Friday 1 May 2020

Ayajo ojo osise: NUJ, Oyo fe seto iranwo owo fawon omo egbe




Ayajo ojo osise: NUJ, Oyo fe seto iranwo owo fawon omo egbe
Yanju Adegboyega
Egbe akoroyin, NUJ nipinle Oyo ti pinnu lati seto iranwo owo kan, nipase banki agba ile wa fawon omo egbe re. Oro ohun jeyo ninu atejade kan, ti alaga egbe ohun, Ademola Babalola fi sita lojo Jimoh lasiko to n sajoyo pelu awon osise.
Gege bo se wi, Ademola ni ajoyo ti odun yi lo bawon eeyan lejafuu, pelu bi ko se si awon apejopo ati weje-wemu bii t’ateyinwa.
Ademola ni opo awon aseyori l’egbe osise ti se laarin ayeye ti odun to lo ati t’odun yi pelu afikun p’okan ninu re ni afikun owo osu tuntun fawon osise, eyi tijoba si ti fowo si. O si wa gbe oriyin fun ijoba apapo atawon ijoba ipinle gbogbo.
Babalola ko sai toka sipo tawon osise akoroyin wa, paapaa bawon agbanisise won se ti ge owo osu won nidaji lenu asiko ti arun Corona Virus yi bere ni nnkan osu meji seyin. Ati bawon ika agbanisise mi-in ko se sanwo osu awon mi-in rara.
O salaye pe, ohun tisele yi n ko wa ni po ye kawon osise akoroyin ronu ja ona mi-in, ti owo lw maa gba wole fun won, paapaa ise agbe sise. Ademola ni egbe akoroyin ipinle Oyo ti soro papo pelu banki apapo ile wa lati seto eyawo fawon omo egbe re, lati fi sowo to ba wu won.
Ninu oro re “awon asiwaju egbe akoroyin nipinle Oyo ti n seto eyawo kan lati odo banki agba ile wa fawon omo egbe wa lati fi se owo to ba wu won. Eyi ti won yoo fi maa kun owo osu ti ko ni laari tawon agbanisise ati oludasesile n fun won.
Ademola wa salaye pe, looto lowo tawon akoroyin n gba l’osu ko to nnkan. Sugbon, o ni ohun to ja julo ni ibukun Olorun lori iwonba ti won ba n gba naa pelu adura pe odun to n bo yoo dara ju eyi lo.