa powe ninu oro to ba n so.

 

Leyin bi odun kan, iyawo okunrin yii bimo okunrin lanti-lanti. Lati fi emi imoore bi won se gba won towo-tese han, okunrin yii so omo re ni l’oruko omo baba onile re, Idowu. Idowu ke! Idowu bawo! Awon eeyan bere sii beere lowo re, idi to fi so omo re ni Idowu. Tidunnu-tidunnu lo si fi so fun won p’oun fe fi emi imoore bi baba onile oun se n toju oun han ni.

 

Nigba naa ni won wa salaye fun un pe, oruko Yoruba nitumo. Won je ko ye e pe, omo ti won ba bi leyin awon ibeji ni won maa n so ni Idowu ati pe lai si Taye ati Kehinde, ko le si Idowu. Won ni, idi ti won fi n pe baba onile won ni Baba idowu ni po ti bi ibeji ri, sugbon tawon omo naa ko si mo. Won si wa gba a nimoran lati so omo re ni Olumide to je oruko mi-in ti Idowu n je.

 

Ogunjo osu kin-in-ni odun 1939 ni won bi Olusegun Awolowo. Gbogbo awon eeyan to b mo tabi gbo itan yoo mo p’odun to le die ni odun to saaju 1930 yii fun Awolowo. Gege bi onisowo to mo nnkan to n se, sibe Awolowo nisoro eto oro-aje to denu kole niwon odun 1930. Iya Agba so fun mi pe, gbogbo nnkan lo won debi ti iyo gan o si l’oja lati ra.

 

Gbogbo owo ti Awolowo fi n sowo lo run. Won ta ile re ni gbanjo, moto ayokele re, olowo iyebiye , Chevrolet naa baa rin. Iyen nikan ko, gbogbo aso re atawon dukia mi-in pelu lo sii. Bee, igbeyawo re ko tii pe odun meji. Asiko hila hilo yii ni won bi Segun. Oluwasegun. Eyi to fi igbagbo Awolowo ninu Olorun han. Omo ileri ni.

 

Awolowo ri ibi Olusegun gege bi ipa rere ninu aye re, paapaa ni osu meji si ojo-ibi tie gan. O mu biro re, o si ko oro yii sile:

“Leyin ojo, oorun yoo ran;

Leyin okunkun, imole yoo de;

Ko si ibanuje, ti ko ni idunnu ninu;

Ko si idunnu, ti ko ni ekun tie;

Bo ti wu ki oorun mu to, sanmo dudu die yoo wa;

B’ekun pe dale kan, ayo n bo l’owuro!

 

Omo ti gbogbo obi le fi yangan ni gbogbo igba ni Segun. O jogun opolopo baba re. Gbogbo awon akekoo egbe re atawon tisa ile-eko Agbeni Methodist, Ibadan nibi to lo laarin odun 1943 si 1951 lo maa n so bo se je olopolo pipe to. Lati kekere re lo si ti maa n daabo bo won aburo leyin re.

 

Lodun 1952, Segun wole sile-eko Igbobi niluu Eko. O si se daadaa pupo ninu idanwo asejade oniwee mewaa re. Leyin to pari iwe mewaa, Segun nisoro kekere kan lori ise wo ni yoo yan laayo. Iya re fe ko r’omo ti yoo se okoowo, sugbon baba re n fe omo ti yoo kekoo imo ofin. Awolowo je eda kan ti kii yan fun omo, o nigbagbo ninu ki omo pinnu ohun to wu u lati se. Segun mi eko imo ofin.

 

Lodun 1957, l’omo odun mejidinlogun, Segun kori siluu London ni yunifasiti Cambridge gege bi akekoo. O se daadaa ninu eko re, o si kekoo gboye ninu imo ofin.

 

Logunjo osu kin-in-ni odun 1960, Segun p’omo odun mokanlelogun. Gege bi asa nigba naa l’orile-ede United Kingdom, odun mokanlelogun ni won fi n so p’eeyan ti balaga. Segun si sayeye re ni ojule 15A Kensington Palace Gardens. Awon akekoo egbe re ni Cambridge atawon ore re si wa nibe lati ye e si. Koda, aburo re, Tola Awolowo (to pada di Oyediran); Degbola Ademola ati aburo re obinrin, Nike Adegbola pelu Kayode Oyediran wa lara awon odo to wa nibi ayeye ojo-ibi ohun.

 

Leyin to ti pari eko re, to si se daadaa ninu eko imo ofin, o di agbejoro nile Geesi lodun 1962. Akoko idunnu lojo ohun fawon obi re, paapaa fun baba re t’oun pelu di agbejoro ni nnkan odun merindinlogun seyin, nigba ti Segun gan si wa l’omo odun meje pere. Bo se yege di agbejoro bayii, ore re, Yomi Akintola, to je omo Oloye Samuel Ladoke Akintola lo koko wa lo siluu Dublin to n gbe nigba naa. Lati Dublin ohun si ni Segun ti kori si papako ofurufu lati maa bo lorile-ede Naijiria ninu osu kejo odun 1962. Ninu oro mi-in to so, Dokita Kunle Olasope ni osu kin-in-ni odun 1963 ni Segun pada si Naijiria.

 

Nibi la o tun ti danu duro labala itan manigbagbe lose yii. Ipade wa tun di lose to n bo, nigba ta o tun maa tesiwaju. Inu apileko Bola Adewara to pe ni “Video of our Lifetime” la ti se ayolo itan yii. Titi di lose to n bo ohun. Awa la o maa wa, eyin la o si maa ba. Ire o!

Akiyesi.

O ti jade ninu iwe iroyin KAKAKI ose yii.